Dubai: Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìwé ìrìnnà ọlọ́dún márùn ún tí UAE n fún arìnrìnàjò

@HHShkMohd

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Ilẹ UAE sọ pe awọ̀n n gba alejo arinrinajo igbafẹ to le ni miliọnu mọkanlelogun lọdọọdun.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ilẹ United Arab Emirate (UAE), ti ṣi aṣọ loju ipele akọkọ iwe irinna ọlọdun marun un fun awọn eniyan lati gbogbo orilẹ-ede.

Awọn alaṣẹ fi ikede naa sita lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ ti orilẹ-ede naa ṣe fun ọdun 2020 l'ọjọ Iṣẹgun.

Iwe irinna tuntun ti wọn fẹ ẹ fi sita yii laarin oṣu mẹrin ni yoo fi aaye gba awọn arinrinajo igbafẹ lati wọ orilẹ-ede naa laimọye igba fun ọdun marun o le.

Sheihk Mohammed to jẹ Igbakeji Aarẹ ati Olootu ijọba ilẹ UAE, to si tun jẹ Ọba ilu Dubai, sọ pe wọn gbe igbesẹ naa lati le sọ ilẹ UAE di orilẹede ti awọn arinrinajo igbafẹ yoo maa lọ ju l'agbaye.

Ṣugbọn, ko sọrọ lori boya awọn eniyan yoo ma a san owo fun un tabi iye ti iwe irinna naa yoo jẹ.

Awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ilẹ UAE

Oríṣun àwòrán, Twitter/@HHShkMohd

Àkọlé àwòrán, Ṣaaju ikede yii, awọn arinrinajo igbafẹ le duro ni ilẹ UAE fun aadọrun ọjọ pẹlu iwe irinna alaimọye igba to jẹ ọfẹ.

Sheikh Mohammed tun darapọ mọ ileeṣẹ ipolongo ilu Dubai lati fi ikede yii sita loju opo Twitter.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Amọ ṣa, ileeṣẹ iroyin Gulf n sọ pe awọn ẹri kan jade pe orilẹede naa yoo fi aaye gba awọn to ba ni iwe irinna ọlọdun marun un lati lo to oṣu mẹfa lẹẹkan naa to ba wu wọn.

Àkọlé fídíò, Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele

Ofin ati ilana ti ẹni to ba fẹ ẹ gba iwe irinna tuntun yii ko yatọ si eyi to ti wa nilẹ tẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?