Siji Ọlamiju: Paracetamol àti ìyẹ̀fun bleach tí àwọn ọlọ́jà ń lo láti ṣe GààríÌ ti mú kí ijọba pariwo síta

Awọn agba bọ wọn ni ọna ọfun ni ọna ọrun.
Amọṣa ki ọpọ ma baa gba ọna ati jẹ Gaari di ero ọrun lo mu ki ijọba ipinlẹ Ọṣun maa pariwo tantan si eti awọn araalu paapaa awọn to n ṣe Gaari ni ipinlẹ naa.
- Iheanacho gba Leicester city lọ́wọ́ ìtìjú agbolé
- Ẹ̀yin ẹkùn yókù, ẹ fi ikọ̀ àbò "Amotekun ṣe àwòkọ́ṣe rere - APC
- A móyè yìí jẹ... ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ fòǹtẹ̀ lú gómìnà mẹ́rin
- Díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò mi ìgboro tìtì l'ọ́dún 2020 rèé
- Ẹ́ gba fóónù, ẹ pe ẹbí yín pé a fẹ́ dáná ṣun yín - Aráàlú sọ fún adigunjalè méji
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti ke sawọn olounjẹ nipinlẹ ọhun lati dẹkun aṣa lilo ogun paracetamol lati fi se ẹran rọ tabi lilo eroja ifọṣọ 'bleach' fun ṣiṣe Gaari lati mu ki Gaari ati fufu tubọ funfun sii.
Amugbalẹgbẹ fun gomina ipinlẹ Ọṣun lori ọrọ ilera, apoogun Siji Ọlamiju pẹlu kọmiṣọna fun iroyin ati itaniji, Funkẹ Ẹgbemode lo pe ipe yii lati ṣalaye awọn ijamba ti irufẹ igbesẹ bẹẹ lee ko ba ẹya ara bi ifun, ẹdọ, kidirin ati ọkan.
Ọlamiju ni ijọba ṣẹṣẹ ṣawari aṣa naa ni nipasẹ awọn oṣiṣẹ ilera ti wọn yan lati ṣe abẹwo sawọn ileewosan ilera alabọde kaakiri ipinlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, others
Wọn ni iwa ọdaran paraku ni aṣa naa leyi ti awọn to n ṣe e gbọdọ dẹkun rẹ ki ọwọ palaba wọn to segi.
O ni erooja ifọṣọ ni Hypo ti ko si yẹ ko maa kan ara ki a to ma sọ inu ikun.
kọmiṣọna fun iroyin ati itaniji, Funkẹ Ẹgbemode ni ijọba ipinlẹ Ọṣun yoo bẹrẹ eto itaniji jakejado ipinlẹ naa lori rẹ.
O ni ijọba ti ṣakiyesi pe awọn eeyan kan n lo ogun ara riro paracetamol lati se ẹran rọ ati lati se ẹsẹ maluu to ba le lati din inawo ati akoko wọn ku.












