EFCC 2019 in Retrospect: Gomina mẹ́ta wà láàrín ènìyàn 1,245 tó kó sí panpẹ wa ni 2019

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹ-ede Naijiria, EFCC ti sọ wi pe ẹniyan ẹgbẹ̀fà ati marundinladọta (1,245) ni awọn ti fi jofin iwa ibajẹ ni ọdun 2019.
Ọga Agba Ajọ EFCC, Ibrahim Magu sọ wi pe igba akọkọ ni yii ti awọn yoo fi awọn asebajẹ jofin, eleyii ti gomina mẹta si wa ninu wọn.
Magu fikun un wi pe ajọ EFCC ti setan lati ri i wi pe iwa ibajẹ ati aṣemaṣe dopin ni orilẹ-ede Niajiria, paapaa lọdun 2020 ti a wa yii.
Magu ṣalaye pe awọn ṣi rọ awọn eniyan ti wọn ba ri awọn aṣebajẹ ni awujọ, ki wọn fi oju wọn han pẹlu ipese to wa fun awọn ti wọn ba ṣe ofofo awọn aṣebajẹ, iyẹn whistleblower policy.
Bakan naa ni Ọga Agba Ajọ EFCC, Ibrahim Magu mẹnuba ipenija ti awọn n koju lọdọ ile ẹjọ.
Magu sọrọ lori bi awọn ile ẹjọ to n gbọ ẹsun iwa ibajẹ ṣe n fa bi igbin ki wọn to ṣe igbẹjọ lọpọ igba, eleyii ti Magu sọ wi pe ohun fa ifasẹyin fun iṣẹ awọn ni awujọ.
Magu tun fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe laipẹ laijina ni wọn maa tun ri iṣẹ ajọ EFCC sii lori awọn igbẹjọ to ti bẹrẹ tẹlẹ












