Iran crisis: Ọmọogun Amẹrika rí èròjà àdó olóró méjì ní ìbití báálù já sí

Oríṣun àwòrán, AFP
Orilẹede Iran se asise ni, pẹlu bo se fa baalu orilẹede Ukraine ja wa silẹ lọjọru lẹba ilu Tehran, ti ẹmi mẹrindinlọgọsan si bọ ninu isẹlẹ naa.
Awọn agbẹnusọ kan fun orilẹede Amerika salaye pe awọn nigbagbọ pe ado oloro ni wọn yin mọ baalu Boeing 737-800 to ja wa silẹ naa.
Saaju ni orilẹede Ukraine ti kede pe oun si n sagbeyẹwo lati mọ boya ado oloro lo ja baalu naa walẹ abi bẹẹkọ sugbọn Iran ti sẹ pe eyi ko ri bẹẹ.
Ijamba ọkọ baalu ofurufu ọhun si lo waye lẹyin wakati diẹ ti orilẹede Iran ju ado iku si ibudo awọn ọmọ ogun ilẹ Amerika meji to wa ni Iraq.
Awọn ọmọ ogun ọtẹlẹmuyẹ Amẹrika lo sọ fawọn akọroyin CBS pe, awọn se awari awọn eroja meji kan to faramọ ado oloro nibi isẹlẹ ado oloro.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣé wàhálà Amẹ́ríkà àti Iran leè dédé parí báyìí?
Ṣe wọn ni ko si ohun to le koko ti kii rọ bo pẹ boya. Ọrọ wahala laarin orilẹede Amẹrika ati Iran eleyi to n fẹju mọọ lati bii ọjọ diẹ sẹyin ti n dabi ẹnipe yoo rọrun laipẹ.
Ko si idi meji fun eyi ju wi peorilẹede Amẹrika ni oun ti "ṣetan bayii lati joko fun ijiroro to duro daadaa" pẹlu orilẹede Iran lẹyin ti awọn orilẹede mejeeji gbena woju ara wọn.
Ninu lẹta kan ti orilẹede Amẹrika kọ ṣọwọ si ajọ iṣọkan agbaye, UN, o ni pipa ti awọn pa Ọgagun Qasem Soleimani ko ṣẹyin didaabo bo orilẹede Amẹrika atawọn eeyan rẹ.
- Iran ti jáwọ nínú ìlù ogun tó n lù -Trump
- Ọmọọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Harry àti ìyàwó rẹ̀ kọ ipò wọn sílẹ̀ ní ìran ọba
- Ta ló ń fi ògùn Paracetamol, Hypo dín Gààrí lọ́dọ̀ yín níbẹ̀ yẹn?
- Iheanacho gba Leicester city lọ́wọ́ ìtìjú agbolé
- Ẹ̀yin ẹkùn yókù, ẹ fi ikọ̀ àbò "Amotekun ṣe àwòkọ́ṣe rere - APC
- Makinde fẹ́ san ₦30,000 fáwọn òṣìṣẹ́ l’Oyo, yóò tún kọ́ ọjà ìgbàlódé sí Akẹ̀sán
- A móyè yìí jẹ... ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ fòǹtẹ̀ lú gómìnà mẹ́rin
Orilẹede Iran pẹlu naa ti yin ado oloro sawọn ibudo ọmọogun ofurufu orilẹede Amẹrika to wa ni orilẹede Iraq ṣugbọn iroyin sọ pe ko si ẹni to ku ninu ikọlu. Awọn pẹlu naa ni orilẹede Amẹrika nikan kọ ni igbesẹ rẹ lati daabo bo awọn eeyan rẹ, igbesẹ ikọlu tiwọn naa wa lati daabo bo orilẹede Iran atawọn eeyan rẹ.
Olori orilẹede Iran, Ali Khamenei ṣe apejuwe ikọlu naa gẹgẹ bi iwọsi nla fun orilẹede Amẹrika, o si paṣẹ pe ki Amẹrika ko ara rẹ kuro lẹkun naa.
Amọṣa, igbakeji aarẹ orilẹede Amẹrika, Mike Pence ni iwadii n fihan pe orilẹede Iran ti sọ fun awọn ikọ ọmọogun to wa lẹyin rẹ lati maṣe kọlu ohun ini Amẹrika kankan.
Nibayii, ileegbimọ aṣoju-ṣofin lorilẹede Amẹrika yoo dibo loni lori igbesẹ ati din agbara Aarẹ Donald Trump ku lori gbigbe ogun dide lai gba asẹ to ye kooro lọwọ ileegbimọ aṣofin apapọ orilẹede naa.
Ninu lẹta to kọ ṣọwọ si ajọ UN naa, aṣoju ijọba Amẹrika lajọ iṣọkan agbaye, Kelly Craft ni Amẹrika ṣetan lati jiroro lọna ati dena awọn ohun ti Iran lee gbe kalẹ to lee maa dun mọhurumọhuru mọ eto alaafia ati abo lagbaye.
Lẹta naa fi kun un pe, iku Soleimani di dandan ati pe Amẹrika yoo gbe awọn igbesẹ miran to ba yẹ lẹkun Middle east lati daabo bo awọn oṣiṣẹ rẹ atawọn ohun ini rẹ gbogbo.
Amọṣa aṣoju ijọba orilẹede Iran, Ambasadọ Majid Takht Ravanchi ṣalaye pe ipe orilẹede Amẹrika fun ijiroro ko ṣee gbọ seti rara pẹlu bi orilẹede Amẹrika tun ṣi ṣe n tẹsiwaju pẹlu awọn igbesẹ to mu eto ọrọ aje ha gaga lori Iran.













