Supreme Court: Okowa, Ishaku, Bello àti Ikpeazu yege àtakò ìbò

Oríṣun àwòrán, Empics
Ilé ẹjọ to ga jùlọ lórílẹ̀-èdè Najiria ti dájọ pé àwọn gómína mẹrin ti ẹjọ wọ́n wà níwáju òun, ni wọ́n n jáwé olúbori nínú ìdìbò to gbé wọ́n wọlé.
Àwọn gómínà náà ni Okezie Ikpeazu (ipinlẹ Abia) Dairus Ishaku (Ipinlẹ Taraba), Ifeanyi Okowa (ipinlẹ Delta) àti Abubakar Bello (Ipinlẹ Niger).
Ní ìpínlẹ̀ Abia, Alex Otti to dije lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Grand Alliance (APGA), kàn si ilé ẹjọ to ga jùlọ láti da ìdìbò Ikpeazu nu, ti ilé ẹjọ to n gbẹ́sun awuyewuye to jẹyọ nídi ìdìbò ti dá láré.
Lateef Fagbemi to jẹ́ agbẹjọrò Otti rọ ilé ẹjọ láti dá ijáwe olúbori ikpeazu sigbo, ki wọ́n si gbe fun onibara oun.
Sùgbọ́n John Galinje to dájọ náà lorukọ igbimọ ẹlẹni meje to jokó lori ẹjọ náa ni àwọn afinisu náà ko lee mu ẹ̀ri to dáju wá si iwájú ilé ẹjọ.

Ní ti gomina Taraba, ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress (APC) ti ké gbàjare pé, Dairus Ishaku to jẹ́ gómínà kò wọle ìdìbò náà lọna to tọ, bákan náà ni ẹgbẹ́ tún sọ pé, kò tèlé ìlànà to yẹ gẹ́gẹ́ bi ofin ẹgbẹ́ (2010)ṣe sọ.
Kanu Agabi to sojú Ishaku ati People's Democratic Party (PDP) rọ ilé ẹjọ láti da ẹjo APC nù nítori pé ẹ̀sù wọ́n o mọyan lórí.
Ní ìdáhun Agabi, Ishiaku Dikko to jẹ́ agbẹ́jọrò APC nigba ti ó ń fìdí ẹ mulẹ̀ pe, lóòtọ ni wọ́n fagile asoju APC lati dije dìbò pé o tọ si ẹni to ṣe ipò keji láti dupo.
Nínú ìdájọ rẹ̀, adájọ naa gba pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC ko ni ọmọ ẹgbẹ́ to pegede nínú idibo náà.

Ní ìpínlẹ̀ Delta, Great Ogboru àti ẹgbẹ òṣèlú APC rọ ilé ẹjọ láti da ìbò Ifeanyi Okowa nu nítori ẹ̀sun ségeṣègé to wáye nínu ètò ìdíbò.
Yunus Usman, to sojú ẹgbẹ oselu alátakò sàlàyé pe, gbogbo ìbò ti Okowa ni kọja iye ènìyàn to forúkọ silẹ̀ fún ìdìbò gómìnà to wáye ní ọjọ kẹsan oṣù kẹta, 2019.
Ẹ̀wẹ̀, Damian Dodo to jẹ́ agbẹ́jọrò Okowa rọ ilé ẹjọ láti dẹjọ olupẹjọ nù nitori kò si ẹ̀ri to dájú.
O ní àwọn olùpẹjọ ko ri ẹri mu jáde yála nile ẹjọ to n gbẹjọ ẹsun ìdìbò àti nílé ẹjọ kò tẹmilọrun.
Adájọ Centus Nweze ni, Ogboru àti APC pé wọn o le fi ẹri to dáju han pe èrò to dibo pọ ju àwọn to forúkọ silẹ̀ lọ.

Bakan náà ni ilé ẹjọ dá ẹjọ olùpẹjọ to fẹ̀sun kan gómìnà Niger nú.
Ẹjọ kòtẹ́milọrun ti Umar Mohammed Nasko to jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ PDP pè ni adájọ tun dànu
Mohammed fi ẹsun kan Bello pe iwé ẹri èké lo gbe kalẹ̀ to si jẹri irọ sinú iwé to to fọwọ́ si lọ́ds àjọ ẹleto ìdìbò.
Bákan náà lo ni ilé ẹjọ to n gbẹsun ìdìbò ko dá jọ láàrin ọgọsan ọjọ gẹ́gẹ́ bi òfin se sọ
Mary Abaji to jẹ adajọ nio pe ilé ẹjọ ti se nkan ti ó to fún ẹjọ ti wọ́n dá .
O ni ilé ẹjọ to ga jùlọ ko lágbara láti tu gbé ẹjọ ti ilé ẹjọ kòtẹmilọrun ti dá tẹ́lẹ̀












