Omotola Jalade Ekeinde: Òjòjò Covid-19 ló mú mi, mò ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́

Omotola Jalade Ekeinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omotola Jalade Ekeinde

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọrọ arun coronavirus to n ba gbogbo aye finra ko mọ olowo, bẹẹ ni ko mọ talaka, koda ko mọ ọmọde, ko mọ agba.

Arun naa tun ti mu gbajugbaja oṣere tiata, Omotola Jalade Ekeinde, to si kede loju opo Twitter ati Facebook rẹ pe, ojojo arun ọhun ni ko jẹ ki oun yọju sita lati ọjọ yii wa.

Ekeinde ṣalaye pe ohun ti wa ni iyasọtọ lẹyin ti oun lugbadi aarun naa, ara oun si n ti n pada bọ sipo diẹdiẹ bayii.

O ṣeleri lati maa sọ fawọn ololufẹ rẹ, bi ara rẹ ba ti n ṣe sii looree kooree.

Ẹwẹ, ọgọọrọ awọn ololufẹ Ekeinde ni wọn gbadura fun ilera to peye fun un, wọn ni laipẹ lai jina, Eleduwa yoo mu un lara da.

Awọn miiran tun gbadura pe Omotola ni yoo bori coronavirus, wọn covid-19 ko ni rẹyin rẹ.

Omotola ni oun ko ṣai gbọ iroyin bi ọkọ tirela ati apoti ikẹru ti wọn n pe ni ''container'', ti n ṣeku pa awọn ọdọ niluu Eko.

Omotola sọ pe, ohun to buru jai ni iru iṣẹlẹ yii, o wa ke si Gomina Babajide Sanwo-Olu lati wa nnkan ṣe si ọrọ awọn ọkọ tirela to da ẹmi awọn araalu, papaajulọ awọn ọdọ, legbodo.

Gbajumọ oṣere naa ni adura ti onikaluku maa n gba naa ni pe, ki aburu maa ṣẹlẹ si ẹnikọọkan, ṣugbọn o ni ko si ẹni ti iru iṣẹlẹ bẹẹ ko le ṣẹlẹ si i.