Seyi Makinde: Ẹ ṣe àkójọpọ̀ orúkọ àwọn òǹtàjà tí àjálù bá lọ́jà Akẹ̀sán fétì ìrànwọ́

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Idunnu ti n subu lu ayọ bọ fun awọn osisẹ ipinlẹ Ọyọ nitori gomina Seyi Makinde ti kede pe ko ni si osisẹ kankan nipinlẹ Ọyọ ti owo rẹ yoo kere si ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira, tii se owo osu to kere julọ tijọba apapọ kede rẹ.

Gomina Seyi Makinde seleri bẹẹ lasiko isin alajumọse akọkọ lati ki ọdun tuntun 2020 kaabọ, eyi ti ijọba ipinlẹ Ọyọ seto pẹlu awọn osisẹ, to waye lọgba Secretariat milu Ibadan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gomina ni ijọba oun ti sefilọlẹ igbimọ kan ti yoo dunadura pẹlu awọn osisẹ lori agbekalẹ owo osu tuntun naa pẹlu afikun pe oju opo kanna ni ijọba ati awọn ẹgbẹ osisẹ n tọ lori ọrọ yii.

Awọn osisẹ Ọyọ fi ijo si lori owo osu tuntun

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Bakan naa ni Makinde fọwọ idaniloju sọya pe ijọba oun ko ni mẹẹri nidi ipese eto idẹrun to yanranti fun awọn osisẹ ipinlẹ Ọyọ, eyi ti yoo mu igbe aye wọn bẹsuẹ si.

Seyi Makinde ati awọn ọmọ igbimọ alasẹ rẹ to se abẹwo si ọja Akẹsan

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Ẹwẹ, gomina Seyi Makinde ti se abẹwo si ọja akẹsan nilu Ọyọ to jona lọjọ Aiku lati se abẹwo si awọn ohun to jona nibẹ.

Gomina Makinde, ẹni to ba awọn eeyan to padanu ẹmi ati dukia ninu isẹlẹ ijamba ina naa, wa seleri pe oun yoo kọ ọja igbalode pada fun wọn, ti isẹlẹ naa yoo si di ile ọba to jo, ẹwa lo bu kun.

Seyi Makinde ati awọn ọmọ igbimọ alasẹ rẹ to se abẹwo si ọja Akẹsan

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

"Mo gba gbogbo ẹbi mọra lori bi awọn osisẹ panpana se kuna lati tete bomi pa ina ọhun ko to bọwọ sori, ijsba mi yoo si se atunse to yẹ nipa isẹlẹ naa."

Makinde wa kesi alaga afunsọ ijọba ibilẹ ila oorun Ọyọ, ti ọja Akẹsan wa labẹ rẹ lati se akojọpọ orukọ awọn ontaja ti ajalu naa ba, lọna ti seto iranwọ to yẹ fun wọn.