Harry àti Megan: Ọbabinrin rọ àwọn òṣìṣẹ́ láàfin láti wá ojútú si ìpinnu wọ́n

Obabinrin, Megan ati Harry

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Prince Harry àti Megan: Ọbabinrin rọ àwọn òṣìṣẹ́ laáàfin láti wá ojútú si ìpinnu wọ́n
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọbabìnrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ ààfin lati wá ọ̀nà abáyọ to ṣee múlò si ìpínnu ti Haary àti Megan pinu láti kúrò ni ààfin àti pe àwọn fẹ́ máa fi ọwọ́ àwọn ṣiṣẹ́.

Akọròyìn BBC to ń sojú ilé ọba, Nicholas Witchell sọ pé ọlọlá jùlọ ti kàn si ọmọ ọba Wales àti Duke ti Cambridge lónìí ọjọbọ.

Wọ́n rọ àwọn àdárí nile ìjọba láti sọ̀rọ pọ̀ pẹ̀lú Sussex àti ìjọba.

Ọ̀rọ̀ náà jáde pé àtẹjáde Harry àti Megan dun àafin gidigidi.

Ọmọ ọba Harry àti Meghan o fi ọ̀rọ̀ lọ ẹníkẹ́ni ni àfin ki wọ́n to gbé àtẹjáde wọ́n, gẹ́gẹ́ bi àfin ṣe sọ fún akọròyìn BBC Jonny Dymond.

Àkọlé fídíò, Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'

Sááju lálẹ́ Ọjọru ni ọmọọba Harry àti Meghan sàlaye pé àwọn kò fẹ́ jẹ́ àsáju nínú ààfin mọ, àti pe àwọn fẹ́ maa fi ọwọ́ àwọn ṣiṣẹ́ owó

Wọ́n pinnu lati pín àsìkò wọ̀n láàrin UK àti North America àti pé àwọn kò ni fi ààfin sílẹ̀ àti gbogbo ojúṣé àwọn ní ààfin.

Àkọlé fídíò, Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele

A fẹ́ máa f'ọwọ́ ara wa ṣíṣẹ́ ajé - Ọmọọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Harry

Meghan ati Harry

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Idile ọba ni Ilẹ Gẹẹsi ti sọ wi pe pẹlu ibanujẹ kan ni awọn fi gba iroyin pe Ọmọọbakunrin Harry ati iyawo rẹ, Meghan Markle fẹ fi ipo ọkan gboogi lara ọmọọba orilẹ-ede ilẹ Gẹẹsi silẹ.

Eyi ko ṣẹyin bi Ọmọọba Harry ati iyawo rẹ, Meghan Markle ṣe fi lede ni oju opo ikansiraẹni Instagram wọn pe awọn fẹ yẹba diẹ kuro lara ilẹ baba wọn, lẹyin ti awọn gbe e yẹwo fun ọpọlọpọ igba.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Wọn fikun un pe awọn nifẹ lati lọ ri orilẹ-ede to wa ni Ariwa Iwọ Amerika ni bi ti awọn ti ṣetan lati bẹrẹ igbesi aye ọtun.

Nibẹ ni awọn yoo ti ma a ṣisẹ lati le fi tọju idile wọn, lai gbẹkẹle owo isuna to n wa lati ile ọba Ilẹ Gẹẹsi.

Ọmọọba Harry ni awọn yoo ma ṣisẹ pọ lati mu idagbasoke ba Ọbabinrin Elizabeth, ti o jẹ iya fun wọn.

Ẹwẹ, ile Ọba ilẹ Gẹẹsi ko dun inu si igbesẹ ti ọmọọba Harry ati iyawo rẹ gbe yii.

Harry ati Meghan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi akọroyin BBC ṣe jabọ, ile Ọba Buckingham ni awọn ko woye pe iru nkan bayii lee waye, nitori wọn ko fi igbeṣẹ naa lọ ẹnikẹni ki wọn to gbe igbeṣẹ naa.

Àkọlé fídíò, 'Mo fọ́ lójú ṣùgbọ́n mo mọ gbogbo irinṣẹ́ tí mo fi ń ṣe mọkalíìkì'