Operation Amọtẹkun: Ilé iṣẹ́ ààrẹ ránṣẹ́ pe àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá lórí ọ̀rọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn

Awọn gomina ilẹ Yoruba

Oríṣun àwòrán, Facebook/SEyi Makinde

Ile iṣẹ aarẹ ti ranṣẹ pe awọn gomina marun un to wa nilẹ Yoruba lori agbekalẹ eto aabo ''Amọtẹkun'' ti wọn fẹ ṣe ifilọlẹ rẹ l'Ọjọbọ.

Gbogbo eto lo ti to fun ifilọlẹ eto naa eleyi ti Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu jẹ alaga rẹ.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe, ile iṣẹ aarẹ yoo ṣepade nirọlẹ oni Ọjọru pẹlu awọn gomina mẹfẹẹfa lati beere idi ti wọn fi fẹ fi eto naa lọlẹ nilẹ Yoruba.

Nibi apero kan to waye lori eto aabo loṣu keje ọdun 2019, lawọn gomina mẹfẹẹfa ti pinnu lati gbe eto Amọtẹkun kalẹ lẹyin ti iṣẹlẹ ijinigbe pọ kaakiri ilẹ Yoruba lọdun to kọja

Awọn eeyan to n ṣe fijilante, awọn onimọ lori ọrọ eto aabo atawọn ọlọpaa yoo wa ninu ẹṣọ Amọtẹkun naa.

Iṣẹ wọn ni lati maa ṣe iwadii lori ọrọ to niṣe pẹlu aabo kaakiri ilẹ Yoruba, bakan naa ni wọn le mu awọn ọdanran.