Harry and Meghan: Olóòtú Canada ní ọ̀rọ̀ gbọ́dọ̀ wáyé nípa ìgbésẹ̀ wọ̀n

Oríṣun àwòrán, PA Media
Ijọba orilẹ-ede Canada ti ni ọpọlọpọ ijiroro gbọdọ waye lori igbeṣẹ Ọmọọba Harry ati Meghan lati wa bẹrẹ si ni gbe ni Canada.
Olootu Ijọba ilẹ Canada, Justin Trudeau lo sọ ọrọ yii pe ijiroro gbọdọ waye lori ọna ti wọn yoo gbe gba ati iye owo ti yoo na wọn fun aṣeyọri igbeṣẹ wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olootu Trudeau ni bo tilẹ jẹ pe awọn ara ilẹ Canada fẹran lati gbalejo awọn ladelade, ipade gbọdọ waye nipa bi eyi yoo ṣe waye, ati bi gbogbo rẹ yoo ṣe lọ.
O ni titi di asiko yii, Harry ati Meghan ko i tii fi to ijọba ilẹ Canada leti nipa ohun gbogbo to rọmọ ki awọn Ọmọọba naa wa ma a gbe ni orilẹede wọn.
Ọpọlọpọ ariyanjiyan lo n lọ lori eto aabo fun awọn ẹbi ọba naa lasiko ti wọn ba n gbe ni Canada.
Bi awọn miran ṣe n sọ wi pe ko lẹtọ ki wọn ma a lo owo araalu lati fi tọju wọn ti wọn ba ti kurọ ni Ilẹ Gẹẹsi lọ gbe ni orilẹede Canada.
Ti a ko ba gbagbe, laipẹ yii ni Ọmọọba Harry ati iyawo rẹ sọ wi pe awọn fẹ ṣiṣẹ aje lati fi tọju ara wọn.
Ọbabìnrin Elizabeth ti fara mọ́ ìpinnu ọmọ ọba Harry àti Meghan láti lọ ṣiṣẹ́ ajé
Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi, ti faramọ 'asiko iṣipopada" ti Duke ati Duchess ti Sussex yoo maa lo ni Canada ati United Kingdom.
O sọ ninu atẹjade kan pe "gbogbo ara l'oun fi fọwọ si" ifẹ ọkan wọn lati bẹrẹ igbe aye tuntun, ṣugbọn "oun to wu oun ju ni pe ki wọn o maa ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọkan lara ẹbi ọba ilẹ Gẹẹsi".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣaaju ni awọn eeyan ti n reti remu pe Ọbabinrin Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ọmọọba Harry yóò sèpàdé ní Ọjọ́ Ajé.
Eyi waye lẹyin ipade kan ti Ọbabinrin naa ṣe pẹlu tọkọ-taya naa, ati ẹgbọn Harry, Williams, lọjọ Aje.
Ìpàdé náà kò sẹ̀yìn bí Ọmọbakùnrin Harry àti ìyàwó rẹ̀, Meghan Markle se ní àwọn fẹ́ fi ipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òkan gbòógì nínú ìdílé ọba.
Ọbabinrin Elizabeth sọ pe awọn ọrọ to so mọ ipinnu Harry ati Meghan pọ, to si n pe fun ọpọlọpọ iṣẹ la ti ṣe

Oríṣun àwòrán, EPA
Awọn tọkọtaya naa tun fidi rẹ mulẹ lẹẹkan sii pe awọn ko fẹ gboju le owo ilu.














