EKSU: Fásitì ìpínlẹ̀ Ekiti dá òṣìṣẹ́ 355 padà sẹ́nu iṣẹ́

Fasiti ijọba ipinlẹ Ekiti

Oríṣun àwòrán, @Titiloye_Blog1

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan ọhun ni wọn da pada sẹnu iṣẹ ninu awọn eeyan ẹgberun o le diẹ

Fasiti ijọba ipinlẹ Ekiti to wa ni Ado Ekiti ti da awọn oṣiṣẹ marundinlọgọtalelọọdunrun pada sẹnu iṣẹ lara awọn to da duro loṣu Kẹwaa, ọdun 2019.

Awọn oṣiṣẹ naa ni wọn pe pada sẹnu iṣẹ lẹyin imọran igbimọ ti Fasiti naa gbe kalẹ lori ọrọ idaduro ọhun.

Igbimọ to ga ju nile iwe EKSU ti fi ọwọ si igbesẹ naa.

Ọdun 2019 ni wọn jawe lọ gbele ẹ fun awọn oṣiṣẹ to le ni ẹgbẹrun kan nile iwe naa, leyi to fa ọpọlọpọ awuyewuye.

Àkọlé fídíò, Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele

Iroyin sọ pe, awọn arundinlọgọtalelọọdunrun yii ni ile iwe naa pe pada sẹnu iṣẹ bayii lara awọn eeyan naa.

Àkọlé fídíò, Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU