Ọṣun; Àwọn aláìsàn ojú ké sí ìjọba láti ràn wọ́n lọ́wọ́

"Lootọ ni oju n dunmi; ṣugbọn airi itọju ni o koba oju mi."
Ọrọ yii lo ti ẹnu alagba Ahmed Lamidi, ẹni ọgọrin ọdun jade ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba ni aafin ọba ilu Ifọn orolu nipinlẹ Ọṣun.
Alagba Lamidi wa lara awọn eeyan ilu Ifọn-Orolu nipinlẹ Ọṣun to wa fun iwosan ọfẹ fun aisan oju wọn.
Alagba Lamidi ni aisi owo ti fọ oju ọpọlọpọ oju awọn eeyan ni ẹsẹ pupu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọdun mejila ni alagba ẹni ọgọrin ọdun naa ni oju oun ti kọkọ bẹrẹ ki o to di pe o fọ nitori aisi owo lọwọ rẹ pẹlu ọwọngogo itọju aisan oju.
"O dara ki ijọba maa gbe eto ilera ati iwosan oju wa si ẹsẹ pupu nitori aisi owo ati bi itọju aisan oju ṣe di ọwọngogo lo n fa ọpọ oju to n fọ laarin awọn ọmọ orilẹede Naijiria."

Bakan naa lawọn to laisan oju ti wọn wa sibi eto iwosan ọfẹ lori aisan oju naa ni wọn pariwo sita pe asiko to fun ijọba lati ṣe iranwọ ti yoo mu adinku ba iye owo ti wọn n san fun itọju aisan oju lorilẹ-ede Naijiria.
Arabinrin Ọlayiwọla Abọsẹde sọ fun BBC Yoruba pe ''oju popo ni oun ti n ta ọja lati fi bọ ẹbi ki o to di pe oun ṣakiyesi pe oju oun n wo bayi-bayi.
"O ti n lọ bii ọdun kan abọ ti oju yii ti wa bayii, o si ṣeeṣe ki oju mi maa ri bayii kani agbara mi gbe inawo rẹ ni."

Ninu ọrọ tirẹ, Dokita iwosan oju, Echetta Ugonna ṣalaye pe aimọkan, aisi iroyin to to ati ọwọngogo itọju aisan oju n ṣe akoba fun awọn ti oju n yọ lẹnu lorilẹ-ede Naijiria, paapaa lẹsẹ pupu.
Dokita Ugonna ni lootọ omi lee ṣebi ẹni pọ ju ọka lọ fun ijọba lori eto iwosan ati ilera oju, ṣugbọn ohun to tọna bayii ni ki awọn ti Ọlọrun ṣẹgi ọla fun lawujọ o dide fun ipese owo lati seto itọju fun awọn ti oju n dun lawujọ.















