Lagos gas explosion: Afẹ́fẹ́ Gáàsì tó rọra ń yọ́ọ́ jò pa Ajibola lẹ́nu iṣẹ́ jórin-jórin

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA ti ri oku olukṣẹ kan latarii ibugbamu gaasi to ṣẹlẹ ni agbegbe ibudokọ Alafia ni Orile Iganmu, ipinlẹ Eko.
Ggẹ bi iroyin iwadii ti wọn ṣe ṣe sọ ọ ati ọrọ lẹnu awọn eeyan oṣojumikoro, ohun to fa sababii iṣẹlẹ aburu yii ni afẹfẹ gaasi to rọra n yọọ fiiin jo jade lataraagolo nla gaasi to si fa iku olukọṣ to n lo o lati fi jo irin mọ irin.
Oloogbe naa, Ajibola Olaoye padanu ẹmi rẹ nibẹ naa nigbati awọn mẹrin mii fara gba iṣẹlẹ ọhun ti wọn fara pa gidi amọ wọn ti sare gbe wọn lọ sileewosan kan to wa ni tosi.
- Inú odò ni wọ́n ti rí òkú ọmọ ọdún méjì tó sọnù l'ọ́jọ́ ọdún Eid nílùú Ibadan
- Coronavirus já wá sílẹ̀ ju ti àt'ẹ̀yìn wá lọ, kò ju èèyàn 288 tó kó o lọ́jọ́ Ajé
- A ṣe sùúrù tó, ọmọ wa ló gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀gá fásitì UI lọ́tẹ̀ yìí - àkóríjọ́ ẹgbẹ́ ọmọ Ibadan
- 'Irọ́ ni o, àò pinnu láti kógbá Shoprite wọlé ní Nàìjíríà'
Ohun ti ajọ LASEMA gaan ba nigba ti wọn debẹ ni pe ibugbamu gaasi ọhun ti ṣẹlẹ eyi to n lo lati fi jo irin ninu ọkọ akẹru nla torii pe gaasi naa n yọọ jo jade.
Ẹwẹ, ki awọn ikọ aṣeranwọ gan to de ni iku Ajibola ti waye ati ti wọn si tun ti gbe awọn mẹrin to fara pa nibẹ lọ sile iwosan.
Ajọ LASEMA, awọn ọlọpaa, ileeṣẹ panapana Eko atawọn oṣiṣẹ alaabo mii lo tara ṣaṣa lọ sibi iṣẹlẹ ọhun ti wọn si gbakoso gbogbo adugbo naa ki iṣẹlẹ ọhun ma baa bimọ mii.
Nibayii, wọn ti gbe oku Ajibola fun ẹbi rẹ.









