Illegal Orphanage: Ìjọba ti ayédèrú ilé ọmọ aláìlóbìí pa, ọmọdé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbòmìnira

Awọn alaṣẹ tọrọ kan lorilẹede Naijiria ti ko agadagodo silẹkun ile ọmọ alailobi kan ti ko niwe ofin ni ipinlẹ Kaduna, ti wọn si tu ọmọde mẹtadinlọgbọn silẹ.
Ọjọ ori awọn ọmọ naa wa laarin ọdun mẹta si mejila.
Agbẹnusọ ile iṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Kano, DSP Abdullahi Haruna sọ fun BBC pe, o to ọmọde mọkandinlogun tawọn tu silẹ nile awọn ọmọ alailobi Du Merci niluu Kano.
- Àṣìṣe ní orílẹ̀èdè Iran fi já bàálù Ukraine wa silẹ̀ - Iléeṣẹ́ ìròyìn Amẹrika kéde
- Amotekun dé! Ẹ̀yin ọmọ Yorùbá lókè òkun, ẹ má bẹ̀rù mọ́ láti wálé - Akeredolu
- Ibadan Fire: Iná míràn tún ṣẹyọ nilú Ibadan
- Bàbá akẹ́kọ̀ọ́ LASU tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti pásítọ̀ fi ṣ'oògùn owó ń bèèrè fún ìdájọ́ òdodo
- A fẹ́ máa f'ọwọ́ ara wa ṣíṣẹ́ ajé - Ọmọọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Harry
- Ìfẹ́ èmi àti olólùfẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ta jẹ ètè ara wa nínú sinimá - Nkechi Blessing
Bakan naa ni Abdullahi sọ pe, ile iṣẹ ọlọpaa tun tu awọn mẹjọ miiran silẹ nile awọn ọmọ alailobi Du Merci to wa niluu Kaduna.
Ile iṣẹ ọlọpaa sọ pe, eleyi ṣeeṣe pẹlu iranlọwọ ajọ NAPTIP to n gbogun ti fifi eeyan ṣe owo ẹru lorilẹede Naijiria.
Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa ni, ayederu ile ọmọ alailobi nibi tawọn ti tu awọn ọmọde naa silẹ.

Oludamọran fun Gomina ipinlẹ Kano, Fatima Abdullahi Dala, to ba BBC sọrọ ṣalaye pe Du Merci ti wa fun bi ọdun mẹẹdọgbọn lai niwe ofin.
O wa rọ awọn eeyan Kano lati fi to ijọba leti, ti wọn ba ṣakiyesi iru ile ọmọ alailobi bẹẹ lagbegbe wọn.












