Olusegun Runsewe rí ẹ̀wọ̀n he torí pé ó tàpá sí àṣẹ iléẹjọ́

Oríṣun àwòrán, NCAC
Runsewe àti Bobrisky ní ìjà tì tẹ́lẹ̀ lohun tí ọ̀pọ̀ mọ̀ tí wọ́n sì ń tàn káàkiri.
Lẹyin ti ko ju bii wakati mẹrinlelogun eyi tii ṣe ọjọ kan ti ile ẹjọ paṣẹ pe ki oludari agba ileeṣẹ to n risi ọrọ aṣa ati iṣe na ni Naijiria, Oluṣẹgun Runsewe lọ sẹwọn, o ti ni oun loun mọ idi.
O ni idi ti wọn fi n fun ogun mọ oun ni tori pe oun ti ilu aṣa ati iṣẹ ọna to wa niluu abuja pa.
Awọn oniroyin ni oludari agba ileeṣẹ to n risi ọrọ aṣa ati iṣe sọ ọ̀rọ̀ yii fun niluu Abuja.
O ni idi ti awọn si fi ti ilu naa pa ni wi pe o ti n di ibi isapamọ si fun awọn ọmọ amugbo ati ọdaran.
Ẹwẹ, o ni awọn ọlọpaa Naijiria si ti paṣẹ pe ki wọ́n ṣi i pada.
O ni lẹyin eyi oun ko le tun ṣẹṣẹ maa fi alaye dahun ibeere kankan lori ọrọ na.
Ṣáájú, ìròyìn sọ pẹ́yìn ìjà pẹ̀lú Bobrisky, Runsewe rẹ́wọ̀n he torí ó tàpá sí àṣẹ iléẹjọ́
Ileẹjọ giga kan to kalẹ sadugbo Maitama nilu Abuja ti pasẹ lọjọbọ pe ki wọn sọ ọga agba fun ibudo asa ati isẹ ọna nilẹ wa, Olusẹgun Runsewe sọgba ẹwọn tori hihu iwa ọyaju sile ẹjọ.
Adajọ Jude Okeke, lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ pasẹ fun ọga agba ọlspa pe ko ls mu Runsewe, ko si fi sinu ọgba ẹwọn Kuje nilu Abuja titi ti yoo fi bọ asọ ọyaju sile ẹjọ silẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Amotekun dé! Ẹ̀yin ọmọ Yorùbá lókè òkun, ẹ má bẹ̀rù mọ́ láti wálé - Akeredolu
- Ìfẹ́ èmi àti olólùfẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ta jẹ ètè ara wa nínú sinimá - Nkechi Blessing
- Ẹ̀yin ẹkùn yókù, ẹ fi ikọ̀ àbò "Amotekun ṣe àwòkọ́ṣe rere - APC
- Ọmọọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Harry àti ìyàwó rẹ̀ kọ ipò wọn sílẹ̀ ní ìran ọba
- Ta ló ń fi ògùn Paracetamol, Hypo dín Gààrí lọ́dọ̀ yín níbẹ̀ yẹn?
- Makinde fẹ́ san ₦30,000 fáwọn òṣìṣẹ́ l’Oyo, yóò tún kọ́ ọjà ìgbàlódé sí Akẹ̀sán
Ohun to fa sababi ni pe Runsewe se orikunkun si asẹ ileẹjọ to pa lọjọ Kẹẹdogun osu Kejila ọdun 2017, pe igun mejeeji to ni nkan se pẹlu ẹjọ kan nipa abule isẹ ọna gbọdọ jẹ ki ohun gbogbo wa bo se wa.
Ileẹjọ ni Runsewe ko gbọdọ ti amule isẹ ọna naa pa amọ to kẹyin si asẹ naa, ti adajọ Okeke si ni ki wọn gbe asọ ẹwọ wọọ lọrun, ko lee jẹ ẹkọ fun awọn eeyan miran to maa n tapa si asẹ ileẹjọ.














