El-zakzaky: Ìjọba Nàìjíríà sọ ìdí tí kò fi tú El-Zakzaky sílẹ̀ pẹ̀lú Sowore àti Dasuki

Ọpọlọpọ eniyan lo ti n beere wi pe ṣe ijọba Naijiria ko fi da olori ijọ Shia Islamic Movement, Sheikh Ibrahim El-Zakzaky silẹ pẹlu Omoyele Sowore ati Sambo Dasuki.
Amọ, Minisita fun eto idajọ ni Naijiria ti sọ wi pe ko si agbara lọwọ ijọba Naijiria lati da El-Zakzaky silẹ.
O sọ wi pe ijọba apapọ ko ni ẹtọ lati da si ọrọ naa nitori wi pe ijọba ipinlẹ Kaduna lo gbe e lọ sile ẹjọ.
Ọjọ Iṣẹgun to kọja ni ijọba paṣẹ pe ki ileeṣẹ alaabo DSS o tu Sowore ati Dasuki silẹ, ti ko si ka lai si El-Zakzaky laarin wọn.
O fi kun ọrọ rẹ pe: "Ijọba apapọ ko le dasi eto igbẹjọ ti ipinlẹ, nitori ẹtọ ijọba ipinlẹ ni lati ṣamojuto ẹjọ to ba pe sile ẹjọ bo ba ṣe wu u.
Ọpọlọpọ igba ni ijọba apapọ ti sọ pe oun kọ l'oun fi ofin gbe El-Zakzaky, ati wi pe ijọba ipinlẹ Kaduna lo pe e l'ẹjọ.
Ṣaaju asiko yii ni ile ẹjọ ti pasẹ pe ki wọn o yọnda El-Zakzaky ati iyawo rẹ, Zinatu, amọ ti ijọba ko mu aṣẹ ile ẹjs ṣẹ.
Lori iru awọn nkan bayii ni ijọba orilẹ-ede Amẹrika ṣe fi ikede sita ni ọjọ kejilelogun, oṣu Kejila wi pe orilẹ-ede Naijiria wa lara awọn orilẹ-ede ti ko faaye gba ẹnikẹni lati lo ẹtọ to faaye gba wọn lati ṣe ẹsin to wu u laisi idasi ijọba.
Akọwe ijọba Amẹrika, Mike Pompeo lo kede eyi sita.
Ikede ti Amẹrika fi sita n tọka si wahala to yọri si mimu ti wọn mu Sheikh El-Zakzaky si ihamọ.
O tun ṣalaye wi pe ileeṣẹ ologun Naijiria ati awọn oṣiṣẹ alaabo to ku n fi ẹtọ ominira lati ṣe ẹsin to wu wọn dun awọn ọmọ ijọ Shia.
Oṣu Kejila, ọdun 2015 ni awọn ọmọ ijọ Shia di ọna mọ awọn ọkọ to kọwọrin pẹlu Olori ileeṣẹ ologun Naijiria nigba naa, Ọgagun Tukur Buratai, nilu Zaria.
Fidio kan si jade si gbangba, eyi to fihan bi awọn ọmọ ogun ati Shia ṣe kọlu ara wọn lasiko ti awọn ọmọ ogun fẹ ẹ kọja ni ọna naa.
Wahala to waye laarin awọn ọmọ ogun nitori iṣẹlẹ naa yọri si iku ọpọlọpọ.
Lati igba naa si ni awọn alaṣẹ ti mu Zakzaky ati iyawo rẹ, Zinatu si ihamọ.
- Ilorin gbàlejò Wizkid, àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ fẹ́ ẹ̀ gbée lójú agbo
- Ìjọba Buhari kò tíì fi akọ̀ròyìn kankan sátìmọ́lé láti ọdún 2015 - Garba Shehu
- Funke Akindele, Toyin Abraham, Bimbo Oshin ṣe Kérésìmesì lọ́nà àrà
- Èyí ni ìdí tí Bàbá Kérésì fi máa n wọ aṣọ pupa àti funfun nígbà gbogbo
- Ẹ ronúpìwàdà lásíkò ọdún, àti àwọn ìkíni mìrán tó jẹ yọ fún Kérésì



















