Ibadan VC Appointment: Ẹgbẹ́ ọmọ Ibadan fẹ́ kí ààrẹ Buhari yan ọmọ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọgá fásitì Ibadan

Fasiti UI

Oríṣun àwòrán, UI

Agbarijọpọ awọn ọmọ bibi ilu Ibadan ti ke gbajare si aarẹ Muhammadu Buhari lati foju aanu wo awọn ko fi yan ọmọ bibi ilu Ibadan si ipo ọga agba fasiti ilu Ibadan.

Arọwa yi to wa lati ọdọ aarẹ ẹgbẹ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC ko ṣẹyin bi eto iyansipo ẹni ti yoo jẹ ọga fasiti naa lẹyin ti saa Ọjọgbọn Abel Olayinka to jẹ ọmọ ipinlẹ Osun ba pari.

Oloye Adeyemi Soladoye, aarẹ ẹgbẹ ni awọn ọmọ Ibadan ti ṣe suuru to lati igba ti wọn ti da fasiti naa silẹ ati pe aika nkan kun awọn ti to gẹ bayi.

''Awa ọmọ Ibadan kii ṣe oni wahala nii nitori rẹ lo fi dabi ẹni pe a ko tii sọrọ lati nkan bi ọdun mejilelaadọrin ti wọn ti da fasiti Ibadan silẹ pe ki wọn yan ọmọ Ibadan ni ọga fasiti naa.''

''Lọpọ igba ni awọn ọmọ wa ti yẹ ki wọn de ipo yi ṣugbọn niṣe ni wọn maa n doju ọrọ ru ti wọn yoo si yan ẹlomiran sipo.''

Soladoye fi kun un pe ''Nigba to ti wa di pe kii ṣe ẹni to ba gbe igbaoroke ni wọn yoo mu, a fẹ ki aarẹ o mu ọmọ wa ninu awọn ti orukọ wọn ba de ọdọ rẹ''

Agbarijọ ọmọ ẹgbẹ Ibadan

Oríṣun àwòrán, Premium Times

Àkọlé àwòrán, Aworan ọmọ ẹgbẹ Ibadan lasiko ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ

''Awọn ọmọ wa koju oṣunwọn, o si yẹ ki aarẹ wo nkan mii mọ Ibadan lara lati yan ọmọ wa si ipo ọga fasiti Ibadan.''

Bawo ni iyansipo ọga fasiti ti ṣe maan waye?

Ọdọ Aarẹ orileede Naijiria ni aṣẹ wa lori ẹni ti wọn yoo yan ni ipo ọga fasiti lẹyin ti awọn igbimọ ayẹwo ti fasiti ba yan ti fi orukọ eeyan mẹta tabi mẹrin ṣọwọ si.

Ni ibamu pẹlu ofin to da awọn fasiti ijọba apapọ silẹ, ẹnikẹni to ba ti kaju oṣunwọn ni ijọba lẹtọ lati yan lai fi ti ibi to ti wa ṣe.

Lọpọ igba awọn fasiti Naijiria a ma ni fakinfa lori yiyan ọmọ ilu gẹgẹ bi ọga fasiti ijọba apapọ.

Bi awọn ara ilu ba ti ṣe n ni ki ijọba yan ọmọ wọn lawọn alakoso yoo ma sọ pe ilana ko yọ ẹnikẹni silẹ.

Yatọ si ipo ọga agba fasiti Ibadan, Oloye Adeyemi sọ pe o wu awọn bakan naa ki aarẹ yan ọmọ Ibadan si ipo ọga agba ile ikọṣẹ iṣegun fasiti Ibadan,UCH.

O lootọ awọn ko ni ikapa kankan lati mu aarẹ ni dandan ṣugbọn o ti wa fẹ di lemọlemọ pe wọn yoo fi ọmọ Ibadan to kaju oṣunwọn silẹ ti wọn yoo si yan ọmọ Ilu mi sipo ọga fasiti Ibadan.