Nigeria Police: Ọlọpàá f'ọ̀bẹ la ará ilú nífun nílùú Eko.

Bala Elikana

Oríṣun àwòrán, @Bala

Àkọlé àwòrán, Ọlọpàá f'ọ̀bẹ la ará ilú nífun nílùú Eko.

Okùnrin kan ti àwọn ènìyàn mọ si Olalekan Ogunsanya ni iròyìn sọ pé ASP Francis fi ọ̀bẹ là nífun nígbàtí gbólóhùn aṣọ ṣẹlẹ̀ láàrin wọ́n lágbègbè Itire nílùú Eko.

Samuel Agbolajo ti ọ̀rọ̀ náà sojú rẹ̀ ló gbé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sórí ayelujara Facebook rẹ̀ pé, ọlọpàá Francis ṣe Ogunsanya lọ́sẹ lásìkò ti ìjà dú wọ́n.

Bakan náà ni Agbalajo fẹ̀sùn kan pé ilé iṣẹ́ ọlọpàá Itire ti wọ́n mú ẹjọ́ lọ ń gbìyànjú láti bo ẹsùn náà mọ́lẹ̀ ti wọ́n si ti tú Francis silẹ̀.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Naijiria tó ló ti bu énú àtẹ lu ìwà ti Francis wù lẹ́yin ti wọ́n ri foto adẹ́rù bani náà lori Facebook.

Bo tilẹ̀ jẹ́ pé Ogunsanya la wàhálà náà já, sibẹ̀ o ní òun n fẹ ki igbésẹ̀ to gbópọ̀n lati ọ̀dọ̀ ọlọpàá

Iwádìí fi han pé Francis jẹ ọkàn lára àwọn ẹka ọlọpàá FCIID ni agbègbè Alagbọ̀n, Ikoyi.

Wàhálà bẹ́ sílẹ nígbà ti Francis n gbé àwọn ẹbi rẹ̀ lọ si ilé ìwòsàn ti o sì gbá òun pẹ̀lú ọkọ tirẹ̀, Ogunsanya ni gbogbo ǹkan ti òun fẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lásìkò náà ni pe ki o tọ̀rọ̀ aforiji, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ni ọlọpàá náà fi pàdé òun.

" Inú bi mi, botilẹ jẹ́ pe mo fẹ kó bẹ̀ mi sùgbọ́n ṣe lo n pariwo 'ṣe o mọ irú ènìyàn ti mo jẹ́ ni?' Bẹẹ lo mú búlálà àti ọ̀bẹ jáde to si jáde kúrò nínú ọ̀kọ rẹ̀ wá si ọ̀dọ̀ mi, bẹ́ẹ̀ ni emi náà sáre lọ mu irinṣẹ́ ti àwọn kafinta fi n gé igi ti mo ri láti dáàbò bo ara mi."

O ní lẹ́yin náà ni Francis tún lọ sínú motorẹ̀ nígba ti àwọn èrò di lọ́wọ́ láti súnmọ òun, sùgbọ́n o tu gbìyànju síi.

"Lẹ́yin ti o fi fi ọbẹ làmi lọ́fun, mí o tilẹ̀ mọ àwọn èèyàn lo pé àkíyèsí mi sii ti mo fi ri ẹ̀jẹ̀ to sàn, mó wá pe òní fóto kan láti yà mi ki wọ́n to gbé mi lọ si ilé ìwòsàn.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, alukoro ọlọ́pàá ni ìpínlẹ̀ Eko, bala Elkana ni ìjà bẹ silẹ̀ láàrin ọlọ́pàá àti Ogunsanya, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lóri ọ̀rọ̀ náà láti fi ìdí òkodoro ọ̀rọ̀ múlẹ̀.