Carabao cup: Iheanacho gba góòlù wọlé láti ra Leicester city padà lọ́wọ́ ìfìdírẹmi

Kelechi Iheanacho, agbabọọlu NAijiria gba goolu wọle fun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ipele to kangun si aṣekagba ni idije Carabao cup waye ni ilẹ Gẹẹsi ṣugbọn ori lo ko ikọ agbabọọlu Leicester city yọ lọwọ idojuti ni kọọrọ iyara wọn ni papa iṣere Kings power.

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ lo ti wo o pe irọrun ni ifẹsẹwọnsẹ ọhun yoo ba de fun ikọ naa amọṣa omi fẹrẹ t'ẹyin wọ igbin wọn lẹnu.

Ọpẹlọpẹ goolu kan ti Kelechi Iheanacho gba wọle ni ko jẹ ki Aston villa na Leicester city mọle lẹyin ti Frederic Guilbert ti kọkọ fi ori gbe goolu wọle fun Villa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kejidinlogun.

Abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa ni wọn gbe Iheanacho wọle ti o si jẹ goolu naa.

Ninu ọrọ rẹ, olukọ ẹgbẹ agbabọọlu Leicester city, Brendan Rodgers ṣapejuwe Kelechi gẹgẹ bii agbabọọlu ti ẹbun rẹ ko ṣee fọwọ rọ sẹyin. O ni lootọ ni pe Iheanacho kii fi bẹẹ ri aye gba bọọlu ki oun to de gẹgẹ bi olori ikọ naa ṣugbọn lati igba ti oun ti de loun ti bẹrẹ si nii fun un ni aye lati maa dabira lori papa, eleyi to ni o si ti n so eso rere.

Bakan naa lo ni agbabọọlu ọmọ Naijiria naa a maa ṣe iṣẹ takuntakun ni gbogbo igba to si jẹ pe eyi ti n fara han ninu ayo to n gba bayii.