Ìjọba ìpínlẹ̀ Òndó àti Zamfara ya ọjọ́ sọtọ fún gbígba PVC

Awọn kaadi idibo

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Àkọlé àwòrán, Iye kaadi idbo ti awọn eeyan ko tii gba n kan ọpọ lominu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iroyin to n te wa lọwọ ni pe ọgọọrọ eniyan lo tu jade lati lọ gba kaadi idibo PVC won, leyin ti Ajo eleto idibo kede ojo kokanlelogbon, osu kejo gege bi ojo ti won yoo pari gbigba kaadi naa.

Ọgọọrọ awon eniyan to tu jade ko ṣẹyin bi ipinlẹ Ondo ati Zamfara se gbe igbesẹ lati rii pe awọn ara ilu wọn gba kaadi idibo PVC wọn pẹlu yiya ọjọ isinmi sọtọ lati lọ gba.

Ọjọbọ tìi se ọgbọn ọjọ, osu kẹjọ ni Ipinlẹ Ondo kede gẹgẹ bi ọjọ isinmi nigba ti ipinlẹ Zamfara si kede Ọjọ Ẹti ti i se ọjọ kọkanlelọgbọn, Oṣù Kẹjọ.

ONDO
Àkọlé àwòrán, Ọjọ́ kọkanlelọgbọn, oṣù kẹjọ ní Àjọ eleto ìdìbò INEC kéde gẹgẹ bí gbendeke fún gbígba káàdì ìdìbò PVC.
Ondo
Àkọlé àwòrán, Lai pe yi ni iroyin kan gbode pe o to kaadi idibo 315,000 ti awọn oludibo ko ti ri gba nipinle Kwara.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn,Osu Kẹrin, ọdun 2017 ni ajọ eleto idibo INEC bẹrẹ eto iforukọsilẹ fun eto idibo ni orile-ede Naijiria.

Lẹyin ti wọn ri wi pe kaadi idibo ti awọn oludibo to f'orukọ silẹ ko tii wa gba pọ kaakiri awọn ileeṣẹ ajọ naa lorilẹ-ede Naijiria ni ti wọn kede isunsiwaju ọjọ gbedeke fún gbígba PVC.

Loju ọpo Twitter INEC, wọn fi ikede iye awọn to ti gba kaadi wọn ati iye awọn kaadi ti wọn ko ti wa gba pe...

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Kini o n se idiwọ gbigba kaadi fun awọn oludibo

Ni awọn aye iforukọsile ti ile isẹ BBC se abẹ́wo si, nise ni awọn oludibo kun ibẹ̀ rẹpẹtẹ.

Ọpọ awọn to ba BBC sọrọ si salaye pe iye awọn osise ajo eleto idibo to wa ni ilẹ̀ kere si iye awn eeyan to wa gba kaadi.

Folayemi Busoye to je adari ni aaye kan ti BBC kan si ni agbegbe Ikoyi nilu Eko so pe kii se kaadi tuntun nikan lawọn n fun awọn oludibo ni aaye naa.

''Awọn to sọ kaadi nu to fe gba kaadi tuntun miran naa n wa si ibi.''

Aworan oludibo to mu kaadi idibo rẹ lọwọ
Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan kan ti forukọsilẹ tipẹ ti wọn ko si ti ri kaadi idibo wọn gba

Lai pe yi ni iroyin kan gbode pe o to kaadi idibo 315,000 ti awọn oludibo ko ti ri gba nipinle Kwara.

Garba Madami to jẹ alamojuto eto idibo nipinlẹ naa lo salaye ọrọ yi fun awọn oniroyin .

O ni eeyan 1.2 milionu ni wọn letọ lati kopa ninu idibo gbogbogbo ọdun 2019 lati ipinlẹ naa sugbọn eeyan 160,000 tutun lo sẹsẹ fi orukọ silẹ ninu eto iforukọsilẹ to n lọ lọwọ.

Gẹgẹ bi nnkan ti ajọ INEC sọ,gbigba kaadi idibo yoo tẹsiwaju titi di igba ti idibo ọdun 2019 ba sun mọ sugbọn etọ iforukọsilẹ yoo wa si ọpin ni Ọjọ́ kọkanlelọgbọn oṣù kẹjọ

Àkọlé fídíò, Ìjẹ̀bú: Àgbàlàgbà ni mo máa ń ṣe nínú eré tẹ́lẹ̀
Àkọlé fídíò, 'O yé kí ìbáṣepọ̀ Nàìjíríà àti UK dán mọ́rán síi lẹ́yìn àbẹ̀wò May'