Lanre Rasak: Èàkàn ẹgbẹ́ òṣèlú APC mií Lanre Rasak dágbére fáyé

Oloogbe Lanre Razak

Oríṣun àwòrán, Other

Eekan ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, Lanre Razak ti jade laye lẹni ọdun mẹrinlelaadọrin.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe Ọgbẹni papoda lọjọ Abamẹta ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹjọ ọdun 202o yii lẹyin aisan ranpẹ.

Nigba aye rẹ, Ọgbẹni Razak wa ninu igbimọ to n gba gomina ipinlẹ Eko lamọran.

Ọgbẹni Rasak kọkọ fi erongba rẹ rẹ han lati dije fun ipo ṣenẹtọ lẹkun ila oorun ipinlẹ Eko ki o to yọwọ nibẹ ṣaaju ibo abẹle.

Ọjọ Aiku ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹjọ yii ni wọn yoo ṣin Ọgbẹni Rasak ni ilana ẹsin musulumi.