Ogun COVID-19 test: Ìjọba kéde ìlànà tuntun fún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ ṣe ìdánwò àṣejáde

Oríṣun àwòrán, @dabiodunmfr/theencounter.com.ng
Ijọba ipinlẹ Ogun ti kede pe, eto ayẹwo arun Coronavirus ti di ọfẹ fawọn akẹkọọ ile ẹkọ girama to fẹ wọle pada.
Ijọba gbe igbesẹ ọhun lẹyin idarudapọ to waye laarin awọn obi to ni ọmọ nile ẹkọ girama ati ijọba ipinlẹ Ogun lọjọ Aiku.
Bakan naa ni ijọba pasẹ pe ki wọn pin aṣọ iboju ni ọfẹ fun gbogbo akẹkọọ to wa nipinlẹ naa, boya nile ẹkọ ijọba ni tabi ti aladani.
Awọn ọrọ yii lo foju han ninu atẹjade kan ti gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun funra rẹ fọwọsi nirọlẹ ọjọ Aje.
Gomina Abiodun ni oun kabamọ lori gbogbo idarudapọ to waye lori iṣẹlẹ naa.
O ni ipese eto ẹkọ to ye kooro ati igbaye gbadun awọn akẹkọọ ipinlẹ naa lo jẹ ijọba oun l'ogun julọ.O tun han ninu atẹjade naa pe, ayẹwo awọn akẹkọọ lati mọ boya wọn ni arun Coronavirus kii ṣe dandan mọ fawọn akẹkọọjade to fẹ wọle pada sile ẹkọ.
Ni ọjọ Aiku lawọn obi ati alagbatọ ni ipinlẹ Ogun fọn si igboro ilu Abẹokuta lati fi ẹhonu wọn han lori ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira ti ijọba ipinlẹ naa kede pe ki awọn akẹkọọ ileewe aladani o san fun ayẹwo kokoro arun COVID-19 ki wọn to lee wọle pada si ileewe.
Lati igba ti iroyin naa ti jade sita lo ti n ṣe ọpọlọpọ ni haa-hin nitori idẹyẹsi naa.
Bi ọpọlọpọ obi ṣe n pariwo pe bawo lọbọ ṣe ṣori ti inaki o ṣe to fi jẹ wi pe awọn akẹkọọ ileewe aladani ni yoo maa sanwo ayẹwo COVID-19 ki wọn to wọle pada sileewe.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ijọba ipinlẹ Ogun ninu atẹjade kan ti olubadamọran fun gomina ipinlẹ Ogun lori ọrọ Ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama, arabinrin Ronkẹ Soyọmbọ ṣalaye pe o di dandan fun awọn akẹkọ lati pese iwe ẹri ayẹwo COVID-19 wọn ki wọn to gbawọn si ileewe paapaajulọ awọn to ba wa ni ileegbe lawọn ileewe naa.
Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Ogun ni gbogbo awọn ileewe aladani ni lati rii daju pe awọn akẹkọọ wọn ni iwe ẹri yii.
Amọṣa loju opo Twitter ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC to jẹ ajọ kan ṣoṣo to laṣẹ lori eto ayẹwo fun kokoro arun naa, ọfẹ ni wọn kọ pe wọn n ṣe ayẹwo fun kokoro arun naa lorilẹede Naijiria.
Ajọ naa ni ko si ibikibi ti wọn ti n fi owo ṣe ayẹwo COVID-19 fun ẹnikẹni lorilẹede Naijiria.
Eyi lo mu ki ọpọ maa beere ibi ti ijọba ipinlẹ Ogun ti wa ri ẹdinwo owo ayẹwo kokoro arun COVID-19 ti wọn ni awọn n ṣe ati pe ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira ti wọn fẹ maa gba naa, owo ayẹwo ni ibudo wo ni?

Amọṣa, ijọba ipinlẹ Ogun ni awọn eleto ilera kan lawọn fẹ lo ati pe awọn ti ba awọn eleto ilera naa sọrọ lati pese ayẹwo ọhun fun wọn ni ẹdinwo.
Wayi o, awọn obi ti fariga pe awọn ko ni owo kankan lati san, bakan naa ni awọn ko tilẹ ni iwe ẹri kankan lati fi silẹ.
Ninu ọrọ ti wọn ba BBC News Yoruba sọ, awọn obi kan ni awọn ko ni ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira lati san, ati pe awọn ko lee gba ki ọmọ awọn la wahala ti ayẹwo naa lee ko ba ironu awọn akẹkọọ.
Kí ni ìjọba Ogun sọ nípa N25, 000 owó àyẹ̀wò COVID-19 fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí yóò wọlé padà?

Oríṣun àwòrán, theencounter.com.ng
Awọn obi awọn akẹkọ ileewe aladani ni ipinlẹ Ogun ti fariga lori owo ayẹwo fun arun COVID-19 ti ijọba ipinlẹ naa bu fun awọn akẹkọ kọọkan ni sisan ki wọn to lee wọle pada sẹnu ẹkọ wọn ni ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ.
Awọn obi awọn akẹkọọ ileewe aladani ọhun ke gbajare sita lasiko iwọde kan ti wọn ṣe ni ilu Abẹokuta lọjọ Aiku nibi ti wọn ti ni ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira ti ijọba ni ki awọn akẹkọọ ileewe aladani o san fun ayẹwo kokoro arun COVID-19 ko rọrun rara.
Awọn obi naa ti wọn ya bo ileewosan MTR Specialist Hospital nibi ti wọn ti ni ayẹwo naa yoo ti maa waye ni awọn ko gbaradi fun irufẹ owo bẹẹ ni sisan ati pe bawo lọbọ ṣe ṣori ti inaki o ṣe to fi jẹ wi pe awọn akẹkọọ ileewe aladani nikan ni yoo maa san owo ayẹwo nigba ti awọn akẹkọọ ileewe ijọba ko ni san kọbọ fun ayẹwo kokoro arun naa.
Wọn tun fi kun un pe ko si idi to fi yẹ ki ijọba kan owo naa ni ipa fun awọn akẹkọọ niwọn igba to jẹ wi pe wọn ti ni ki ileewe kọọkan o maa pese awọn ilana ati ohun elo fun ayẹwo awọn akẹkọọ ṣaaju iwọle wọn.
Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin sọ, igbakeji alaga ẹgbẹ awọn obi ati olukọ PTA ni ipinlẹ Ogun, Alagba Kẹhinde Sanwo ṣalaye fawọn oniroyin pe ko yẹ ki ijọba maa dẹyẹsi awọn akẹkọọ ileewe aladani ati si awọn akẹkọọ ileewe ijọba nitori pe ọmọ ipinlẹ Ogun naa ni gbogbo wọn.
Ninu ọrọ tirẹ, oludari eto ilera ni ipinlẹ Ogun, Dokita Olukayọde Soyinka ṣalaye pe ọrọ sisan ẹgbẹrun marundinlọgbọn owo ayẹwo kokoro COVID-19 ṣe ajeji si oun ati pe titi di asiko ti wọn n sọrọ naa, ọfẹ ni ayẹwo kokoro arun COVID-19 ni ipinlẹ Ogun .
Ati pe, aṣẹ ti oun gba lọwọ kọmiṣọna ni lati wa nibi ayẹwo naa fun idẹra awọn akẹkọọ to ba wa ṣe ayẹwo nibẹ.














