C. Ronaldo: C. Ronaldo fi góòlù mẹ́ta bẹ̀rẹ̀ ọdún 2020 pẹ̀lú Cagliari

C. Ronaldo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ogbontagi agbabọọlu ọmọ orilẹede Portugal, Christiano Ronaldo ti fi goolu mẹta ṣẹwọ ninu ọdun tuntun.

Ronaldo tun rọjo goolu gẹgẹ bi iṣe rẹ pẹlu goolu mẹta nibi ifẹsẹwọnsẹ ẹgbẹ agbabọọlu Juventus pẹlu Cagliari ni liigi Serie A.

Igba akọkọ niyi ti Ronaldo yoo gba goolu mẹta wọle ni ifẹsẹwọnsẹ kan naa lati igba to ti dara pọ mọ Juventus lọdun 2018.

Oun ni agbabọọlu akọkọ ti yoo gba goolu mẹta wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ kan ṣoṣo ni liigi mẹta ọtọọtọ lagbaye, iyẹn liigi ilẹ Gẹẹsi (Premier league), liigi orilẹede Spain (la liga) ati liigi ilẹ Aguda, orilẹede Italy (Serie A).

oun yii kan naa si tun ni agbabọọlu to gba goolu mẹta wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ kan naa julọ lagbaye. ifẹsẹwọnsẹ mẹrindinlọgọta ọtọtọ ni Ronaldo ti gba goolu mẹta wọle, eleyii ti ko si agbabọọlu miran to tii dan iru bẹbẹ bẹ wo.

Ronaldo gba goolu s'awọn Cagliari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kii ṣe tuntun mọ pe ifigagbaga wa laarin Ronaldo ati Messi toun pẹlu jẹ odu agbabọọlu lagbaye.

Ni kete ti ifẹsẹwọnsẹ naa pari si ni awọn ololufẹ awọn mejeeji ti n waako lori ikanni ayelujara gbogbo.

Bi awọn ti Ronaldo ko ṣe fẹ wọn ọn kun, lawọn ti Messi naa ko fẹ gba a laabọ.