Abuja: ọ̀rọ̀ Lake Chad di àpérò ọmọ eríwo fún àwọn Minisita

Lake Chad

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn Minisita náà tí yóò péjọ sí Abuja yóò sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà àbáyọ sí ètò ààbò àti ìdókòwò lágbègbè Lake Chad.

Ọrọ to ba ti gba apero ti di nkan nla to ń fẹ́ àmójútò.

Awọn Minisita lati ẹkun ati agbegbe Lake Chad Basin yoo ma a pejọpọ si olu ilu Naijiria lati jiroro lori ọna ibasepọ laarin awọn orilẹ-ede to wa ni agbeegbe Lake Chad Basin naa.

Ipade yii n waye lẹyin ọdun mẹwaa ti awọn agbesunmọmi Boko Haram ti bẹrẹ si nii ṣe iku pa awọn eniyan lagbegbe naa.

Ajọ to n bojuto agbegbe Lake Chad (The Lake Chad Basin Commission, LCBC) ati Ajọ Ilẹ Afirika, the African (AU) ni wọn n se alakoso ipade naa, eleyii ti yoo mu ki awon minisita naa o buwọlu adehun eto aabo to muna doko lasiko naa.

Àkọlé fídíò, Ìjẹ̀bú: Àgbàlàgbà ni mo máa ń ṣe nínú eré tẹ́lẹ̀

Iroyin fi lede pe adehun to ba jade lati ipade naa ni wọn yoo lo lati fi koju awọn ikọ agbesunmọmi bii Boko Haram to n daamu agbeegbe naa.

Àkọlé fídíò, Ilu Ubang, jẹ ilu kan nibiti ede ti awọn ọkunrin wọn n sọ yatọ si ti awọn obinrin wọn.
Àkọlé fídíò, Oriọla: ó yẹ kí a jẹ́ káwọn ọmọ ìsinyi mọ pàtàkì ṣíṣe eré ìdárayá papọ̀