One million boys nìkan kọ́ lẹgbẹ́ òkùnkùn tó n dá Eko rú, 'Awawa Boys' náà tún wà níbẹ̀

Ibẹru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọn ni Bibeli wi, ṣugbọn ibẹru awọn Awawa Boys ni awọn agbegbe kan nilu Eko ni ipilẹṣẹ eto aabo.
Aburu kekere kọ ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa n ṣe ni awọn agbegbe bi i Agege, Ogba, Ifako-Ijaiye, Iyana-Ipaja, ati Abule Egba.
Ọpọ eeyan to si ti kagbako ijamba lọdọ awọn ọmọ ẹgbẹ yii, lo le sọ bo sẹ ri, nitori pe iroyin ko to afojuba.
Ọjọ ti pẹ ti awọn ọmọ ẹgbẹ Awawa ti n ṣoro bi agbọn, ṣugbọn ariwo tun sọ lori wọn laipẹ yii, lasiko isede coronavirus.
Ojoojumọ fun bi ọsẹ kan gbako ni ariwo fi n sọ ni awọn agbegbe ti a mẹnuba tẹlẹ, ati awọn miran to yi wọn ka.
Awọn ara adugbo ko loju orun, ti wọn si n dana sun taya ọkọ laarin oru ti wọn ba n ṣọ adugbo koowa wọn.
- Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ láàrín àwọn ọ̀dọ́ ní Oke Odo ní ìpínlẹ̀ Eko
- Wàhálà tí àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn àt'àwọn ẹgbẹ́ ìjayà míràn ń dá sílẹ̀ láwọn ọgbà fásitì Nàìjíríà
- Ohun tí o kò mọ̀ nípa Ebila "One Million Boys" àti Ekugbemi, olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì tó da ìlú Ibadan rú
- Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe pa Ebila, olórí àwọn "One million boys" n'Ibadan
Eyi ko ṣẹyin bi awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Awawa ṣe n ka awọn eeyan mọle lọganjọ oru ati ọsan gangan lasiko ti ijọba kede konile-o-gbele nitori itankalẹ coronavirus l'oṣu Kẹrin, ọdun 2020.
Igba ti awọn ọlọpaa to kapa wọn ni awọn ara ilu to sun oorun asun forile oṣuka.
Awọn ẹsun bi idigunjale, ati ifipabanilopọ ni wọn fi n kan awọn janduku naa.
Koda, iroyin sọ pe ile ti wọn ba wọ, ti baale ile ibẹ ba kọ lati fun wọn lowo, bibasun ni iyawo rẹ, tabi ki wọn o ṣe ọkunrin naa yanna-yanna.
A ko le sọ ni pato, iru eeyan ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii jẹ, ṣugbọn awọn akọsilẹ kan sọ pe awọn ọdọ ẹya Hausa lo pilẹ rẹ, ki awọn ẹya miran to o tun ma a darapọ mọ wọn.
Agege nilu Eko ni orisun ẹgbẹ yii. A gbọ pe ni igba ti ẹgbẹ naa ṣẹṣẹ n bẹrẹ, niṣe ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa yoo ko ara wọn jọ lọ si ibi ayẹyẹ ti wọn ko pe wọn si.
Wahala ati ipalara si lo maa n jẹ fun ẹni to n ṣe ayẹyẹ, to ba kọ lati fun wọn ni gbogbo nkan ti wọn ba beere fun un, bi ounjẹ, ọti, ati owo.
- Ẹ̀yin ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn tẹ fẹ́ ṣe àjọ̀dún lónìí, lákọ la ń dúró dè yín - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe pa Ebila, olórí àwọn "One million boys" n'Ibadan
- Ìsìpẹ́kítọ̀ d'àwátì, jàndùkú fara gbọta nínú ìjà ọlọ́pàá ati aráàlú ní Ogun
- Àwọn àádọ́ta ọ̀dọ́ wọ gàù nítorí ilé ijó ní Ilorin
- Ènìyàn 653 míràn tún kún iye àwọn tó ní COVID-19 ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, others
A ti ẹ gbọ pe wọn maa n gbakoso oju agbo mọ oninawo lọwọ ni, ti gbogbo elere ti wọn ba pe sibi ayẹyẹ si gbọdọ maa fi orin to wu wọn sinu rẹkọọdu.
Lara iyalẹnu to wa lori ọrọ ẹgbẹ yii ni pe, tako igbagbọ pe ọkunrin nikan lo maa n wa nidi ipanle, ati ẹgbẹ okunkun, awọn ọdọmọbinrin naa wa ninu ẹgbẹ Awawa Boys.
Ọjọ ori ọpọlọpọ wọn kii si i ju ọdun mẹẹdogun si mọkandinlogun.
Awọn iroyin kan ti a ko le e fidirẹmulẹ ti ẹ sọ pe awọn ọmọbinrin naa ni wọn fi maa n dẹ ọkunrin ti wọn ba fẹ ẹ kọlu.
Awọn ọmọbinrin naa yoo kọnu ifẹ si ọkunrin naa, ti ko si gbọdọ kọ. Eyi tumọ si pe ọkunrin naa ti di orisun ounjẹ wọn fun asiko pupọ.
Ilana ti Awawa Boys n gba ṣoro
Wọn maa n pọ babi lasiko ti wọn ba fẹ ẹ ṣisẹ.
Wọn le to ọgọta si ọgọrun, eyi to ma n mu ko nira lati da ẹnikẹni ninu wọn mọ.
Awọn irin'ṣẹ oloro keekeke bi bileedi, ìṣó, irin ẹlẹnu ṣomu-ṣomu, tabi aake ati ada lasiko ti 'ogun ba le'.
Wọn tun gbajumọ fun lilo adalu oogun oloro bi i Codeine, Rephnol, Tramadol, ati igbó.
Awọn kan sọ pe wọn ma n lo Tramadol naa lati le ni okun fun ifipabanilopọ, to jẹ ọkan pataki lara iṣẹ buruku ọwọ wọn.
A tun gbọ pe, wọn ma n fi ijo fa oju eero mọra, nibi ayẹyẹ, kanifa, ati nile ijo. Amọ, ẹni ti ko ba kiyesara yoo padanu nkan ini rẹ sọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa to darapọ mọ ero iworan.
Ijọba ipinlẹ Eko gba awọn kan lara wọn siṣẹ
Ninu oṣu Keje, ọdun 2019 ni Alaga igbimọ amuṣẹya nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Olayinka Egbeyemi, kede pe ajọ naa ti gba mẹwa lara ọmọ ẹgbẹ Awawa siṣẹ.
Egbeyemi sọ pe awọn eeyan naa jẹwọ fun oun pe airiṣẹ ṣe lo mu ki awọn o darapọ mọ ẹgbẹ okunkun, ati pe awọn yoo di ẹda tuntun ti awọn ba n ri iṣẹ aje ṣe.
Awọn igba ti wọn ti bọ sọwọ ọlọpaa
Ninu oṣu Kẹsan, ọdun 2019, ni iroyin jade pe ọwọ ọlọpaa titẹ olori ẹgbẹ naa, Tobi Akinbayo a.k.a Scorpion, ti wọn fura si pe oun ni ọga patapata fun ẹgẹ naa.
Ẹsun ti wọn ni wọn n wa fun ni ipaniyan, idigunjale, ati awọn iwa to ni i ṣe pẹlu ẹgbẹ okunkun.
Ninu oṣu Kejila bakan naa, ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọwọ tẹ mẹrinlelogun lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni Mosafejo, l'agbegbe Oshodi nilu nipinlẹ Eko.
- Akanbi mi, má fọ̀ ọ́, mo wà pẹ̀lú ẹ; ẹni tó ṣe ìgbéyàwó olórùka ló l'ọkọ- Lizzy Anjorin
- Ó yẹ kí ìjọba gbé ilé ìwé tì pa títí di ọdún 2021- ASUU
- Èèyàn 789 gbèkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra nítorí COVID-19 ní Nàìjíríà
- Lẹ́yìn gbogbo sinimá oríta ní Ondo, Akẹti jáwé olúborí ní APC
- Òògùn ìtura dé fún Coronavirus! Ọ̀dọ̀ fásitì jànkàn Oxford ló ti jáde
















