Iran ti jáwọ nínú ìlù ogun tó n lù -Trump

Donald Trump
Àkọlé àwòrán, Iran ti jáwọ nínú ìlù ogun tó n lù -Trump
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹrika ni o jọ bi ẹni pe Iran ti jáwọ nínú ìlù ogun tó n lu lẹ́yin ti o ju àdá olóro si ibudo ikọ ọmọ ogun ilẹ Amẹrika ni Iraq.

Ogbẹ́ni Trump ko si ọmọ ilẹ̀ Amẹrika kankan to farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà àwọn ǹkan díẹ̀ si lo bàjẹ́ ni ibùdó náà.

Ikọlu ti iran ṣe si ibudó Irbil àti Al Assa wáye ni ààrọ kùtùkùtù ọjọrú.

Iran ní àwọn ṣe èyi láti gbẹ̀san ikú igbákeji ọgágun Iran Qasem Soleimani to wáyé lọ́sẹ̀ to kọja

Ikọlu ilẹ̀ Amerika to wáye lọ́sẹ̀ to kọ́ja yìí lo ga júlọ láti dá ibáṣepọ ti ko dánmọràn láàrin orilẹ̀-èdè méjèèji tẹ́lẹ̀ rú pátápátá.

Trump ni orílẹ̀-èdè Merika yóò túbọ̀ fi ọwọ́ líle mu Iran pàáp['aa jùlọ lori isúna àti ọrọ ajé, eyi yóò si wà bẹ́ẹ̀ titi iwá wọ́n yóò fi yí pada

Sááju ní ààrẹ ilẹ̀ Amerika ti halẹ̀ mọ wọ́n pé oun yóò da ọmọogun ilẹ̀ Amerika sita ti Iran ba gbìyànju láti gbẹ̀san igbésẹ̀ Amerika, sùgbọ́n lẹ́yin o rẹyin ti Iran náà ju adó olóro si ibudo àwọn ọmọogun ilẹ̀ Amerika, Trump ti sinmi

Èrè ti Nàìjíríà yóò jẹ nínú ọ̀rọ̀ Iran àti US

Aare Iran ati Amerika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìkọ̀lu Iran àti US: Báwò lọ̀rọ̀ yìí ṣe kan ilẹ̀ Afirika

Pípa ti orílẹ̀-èdè Amẹrika pa igbákeji olóri ogun orilẹ̀-èdè Iran Quasim Soleimani àti ibẹ̀rù bojo ti ọ̀rọ̀ náà ti n dá silẹ̀ láàrin àwọn orilẹ̀-èdè méèjèjì maa le di ǹkan ti yóò dá yánpọyánrin silẹ̀ fún gbogbo àgbaye.

Ní ọjọru, ọjọ kẹjọ,oṣù kíní ọdún 2020, ni Iran fi adó olóró ránsẹ́ si àwọn ọmọogun orilẹ̀-èdè Amerika ni bùdó wọ́n ni Iraq, lẹ́yin ti wọ́n ti ṣèléri pé àwọn náà yóò gbẹ̀san ikú ti wọ́n ṣe pa igbákeji olóri ogun Iran Soleiman .

Sááju àsìkò yìí ni ọ̀gá ọlọpàá orilẹ̀-èdè Naijiria ti ránsẹ si gbogbo àwọn ọ̀gá ọlọpàá jákèjádo Naijiria pé ojú ni alákan fi ń sọri, ati pé ki wọ́n moju to àyika wọ́n dáada.

Gẹ́gẹ́ bi àwọn tí ọ̀rọ̀ kan ṣe sọ àwọn ilẹ̀ Afirika, ni ànfani púpọ nínú iọ̀ẹ̀lẹ̀ náà bákan náà ni àwọn ǹkan to pọ̀ wà láti pàdánù.

Ọjọgbọ̀n to mọ̀ nípa ààbo àti itan iṣẹ̀nbaye, Adam Okene Ahmed sàlayé pé bi ìjà yìí ba ju bi óṣe wà yii lọláàrin àwọn orílẹ̀-èdè mééjèèjì o túmọ si pé Naijiria, Ghana, Chad, Gabon àti àwọn míràn yóò jẹ ànfani to pọ̀.

Fún Naijiria, èyí yóò mu ki owó iṣúna wọ́n kí o tun rú gọ́gọ́ sí

O fi ku pé àwọn orilẹ̀-èdè yìí yoo túbọ náwó láti gbé epo rọ̀ọ̀bi wọ àwọn orilẹ̀-èdè yìí

Orílẹ̀-èdè bii Cameroon to maa n ta epò rọ̀ọ̀bi ní alábọde, wọ́n o na owó to pọ̀ ju iye ti wọ́n yóò pa lọ

China àti Russia ni yóò jẹ mudùmúdùn jùlọ ti ogún bá bẹ́ silẹ̀ láàrin Iran àti US.

Ahmed ní China yóò lo ànfani náà láti wọ ààrin àwọn orilẹ̀-èdè ìwọ̀ òòrun ilẹ̀ Afirika eyi ti ilẹ̀ Amẹrika ti n dari láti ẹ̀yìn wá lọ.

China ati Russia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Èrè ti Nàìjíríà yóò jẹ nínú ọ̀rọ̀ Iran àti US

O tún ni ìgbòkègbodo àwọn agbésùmọ̀mi yóò tun pọ si ni ìhà ìwọ̀-òòrun ilẹ̀ Afirika, pàápàá jùlọ ni Chad Basin.

Onímọ míràn Chukwuma Osakwe to jẹ́ ọjọgbọ̀n nínú ìmọ itan àwọn ológun sàlàyé pé àwọn orílẹ̀-èdè ti wọ́n ti jé ki ìjà ẹsìn pin wọ́n tẹ́lẹ̀ yóò túbọ kojú ìṣòrò ìjà ẹ̀sìn àti wàhálà ètò ààbò.

Àwọn ikọ̀ Bokoo Haram àti Islamic State ni iwọ òòrun Afrika (ISWAP) tún le lo ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti kọlu àwọn ènìyàn Chad, Niger ati Nàijíríà.

Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn ènìyàn ìràn ń jó fótò Trump níná lásìkò ti wọ́n wọde lòdì si Trump ni Tehran ni inú oṣù karun, ojo kẹsan ọdun 2018

Osakwe ni wàhálà ti yóò bẹẹ́ silẹ̀ ni Nàìjíríà le jẹ́ láàrin Shiite àti Sunni nígbà ti àwọn mírànn yoò ma ri ìjà náà bi èyi to n ṣẹ̀lẹ̀ si Islam.

Àwọn ijọ Shiite le lòó láti dá wàhálà silẹ̀ nitori wọ́n fi wé pé ilẹ̀ Amẹrika ń ba àwọn musulumi Shiite ja ni kìì ṣe Iran gan ni wọ́n n ba jà

Ati pé àwọn ọmọ lẹ́yin Shiite míràn pẹ̀lú àwọn musulumi miran to niṣe pẹ̀lú Iran ni ilẹ̀ Adulawọ yìí le fẹ́ maa gbẹsan láti ba ǹkan to ba jẹ́ ti ilẹ̀ Amerika jẹ́.

Ọmọ ilẹ̀ Iran 82 ló kú nínú bàálù tó já lórílẹ̀èdè naa

Iran Crash

Oríṣun àwòrán, AFP

Ọmọ orilẹ-ede Iran mejilelọgọrin lo ku ninu ọkọ ofurufu ilẹ Ukraine ti o jabo ni iṣẹju diẹ ti wọn gbera ni papakọ ofurufu Imam Khomeini, ni olu ilu Iran, iyẹn Tehran.

Àkọlé fídíò, Gbogbo ènìyàn mẹ́rìndínlọ́gọ́sàán tó wà nínú ọkọ̀ òfúrúfú ti ilẹ̀ Ukraine tó jábọ́ ní Iran ló kú pátápátá.

Minisita orilẹ-ede Ukraine fun ọrọ to nii ṣe pẹlu ilẹ okeere, Vadym Prystaiko lọ sọ bee.

Vadym Prystaiko ni ọmọ ilẹ Canada mẹtalelọgọta wa ninu awọn to ku ninu ijamba ọkọ ofurufu naa.

Prystaiko fikun wi pe awọn to wa ninu ọkọ ofurufu naa lẹ ni aadọsan eniyan.

Minisita naa fikun un wi pe engiini ọkọ ofufuru to yọnu naa, lo ṣe akọba fun ọkọ ofurufu naa to fi jabọ lati oke.

Iye awọn eniyan to ku ninu ijamba ọkọ ofurufu Ukraine

  • Ọmọ Ilẹ Iran mejilelọgọrin(82)
  • Ọmọ Ilẹ Canada mẹtalelọgọrin (63)
  • Ọmọ ilẹ Ukraine mọkanla ati gbogbo awọn oṣiṣẹ ọkọ (11)
  • Ọmọ Ilẹ Sweden mẹwaa (10)
  • Ọmọ Ilẹ Afganistan mẹrin (4)
  • Ọmọ Ilẹ Germany mẹta (3)
  • Ọmọ Ilẹ Gẹẹsi mẹta (3)

Kò sí wàhálà lórí ìkọlù Iran, lákọ ni America wà- Trump

Aarẹ ilẹ Amerika, Donald Trump ti fi awọn ọmọ America lọkan balẹ pe ko si wahala.

Trump

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Ẹru Iran ko ba odo America rara, akọ okuta ni USA lọjọkọjọ- Trump

Aarẹ Trump fi lede loju opo twitter rẹ pe America ṣi n ṣe iwadii bi ọ̀ṣẹ́ náà ṣe pọ̀ tó ni ki wọn to mọ ọna ti awọn maa gba ba Iran sọrọ pada lori ikọlu naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Iran sọ ado oloro si ibudo awọn ọmọ ogun America lorilẹ-ede Iraq ni agbegbe Al-Asad ati ni inu Irbil

maapu iraq

Oríṣun àwòrán, Empics

Àkọlé àwòrán, Ibudo naa ni won ti n woye nkan to ti baje bayii

Fonran fidio to safihan bi ọkọ ofurufu naa ṣe ja yii ni Mehdrad Torabi gbe soju opo twitter re:

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Saaju asiko yii ni Aarẹ Trump ti sọ pe kiko ibudo ọmọ ogun America kuro ni Iraq ko le ṣenuure fawọn eniyan orilẹ-ede naa.

iran

Oríṣun àwòrán, Alamy

Àkọlé àwòrán, Opo emi lo sonu nibi eto isinku ogagun Soleiman ti won tun fi sun isinku naa siwaju

Orílẹ̀-èdè Iran ti kọlu ibùdó ọmọ ogun America méjì ní Iraq- America

Lati ọjọ Ẹti to kọja ti Amẹrika ti pa Soleimani, olori ikọ ogun Iran ni agbaye ti wa ni inu fuu-aya fuu lori pe o ṣeeṣe ki ogun waye laarin orilẹ-ede mejeeji.

ado oloro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ko din ni ibudo ọmọogun ilẹ Amẹrika meji ti ado oloro lati orilẹede Iran kọlu.

Ko din ni ibudo ọmọ ogun ilẹ Amẹrika meji ti ado oloro lati orilẹ-ede Iran kọlu bayii.

Amọṣa ko si ẹni to lee fi idi rẹ mulẹ boya ẹmi lọ sii tabi bẹẹkọ.

Gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ aabo lorilẹ-ede Amẹrika sọ, ọpọ ado oloro ni wọn ju sinu ibudo awọn ọmọ ogun naa to wa ni orilẹ-ede Iraq.

Ileeṣẹ Tẹlifiṣan apapọ orilẹ-ede Iran ṣalaye pe igbesẹ naa waye lati fi gbẹsan bi Amẹrika, labẹ aṣẹ aarẹ Trump, ṣe pa olori ikọ ogun Iran, Ọgagun Qasem Soleimani ni Baghdad.

Àkọlé fídíò, Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele

Ileeṣẹ ọmọ ogun Amẹrika, Pentagon, kede rẹ pe ibudo meji ni Irbil ati Al Asad ni ikọlu naa kan.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ikọ ọmọ ogun orilẹ-ede Iran ṣalaye pe awọn fi ikọlu naa fa awọn orilẹ-ede to n lẹdi apo pọ pẹlu Amẹrika, ti wọn n fun Amẹrika laaye lati kọ ibudo sori ilẹ wọn leti ni.

Àkọlé fídíò, Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU

Iran ni pe eyikeyi ninu wọn ti wọn ba lo lati fi ṣina ikọlu si Iran yoo fara kaaṣa ibinu Iran.

Bakan naa ni minisita fọrọ ilẹ okeere ni Iran, Javad Zarif pẹlu ti ṣalaye loju opo Twitter pe awọn fi ikọlu naa daabo bo ara awọn ni o kii ṣe pe awọn fẹ fi fẹ wahala naa loju sii.

iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iran ni pe eyikeyi ninu wọn ti wọn ba lo lati fi ṣina ikọlu si Iran yoo fara kaaṣa ibinu Iran.

Ni tirẹ, Aarẹ Donald Trump kede loju opo Twitter rẹ lẹyin to gbọ iroyin ikọlu naa pe, 'Ko si giri'ati pe awọn ko ti i ṣe ayẹwo ọwọja ọṣẹ ti ado oloro naa ṣe.

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Ọkọ̀ òfurufú Boeing 737 jábọ́ ni kété tó gbéra ní pápákọ̀ òfurufú ni orílẹ̀-èdè Iran

Okọ ofurufu to gbera ni Tehran ọhun jẹ ti orilẹ-ede Ukraine International Airlines lo ti jabo ni kopẹ kopẹ to gbera kuro ni Iran.

iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iroyin ni papakọ ofurufu Kyiv ni Ukraine ni ọkọ ofurufu naa n lọ bo ṣe gbera kuro ni Iran

Wọn ni Kyiv to jẹ olu ilu Ukraine ni ọkọ ofurufu ọhun morile ko to jabọ

Okọ ofurufu naa gbe ero ọgọsan an ati awọn oṣiṣẹ ọkọ ofurufu

Awọn akọroyin Iran ni ọkọ ofurufu Boeing 737 -800 naa jabọ ni agbegbe Parand to wa ni guusu iwọ oorun Tehran to jẹ olu ilu Iran.

Titi di asiko yii ko tii si ẹni to le sọ boya iṣẹlẹ naa ni i ṣe pẹlu ọrọ ilẹ America ati ti Iran to n ja ranyinranyin nilẹ.

Kò sí ẹni tó lè sọ bóyá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú yìí níi ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó n ṣẹlẹ̀ láàrin America àti Iran.

Àkọlé fídíò, Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele

Ile iṣẹ iroyin Reuters ni ina ṣi n jo ninu ọkọ ofurufu naa ṣugbọn ko tii si akọsilẹ ẹni to laa ja titi di asiko yii.

Àkọlé fídíò, 'Inu mi bàjẹ́ nígbà tí mo bí i, odidi oṣù mẹ́ta, mi ò lè gbàdúrà s'Ọ́lọ́run'

Pirhossein Koulivand to jẹ adari ajọ aṣeiranwọ ninu iṣẹlẹ pajawiri ni orilẹ-ede Iran sọ pe o ṣeeṣe ki a ṣi ri awọn ero naa doola ṣugbọn ko tii si ẹni to le sọ bayii ibi to maa ja si.

Ajọ Red Crescent Organisation ni ti wọn ti ni o maa nira pupọ lati ri ẹnikankan to maa jade laaye ninu ijamba ọkọ ofurufu naa.

Àkọlé fídíò, LASU Ritual: Àwọn akẹẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ LASU tí wọn fi ṣowó sọ̀rọ̀ lórí ìgbé ayé olóògbé