Shoprite leaving Nigeria: Ṣé òótọ́ ni pé Tayo Amusan ni yóò gba ìṣàkóso ilé ìtajà Shoprite?

Aworan Tayo Amusan ati ile itaja Shoprite

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Kii ṣe tuntun mọ pe ile itaja Shoprite ti n gbaradi lati kogba kẹru rẹ kuro ni Naijiria, bo tilẹ jẹ pe ako tii le fi idi rẹ mulẹ, ṣugbon iroyin to n lọ ni igboro sọ pe olowo kan, Tayo Amusan ni yoo gba iṣakoso ileeṣẹ naa.

Tuntun ti a rigbọ ni pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọhun ni wọn kan fẹ ṣe atunṣe abẹle nikan ni, lodi si ọrọ to n lọ kaakiri pe wọn fẹ gbe ileeṣẹ ọhun ti patapata.

Ninu ọrọ ti wọn sọ lọjọ Aje, wọn ni wọn fẹ gbe akoso ileeṣẹ naa le ọmọ Naijiria lọwọ ni.

Ọpọ awọn to ti jẹ ṣeku lo ti n woye lati gbakoso ileeṣẹ naa, ṣugbọn orukọ ẹni ti awọn eeyan n jẹ lẹnu ju ni Tayo Amusan.

Àkọlé fídíò, 'A ò tíì rí omi mu, ẹ ní ká máa fọwọ́ tóríi Coronavirus'

Tani Tayo Amusan gan?

Tayo Amusan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

  • Oniṣowo ni Tayo Amusan, ẹni ọgọta ọdun ni, biliọnia si ni pẹlu.
  • O jẹ ẹni ti o maa n sowo ilẹ ati ile, o si maa n ko awọn ọja rẹ si inu ile Shoprite kaakiri ilẹ Afrika.
  • Lọwọ yii, oun ni alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Persianas Nigeria Limited to maa n kọ ilegbe, ile itaja, ile itura atawọn ile miran lati ọdun 1990.
  • Oun kan naa lo da ile itaja The Palms Mall silẹ, lẹyin naa lo tun ṣi awọn ile itaja miran ni ilu Enugu, Kwara, Ota ati Ibadan.
  • Amusan tun jẹ ọkan lara ikọ adari awọn miran ileeṣẹ bii Garages Limited ati Southern Petroleum Limited.
  • Ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Keje ọdun 2019, Amusan kọwe fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi adari ati alaga igbimọ adari ileeṣẹ Resourcery Plc.
  • Ọmọ Yoruba ni Amusan, orukọ iyawo rẹ si ni Ayo Amusan.
  • Ọjọ Aje, ọjọ kẹta oṣu Kẹjọ ọdun 2020 ni iroyin gbode pe ile itaja Shoperite n mura lati fi orilẹ-ede Naijiria silẹ lẹyin ọdun marundinlogun ti wọn ti n ṣowo.
Àkọlé fídíò, Toríi "Coro", ẹ wo bí ètò ìsìn ìgbéyàwó orí ayélujára Zoom ṣe lọ

Wo àwọn iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè tó ti kógbáwọlé rí ní Nàìjíríà àti ìdí

Awọn ileeṣẹ ilẹ okere

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 ni iroyin kan gbode pe gbajugbaja ile itaja Shoprite fẹ kogbawọle ni Naijiria nitori airi ere jẹ latari ajakalẹ arun Covid-19 to mi gbogbo agbaye titi.

Ile itaja naa to wa lati orilẹede South Africa ṣi ṣọọbu rẹ akọkọ si ipinlẹ Eko lọdun 2005, lati ọdun naa lo si ti n gbilẹ sii ni Naijiria.

Ṣugbọn kii ṣe Shoprite ni akọkọ ile iṣẹ lati ilẹ okeere ti yoo kogbawọle ni Naijiria, ọpọ ileeṣẹ lo ti wa to si ti lọ ṣaaju rẹ, lara wọn ree:

Woolworths Holdings Ltd

Ileeṣẹ naa to n ta ounjẹ ati aṣọ loju pali ṣi ṣọọbu rẹ ni Naijiria lọdun 2011 ṣugbọn lẹyin ọdun kan atabọ lọ lo kogbawọle, to si tilẹkun ṣọọbu rẹ mẹtẹta to wa lorile¬ede yii.

Adari ileeṣẹ naa lọdun naa lọhun, Moir Dem, sọ ninu atẹjade kan pe idi ti wọn ṣe ti ṣọọbu ọhunn ko sẹyin ọwọngogo iye owo ile itaja ati iṣoro pinpin ọja ka.

Bo tilẹ jẹ pe o ti kuro ni Naijiria, ileeṣẹ naa ṣi wa lawọn orilẹ-ede miran ni Afrika.

Tiger Brands

Tiger Brands

Oríṣun àwòrán, Reuters

Nigba ti ileeṣẹ Tiger Brands wọ Naijiria lọdun 2012, ida mẹtalelọgọta owo rẹ lo fi ṣowo nileeṣẹ Dangote, eyii to mu ko jẹ ọkan gboogi lara awọn to lẹnu nibẹ.

Ṣugbọn nigba to di ọdun 2015 ni wọn kọrin mi o ṣe mọ, ti wọn si ta ileeṣe ̣hun fun Dangote patapata.

Ọga ileeṣẹ naa, Noel Doyle, sọ pe wọn ko jere mọ ni wọn ṣe lu ileeṣẹ n ni gbanjo fun Dangote.

Etisalat UAE

Etisalat UAE

Oríṣun àwòrán, ETISALAT UAE/FACEBOOK

Ọkan gboogi lara awọn ileeṣẹ to jere ju lagbaye ni Etisalat, eyii to mu ki wọn lamilaaka ni orilẹ-ede marundinlogun.

Ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ ọhun to wa lati orilẹ-ede United Arab Emirate lọdun 2008nde ipo kẹrin lara awọn ojugba rẹ ni Naijiria.

Ṣugbọn o fi Naijiria silẹ lọdun ni 2017 latari airi ere jẹ, gbese gọbọi atawọn nnkan miran.

Lẹyin naa ni wọn pa aṣọ eṣi rẹ da ni Naijiria si 9mobile.

Dunlop ati Michelin

Dunlop ati Michelin

Oríṣun àwòrán, DUNLOP/FACEBOOK

Taya ọkọ ni ileeṣẹ Dunlop ati Michelin n ṣe ni Naijiria, wọn si lamilaaka laye igba tiwọn.

Ọdun 1961 ni wọn da ileeṣẹ ọhun silẹ, ṣugbọn lara awọn ohun to mu ko kogba wọle ni ina ọba ti ko ṣe dede ati awọn igbesẹ ijọba apapọ miran.

Wọn kogba wọle lọdun 2008, ọpọ si ti n gbagbe orukọ wọn, koda, awọn ọmọ aye ode oni ko mọ orukọ to n jẹ Dunlop tabi Michelin.

HSBC ati UBS

HSBC ati UBS

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn ileeṣẹ mejeji yii naa lorukọ nigba aye wọn, ṣugbọn ọdun 2018 ni wọn tilẹkun ṣọọbu lai sọ eredi ti wọn fi gbe igbesẹ naa.

Banki apapọ Naijiria, CBN, lo kọkọ kede idagbere wọn lọdun 2017.

Ṣe lootọ ni awuyewuye to gbode kan pe Shoprite fẹ kogba wọn kuro ni Naijiria?

Ile itaja Shoprite

Oríṣun àwòrán, OTHER

Idahun: 'Irọ́ ni o, àò pinnu láti kógbá Shoprite wọlé ní Nàìjíríà'

Awọn alaṣẹ ile itaja nla Shoprite ti sọ pe awọn ko gbeero lati fi opin si okoowo wọn ni orilẹ-ede Naijiria.

Ile itaja Shoprite lo tobi julọ ni Africa, ẹka rẹ si to ẹgbẹrun mẹta o din igba jakejado ilẹ Afirika.

Owurọ kutu ọjọ Aje ni iroyin gba igboro pe ile itaja naa fẹ ẹ kuro.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, awọn alaṣẹ Shoprite sọ pe awọn n wa ẹni ti yoo ra ẹka to wa ni Naijiria.

Ile itaja nla naa gba o kere tan ẹgbẹrun meji ọmọ Naijiria siṣẹ.

Agbẹnusọ fun agbaninimọran kan fun ileeṣẹ naa, Ọgbẹni Ini Achibong sọ fun akọroyin BBC pe o ti ṣe diẹ ti ileeṣẹ naa ti polowo wiwa awọn ti yoo ra a, ṣugbọn ohunkohun ko yipada.

Àkọlé fídíò, Oyo Schools: Akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì, Poly wà nílé, kí ló mú ti alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, girama wà níta?

Shoprite ni ileeṣẹ awọn ọmọ orilẹ-ede South Africa kẹta ti 'yoo fi Naijiria silẹ.

Laipẹ yii ni ileeṣẹ aṣọ Mr Price dawọ okoowo rẹ ni Naijiria duro. Bakan naa ni Woolsworth ṣe lọdun 2014.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita, Ile itaja nla to wa lati ilu Cape Town lorilẹede South Africa yii sọ pe esi ere ti awọn ri lọdun yii ko fiṣẹ yin awọn rara latọdun ti wọn ti n taja ni Naijiria.

Fun idi eyi, wọn ni ina awọn ko lee wọ mọ lorilẹede yii.

Awọn ile itaja nla nla yatọ fun ti Naijiria lo n kopa ida to fẹrẹẹ to mejila ninu itaja ọlọwọọwọ eyi ti ere wọn si ti n ja walẹ lati ọdun 2018.

Ẹwẹ, nitori isede to wa lode bayii, iye awọn onibara to n lọ si Shoprite dinku pẹlu nkan bii ida meje abọ.

Ni wọn ba pinu lati ko ẹru wọn kuro ni ilu.

Àkọlé fídíò, Toríi "Coro", ẹ wo bí ètò ìsìn ìgbéyàwó orí ayélujára Zoom ṣe lọ