Richard Gbadebo: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo yóò ṣe ìwádìí ikú tó pa akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Ibadan

Gomina Seyi Makinde ati Oloogbe Richard

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ijọba ipinlẹ Oyo ti bẹrẹ iwadii lori iku to pa akẹkọọ Fasiti Ibadan, Richard Gbadebo, to ku nile iṣẹ kan ti wọn ti n ṣe ọṣẹ.

Akọwe agba ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ayika ati ohun alumọni, Bashir Olanrewaju lo kede bẹẹ nigba to ṣabẹwo si ẹbi oloogbe ọhun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ijọba ti bẹrẹ eto ayẹwo ti ileeṣẹ naa gbe kalẹ fun oṣiṣẹ rẹ, yoo si fi iya to tọ jẹ ileeṣẹ ọhun lẹyin iwadii rẹ.

Nigba to n fi da ẹbi naa loju pe ijọba yoo fun ẹbi oloogbe naa lowo gba mabinu, o ni ijọba labẹ iṣakoso Seyi Makinde ko ni la oju rẹ silẹ ki iya maa jẹ awọn ara ilu.

O ni "A wa nibi yii lati ba mọlẹbi oloogbe kẹdun, ati lati fi da wọn loju pe ijọba ti gbe igbesẹ lati ṣe iwadii ohun to fa iku ọdọmọdekunrin naa."

"Ijọba Seyi Makinde yoo ri pe idajọ ododo waye lọna ati dena iru iṣẹlẹ bayii lọjọ iwaju."

Ẹwẹ, baba ọmọ naa to doloogbe bere pe ki ileeṣẹ ọhun pese fidio ti ẹrọ ayaworan CCTV to n ka ohun ti awọn eeyan n ṣe ni ileeṣẹ naa ki ọrọ lede.

Gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ naa sọ, Richard dero lẹyin ijamba to waye nile iṣẹ naa nigab to n ṣiṣẹ alẹ loṣu Keje ọdun 2020.

Àkọlé fídíò, Ohun tẹ́ẹ gbúdọ mọ nípa kókó orí ọyàn yín lásìkò fífọ́mọlọ́yàn

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Richard Gbadebo: Àwọn ajafetoo ẹni dìde láti ṣe ẹjọ́ lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ UI nílé isẹ ọṣẹ

Richard ati falana

Oríṣun àwòrán, others

Ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan ti dasi ọrọ iku akẹkọọ fasiti Ibadan, Richard Gbadebo, to ku l'ẹnu iṣẹ ni ileeṣẹ kan ti wọn ti n ṣe ọṣẹ ni ilu Ibadan.

Ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni naa ti orukọ wọn n jẹ, 'The Alliance on Surviving Covid-19 and Beyond' ti agbẹjọro agba, Femi Falana ṣe adari fun lo kede bẹẹ.

Femi Falana ni awọn ti kọ iwe ẹhonu sijọba ipinlẹ Ọyọ lori ọrọ naa, ti awọn yoo si gbe ileeṣẹ Henkel Nigeria limited lọ si ile ẹjọ fun aibikita wọn fun awọn oṣiṣẹ ile isẹ naa.

Gbadebo to jẹ akẹkọọ ọlọdun kẹta ni fasiti Ibadan lo lọ ṣiṣẹ fun igba diẹ ni ileeṣẹ Henkel Nigeria Limited, amọ to kò si inu ẹrọ to n ṣe ọṣẹ, to si gba ibẹ ku.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keje, ni iṣẹlẹ naa waye ni ilu Ibadan.

Ẹsun ti wọn tun fi kan ileeṣẹ naa ni wi pe, wọn ko pese ohun elo aabo bii PPE fun Richard lo ṣe ku.

Bakan naa ni wọn ni o yẹ ki ileeṣẹ naa ri wi pe, iru awọn ẹrọ to le paniyan bẹẹ wa ni ibi ti eto aabo to peye wa fun awọn oṣiṣẹ lati le da abo bo wọn.

Wọn fikun wi pe, ileeṣẹ naa tun kọ lati sọ kulẹkulẹ ohun gan an to ṣekupa Richard lẹnu iṣẹ ati bi o ṣe ku.

Awọn ajafẹtọ naa wa kesi ijọba ipinlẹ Oyo lati ri wi pe wọn fi ileeṣẹ naa jofin, ki iru iṣẹlẹ bẹẹ ma baa tun waye mọ.

Wọn fikun wi pe, awọn ijọba orilẹede Naijiria lọpọ igba, ti fi awọn oṣiṣẹ silẹ lati ri daju wi pe wọn wa ni alaafia lẹnu iṣẹ, ti wọn si n fi ẹmi ẉon wewu, eleyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

Awọn ajafẹtọ ni idajọ otitọ gbọdọ leke lori iku Richard Gbadebo lẹnu iṣẹ, ki awọn ijọba ati awọn ileeṣẹ kaakiri Naijiria ba le kọ ẹkọ wi pe ẹmi awọn oṣiṣẹ ṣe iyebiye.

Ṣaaju ni BBC ti ba awọn obi oloogbe sọrọ, ti wọn si sọ pe ọrọ iku ọmọkunrin naa jẹ kayeefi, ti kii ṣe lasan.

Àkọlé fídíò, Justice for Richard: Òbí àkẹ́kọ̀ọ́ tó kú síléeṣẹ́ ọṣẹ ń bèèrè fún ìdájọ́ lórí ikú ọmọ wọn

Fidio oke yii ni ọrọ baba ati iya Richard Gbadebo pẹlu BBC yoruba.

Ìrọ́ ńlá ní o, iléeṣẹ́ ọṣẹ́ kòì ṣèlérí owó kankan fún wa o!

Ẹbi Richard Gbadebo, akẹkọọ fasiti Ibadan to ku iku ojiji nileeṣẹ kan to n ṣe ọṣẹ ni Ibadan ti ni irọ ni awọn iwe iroyin kan n gbe jade pe ileeṣẹ ọṣẹ ti ọmọ wọn ku si fun wọn ni ẹbun owo.

Nigba ti akọroyin BBC Yoruba ba ẹgbọn oloogbe sọrọ, Adesewa Gbadebo ni irọ gbaa ni iroyin to n tan kalẹ pe ileeṣẹ naa fun awọn ni owo.

O ni ẹbi awọn ko tilẹ mọ alukoro ileeṣẹ naa rara.

"Agbẹjọro wọn pe wa lorii foonu lonii lati ki wa, igba yẹn la n sọ fun un pe ko lọ wo ori iwe iroyin bayi bayi pẹlu ohun ti wọn kọ sita".

O ni lootọ wọn ti wa ki awọn sile, ṣugbọn akẹẹgbẹ aburo rẹ ko tilẹ fun wọn lẹnu ọrọ rara.

"Igba keji taa maa rira waye ni agọ ọlọpaa nibi ti wọn ti n sọ fun awa gan fun igba akọkọ pe wọn n ṣe ayẹwo lọwọ lori oku rẹ lati mọ ohun to pa a".

Adesewa ni ọlọpaa gan ko tilẹ gba aṣẹ lọwọ ẹbi ki wọn to bẹrẹ ayẹwo, ṣugbọn awọn ṣaa dakẹ.

A ó san ẹ̀san ire fún ẹbí Richard, a ó sí san owó gbogbo ètò ìsìnkú - Iléesẹ́ ọṣẹ tí akẹ́kọ̀ọ́ UI kú sí

Ileeṣẹ ọṣẹ ti akẹkọọ fasiti Ibadan kan, Richard Gbadebo ku si lọjọ aje ọsẹ to kọja Expanded Global Industries Limited ti nawọ ẹ ma binu si idile Richard.

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Oyo ti paṣẹ lọjọ abamẹta pe ki wọn ti ileeṣẹ ọṣẹ ti Richard, akẹkọọ fasiti Ilu Ibadan ku si lọsẹ to kọja.

Lọjọ Satide ọhun ni ijọba paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ki gbogbo wọn dawọ iṣẹ duro ki wọn si ma lọ sibi iṣẹ mọ.

Ṣaju eyi ni iroyin sọ pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ko jẹ ki ikọ ti ijọba ran lọ wọle lọjọbọ ọsẹ.

Ileeṣẹ naa lo ti wa ṣeleri lati san ẹsan ire fun ẹbi oloogbe Richard.

Àkọlé fídíò, Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, oloogbe naa kan ṣagbako iku nigba to wa lẹnu iṣẹ rẹ lọjọ buruku eṣu gbomi mu ọhun.

Ileeṣẹ naa ṣapejuwe iku Richard gẹgẹ bi eyi ti wọn kabamọ rẹ gidi gan wn si ti ṣabẹwo si ẹbi oloogbe leyii ti wọn kọwọrin pẹlu ikọ aṣoju awọn akẹkọọ ileewẹ rẹ lọ sile wọn.

Atẹjade ileeṣẹ ọhun fi han pe wn yoo ṣi maa ba ẹbi naa sọrọ lati ṣeranwọ lasiko ikẹdun yii.

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa wa rawọ ẹbẹ si ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọ́n oṣiṣ ni ipinlẹ Oyo lati jọwọ tun ero wọn pa lori titi ileeṣẹ wọn pa tori pe yoo kan tun da kun iṣoro ọrọ aje eyi ti Covid-19 ti da silẹ tẹlẹ ni.

Bakan naa, ileeṣẹ Expanded Global Industries Limited ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọlọpaa ati ileeṣ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ l'Oyo lati tuṣu de isalẹ koko ohun to fa sababi iku Richard gangan.

Ìjọba Oyo fẹ́ mọ ikú tó pa akẹ́kọ̀ọ́ UI níléeṣẹ́ tó ń ṣe ọṣẹ

Ijọba ipinlẹ Oyo ti paṣẹ ki ileeṣẹ ti akẹkọọ fasiti Ibadan kan ti pade iku ojiji, fi atẹjade sita nipa ohun to ṣẹlẹ si akẹkọọ yii.

Bakan naa ni wọn ni awọn fẹ ri ẹrọ akaworan silẹ CCTV lati ọdọ ileeṣẹ naa, eleyi ti yoo tọka si bi arakunrin naa ti ṣe ṣagbako iku lọjọ Aje.

Oluranlọwọ si Gomina ipinlẹ Oyo lori ọrọ awọn akẹkọọ, Olojede Victor lo fi ọrọ yi soju opo Twitter rẹ.

Olojede ni oun ati oluranlọwọ Gomina lori ọrọ ọdọ ati idaraya, to fi mọ aarẹ awọn akẹkọọ fasiti Ibadan, lawọn kọwọrin lọ ṣabẹwo si mọlẹbi Richard.

Aworan Richard

Oríṣun àwòrán, Twitter

O ni bakan naa lawọn kan si ileeṣẹ Henkel Nigeria Limited, ti Richard ti lọ ṣisẹ ti awọn si paṣẹ pe ki wọn lọ yọju si mọlẹbi Richard ni kiakia.

Olojede ni awọn tubọ ni ki ileeṣẹ naa se eto iranwọ fawọn mọlẹbi Richard ati pe, awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwaadi lori ohun to ṣokunfa iku Richard.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ọjọ buruku eṣu gbomi mu lọjọ Iṣẹgun jẹ fawọn mọlẹbi ati ọrẹ Richard Gbadebo, pẹlu bi iroyin iku rẹ ti ṣe kan wọn lara.

Gẹgẹ bi ohun ti a ri ka, Richard padanu ẹmi rẹ nigba to ko si inu ẹrọ to fi n ṣiṣẹ nileeṣẹ, to n ṣe ọṣẹ abufọṣọ nilu Ibadan.

Ninu alaye ti alukoro awọn akẹkọọ fasiti ilu Ibadan, Oladeji Olawunmi Abiodun ṣe fun BBC, o ni onitiju akẹkọọ ti ko ni wahala ni Richard Gbadebo jẹ.

Onirẹlẹ akẹkọọ ni Richard jẹ gẹgẹ bi awọn akẹgbẹ rẹ ṣe sọ

Oríṣun àwòrán, TWITTER

''Richard ni ọmọ ọkunrin kan ṣoṣo ti awọn obi rẹ bi. O ni ẹgbọn obinrin ati aburo obinrin.Iru iku gbona bayi kọ lo tọ si Richard.''

Oladeji ni awọn akẹkọọ ti ṣaaju yọju si awọn mọlẹbi Richard lati lọ bawọn kẹdun iku rẹ ati pe, nibẹ ni awọn ti gbọ pe ileeṣẹ to ti ṣagbako iku naa ko ti yọju si wọn lati bawọn kẹdun.

''Nigba ti a gbọ ọrọ yii, a ko ara wa jọ lati lọ ba awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa.

Wọn ko kọkọ fẹ gba ki gbogbo wa wọle sugbọn lẹyin ọ rẹyin, eeyan mẹrin ninu wa lo ba wọn.''

''Wọn pada ṣalaye fun wa pe nigba ti Richard fẹ du apo lẹnu ẹrọ to n ṣe ọṣẹ ni o ko si ẹnu ẹrọ naa.''

Àkọlé fídíò, Ibadan Death: Àwọn ará àdúgbò Akinyele ké sita lórí iṣékúpani tó ń wáyé ní ìlú Ibadan.

O ni wọn tun sọ fawọn pe''awọn meji ti wọn jijọ n ṣiṣẹ ni wọn ri ẹjẹ lẹnu ẹrọ naa ti wọn si pakiyesi awọn eeyan to ku si pe eeyan kan ti ko si ẹnu ẹrọ.''

Loju opo Twitter,niṣe ni awọn eeyan n daro iku Richard.

Akẹkọọ ipele keji ni ẹka imọ nipa ilẹ Yuroopu (Department of European Studies, Faculty of Arts, University of Ibadan) ni Richard ti n kẹkọọ ki ọlọjọ to de.

Awọn oludari ileeṣẹ to ni ibi ti Richard ti ku ni awọn yoo gbe atẹjade sita lori iku Richard ṣugbọn titi di asiko ti a fi n ṣe akojọpọ iroyin yii, wọn ko ti fi sita.