Porn Sites 2019 in Retrospect: Njẹ́ ẹ mọ̀ pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló n wo 'Blue film' jù?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn ti darukọ orilẹ-ede Naijiria gẹgẹ bi orilẹ-ede to n wọ ori ayelujara lati wo fidio ibalopọ julọ lọdun 2019.
Oju opo ayelujara kan to maa n ṣe afihan fidio ibalopọ, Porn Hub, lo fi iroyin yii sita loju opo rẹ pe l'ọdun 2019, awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lo wo fidio ibalopọ julọ lọdọọ wọn.
Oju opo ayelujara 'Porn Hub' sọ pe eyi jẹ abajade akiyesi wọn nipa awọn to wo fidio ibalopọ loju opo wọn l'ọdun 2019.
Awọn ipinlẹ ni Naijiria to woo julọ ni:
- Ọlọ́pàá Eko ní kí olùkọ́ UNILAG Boniface wá sọ tẹnu rẹ̀ lórí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀
- Àjọ ọlọpàá Eko kédé pé ìbalòpọ̀ nítà kò bójúmu
- Àwọn ọ̀nà tí obìnrin fi le gbádùn ìbálòpọ̀
- Sisitá ìjọ Kátólíkì méjì wá ṣe iṣẹ́ ìhìnrere l‘Afirika, lóyún bá dé
- Ẹ̀mi arákùnrin yìí kò gbé e, ó bá aláṣẹ́wò lò dórí ìgbà ìkéje ló bá ré sálákeji
Porn Hub fikun pe orilẹ-ede Ghana, Kenya ati Egypt n tọ Naijiria lẹyin ni.
Ohun to ṣeesẹ ko jẹ iyanilẹnu fun awọn eniyan kan ni pe orilẹ-ede Naijiria to jẹ ibi ti ẹsin ti fi ẹsẹ mulẹ daadaa le jẹ orilẹ-ede ti wọn yoo darukọ rẹ gẹgẹ bi orilẹ-ede to n wo fidio ibalopọ julọ lori ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Pornhub.com/Insights
Nigba to n sọrọ, onimọ nipa ibalopọ, Mmirimmachukwu Ekechukwu sọ fun BBC Igbo pe ko si nkan to buru ninu ki awọn ọmọ Naijiria o maa wo awọn fidio ibalopọ, ṣugbọn ki wọn o ye e dibọn.
Ko buru ti eniyan ba lọ si ori ayelujara lati wo fidio ibalopọ, ṣugbọn o jẹ nkan iyalẹnu pe orilẹ-ede Naijiria lo n leke, paapa bi a ṣe maa n fi ara wa han bi 'ẹni mimọ'.
Lẹyin Naijiria lo kan orilẹ-ede Ghana, Kenya, Egypt, Morocco ati awọn miran lori atẹ naa.
- Ẹ́ gba fóónù, ẹ pe ẹbí yín pé a fẹ́ dáná ṣun yín - Aráàlú sọ fún adigunjalè méji
- Pásítọ̀ pe Naira Marley ní ẹlẹ́mìí èṣù, Marley fèsì padà pé kí pásítọ̀ gan tẹ èṣù mọ́lẹ̀
- Díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò mi ìgboro tìtì l'ọ́dún 2020 rèé
- Mọ̀ síi nípa Oyedele Adedokun tó ya àwòràn Donald Trump tó lu ayélujára pa
















