Premiership: Arsenal ta ọ̀mì 1-1 pẹ̀lú Bournemouth ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ Arteta

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmi goolu kọọkan ni Bournemouth ati Arsenal gba ni idije premiership to waye lale Ọjọbọ yii.
Ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn labẹ olukọni tuntun, Mikel Arteta kii ṣe eyi to mu iyatọ pupọ wa si ti atẹyinwa.
- Kí ló ṣẹlẹ̀ tí a fi ń pé ọjọ́ kejì Kérésì ní 'Boxing Day'?
- Gómìnà Sanwo-Olu pàṣẹ pé kí wọn tú ẹléwòn 6 sílẹ lásìkò Kérésìmesì
- Funke Akindele, Toyin Abraham, Bimbo Oshin ṣe Kérésìmesì lọ́nà àrà
- Èyí ni ìdí tí a kò fi yọ̀nda El-Zakzaky pẹ̀lúù Sowore àti Dasuki- Malami
- Bi àwọn kan ṣé n jẹ àsun ní àwọn míì n ṣeré lórí omí láti gbádùn Kérésì àná
Bournemouth lo kọkọ gba goolu wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju karundinlogoji pẹlu Dan Gosling.
Balogun ikọ Arsenal, Pierre-Emerick Aubameyang lo ra ọmi fun Arsenal nigba to gba goolu wọle ni iṣẹju kẹtalelọgọta ifẹsẹwọnsẹ naa.
Pẹlu abajade ifẹsẹwọnsẹ yii, o fihan pe ifẹsẹwọnsẹ kan ṣoṣo ni Arsenal tii bori ninu mẹrindinlogun ti wọn gba sẹyin.










