World cultism day, Cultism in Nigeria: Afurasí sọ fúnlé ẹjọ pé ẹgbẹ́ búburú tóun kó ló ṣàkóbá fún òun

Bawo ni ẹgbẹ́ okunkun se bẹ̀rẹ̀?
Wàhálà tí àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn àt'àwọn ẹgbẹ́ ìjayà míràn ń dá sílẹ̀ láwọn ọgbà fásitì Nàìjíríà
Akẹkọọ ọlọdun kini fasiti Naijiria kan ni Roland jẹ nigba to darapọ mọ ẹgbẹ okunkun Buccaneers.
Laarin oru ni wọn ṣe etutu igbaniwọle ṣẹgbẹ fun un ninu igbo kijikiji.
Awọn to ba ninu ẹgbẹ naa rọ yika wọn, wọn si fi orin, ilu, ijo ati egba to le ki oun ati awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun miiran kaabọ bẹrẹ lati oru titi di afẹmọjumọ.
- Boris Johnson kéde pé òun ti fipò olóotú Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí sílẹ̀
- Ìgbẹ́jọ́ Ike Ekweremadu ní London ń tẹ̀síwájú lónìí
- Ìpalẹ̀mọ́ ọjọ́ Arafah, ìmọ̀ràn mẹ́wàá rèé láti lè mú Hajj rọrùn f'álálàhájì
- Ọwọ́ ọlọpàá tí tẹ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn tó ṣekú pa Uwaila
- Ọwọ́ bàtá Auxiliary tó ń ró ní àrójù, leè ya láìpẹ́ - Ìjọba Oyo dúnkookò
Pataki etutu yi ni ki wọn ba le gbọn gbogbo ojora kuro lara wọn kí wọn si sọ wọn di akin.
Roland sọ fun BBC pe "Bi o ba fi le wọ ibẹ ti o si jade, o ti di ẹlomiran ni yen,"
Awọn ẹgbẹ okunkun yi ni orisirisi orukọ bi Vikings, Black Axe, Eiye ati Buccaneers.
Wọn a ma tẹle ilana ipasẹ eleyi to fara jọ t'awọn ologun.
Wọn a ma lo ọrọ ti o se pe awo lo le ye, ọgbẹri ko le mọ koda wọn a tun ma lo ami idanimọ to ṣafihan irinṣẹ ijayi wọn fẹran julọ pẹlu awọ ti wọn ṣa lesa.
Wọn a ma fi da ọmọ ẹgbẹ wọn loju pe mimi kan ko le mi wọn lati ọdọ awọn ẹgbẹ to ku.
Agbara ati gbajumọ wa lara nnkan ti wọn fi n tori rẹ ṣẹgbẹ okunkun.
Ijọba Naijiria tapa si jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn si ti n fi panpẹ ofin mu ogunlọgọ awọn to darapọ mọ awọn ẹgbẹ yi.
Sibẹsibẹ awọn ẹgbẹ wọn yi ko jáwọ nínú iwa buruku yi ti wọn si n pẹka sii paapa julọ lawọn fasiti Naijiria nibi ti wọn ti ko awọn ọmọ ẹgbẹ mii wọle.

'Iroyin ẹlẹjẹ nipa ikọlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun'
Wọn ti fẹsun kan awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun pe awọn ni wọn wa nidi ikọlu lawọn fasiti kaakiri Naijiria ti wọn a si tun ma dunkoko mọ awọn olukọ lati fun wọn ni maaki.
Lawọn ibomiran wọn a ma fi ileri anfaani ipo tabi siso awọn ọmọ ẹgbẹ yi mo awọn ti yoo ran wọn lọwọ tan wọn jẹ.
Ọpọ awọn ẹgbẹ yi lo ti ni ẹka laarin awọn ti ko si ni ọgba fasiti ti awọn wọn yi a si ma gbe igbe aye ole jija ati iwa janduku.

Oríṣun àwòrán, Other
Lawọn ilu bi Eko ati Portharcourt awọn ẹgbẹ okunkun yi a ma saba fa awọn ọmọ keekeke wọnu ẹgbẹ janduku ladugbo ti iru awọn wọnyi a si wa pada wa di booran nigba ti wọn ba de fasiti.
Loṣu Kẹrin ọdun yi, awọn ara ipinlẹ Eko ati Ogun ko ara wọn jọ lati ma ṣe fijilante ladugbo kọọkan nitori iroyin to gbode pe awọn ọmọ ẹgbẹ janduku One Million Boys ati Awawa Boys n doju ija kọ awọn eeyan ladugbo wọn. Isede wa lasiko yi nitori Coronavirus.

Awọn eeyan sọ pe eyi lo mu ki awọn janduku wọnyi d'aṣọ okunkun boju lati le fi ja awọn eeyan lole ninu ile wọn.
Ko pẹ ko jina ti iroyin gba oju opo ayelujara nipa bi awọn janduku miran ti ṣe n yabo awon adugbo lati le ṣọṣẹ fawọn eeyan mọ inu ile wọn.
Nṣe lo dabi ẹni pe wọn pe ara wọn jọ lati ṣigun bo awọn araadugbo ni.
Awọn ọlọpaa sọ pe ko si ohun to jọ bẹ to ṣẹlẹ ti wọn si ni awọn kan mọọmọ tan iroyin ẹlẹjẹ yi ka ni lati le fi d'ẹru ba awọn ara ilu ṣaaju ki wọn to ṣigun wa.
Sibẹsibẹ awọn ọlọpaa ni awọn mu awọn afurasi to le ni igba t'awọn fura sì pe wọn kopa ninu ija to waye laarin awọn ẹgbẹ okunkun meji kan lẹyin iku ọkan ninu awọn olori wọn.
Idi ti Roland fi di ọmọ ẹgbẹ Buccaneer
Ipinu Roland lati di ọmọ ẹgbẹ okunkun ko sẹyin pe wọn yoo daaboboo ni fasiti rẹ to wa ni ẹkun ila oorun Naijiria.
Ọrẹ rẹ kan ni ọmọ ẹgbẹ okunkun ja lole ti ọrọ naa si di ranto.
Wọn wọ Roland wọ inu ija yi ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun si doju ija kọọ leemeji ọtọọtọ.

O fi ọrọ yi to awọn alaṣẹ fasiti leti ṣugbọn awọn ẹṣọ alaabo fasiti ko ri nkankan ṣe si.
Agbarac awọn ẹṣọ fasiti yi kere jọj si t'awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n gbe ibọn ati awọn ohun ija oloro mii rin kaakiri.
Ọna ati wa aabo f'ẹmi rẹ lo wa lọ s'ọdọ ẹgbẹ okunkun Buccaneer ṣugbọn ni kete to darapọ mọ wọn, ibẹru bojo awọn ẹgbẹ okunkun to ku lo jọba lọkan rẹ.
Njẹ Wole Soyinka lọwọ si idasilẹ awọn ẹgbẹ okunkun?
Awọn ẹgbẹ okunkun Naijiria ko ri bayi lati ipilẹ.
Lọdun 1952 lasiko ti ijọba amunisin oyinbo n lọ si opin ni awọn ọdọmọdekunrin kan ṣe idasilẹ awọn ẹgbẹ yii.
Ninu wọn la ti ri ilumọọka ọjọgbọn Litireṣọ, Wọle Soyinka t'oun ati awọn miran ni fasiti Ibadan da ẹgbẹ wọn silẹ

Awọn akẹkọọ ta n sọ yi pe ẹgbẹ wọn ni National Association of Seadogs, or Pyrates, ti wọn si gbe kalẹ lati tako awọn to n fi ipo ọla yan awọn ara toku jẹ.
Awọn meje lo da ẹgbẹ yii silẹ nigba naa.
Wọle Soyinka sọ fun BBC pe ere lawọn kan n se pẹlu ẹgbẹ t'awọn da silẹ yi.
O ṣàpèjúwe awọn ẹgbẹ okunkun ode oni gẹgẹ bi "ẹgbẹ kebbe,ẹgbẹ alaburu"
"Mi o fi igba kankan ro pe ẹgbẹ kankan ninu ile iwe fasiti yoo ma ṣamulo awọn iwa buruku bi ijinigbe,ipaniyan,fifi ipa bani lopọ,ajigunjale ati awọn iwa miran bayi"
" Mi o lero pe yoo pada da bo ti se ri yi,ki lo si mu di bayi? Nitori pe awọn obi kan,kaka ki wọn foju odaran wo awọn ọmọ buruku wọn yi,nise ni wọn raga bo won"
Ẹgbẹ Pyrates ti Soyinka si yi jẹ ọkan lara wọn gẹgẹ bi o ti ṣe sọ si n ṣe igbelarugẹ awọn iṣẹ oloore f'ẹda moniyan.
Wọn ko ẹgbẹ yi kuro lawọn fasiti lọdun 1984 ki awọn obilẹjẹ ma ba bawọn l'orukọ jẹ.
Wọn ko gba ọmọ ẹgbẹ tuntun kankan sí ẹgbẹ naa mọ.
Bi awọn ẹgbẹ okunkun ti ṣe yapa bẹrẹ si ni ju iwa janduku
Ipinya laarin awọn ọmọ ẹgbẹ Pyrates ni igba naa lo mu ki awọn kan yapa lati lọ da ẹgbẹ Buccaneer ati awọn ẹgbẹ mi silẹ.
Ija pẹẹpẹpẹ to waye bẹrẹ si ni mu ki wọn ma bara wọn du obinrin,ipo,ọla,iyi ati atilẹyin awọn oloṣelu to bẹrẹ si ni lo awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lati doju ija kọ awọn alatako wọn.
Awọn ẹgbẹ kan buru ju ara wọn lọ ti kii si ṣe gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo ma n wuwa ọdaran.
Toun ti bẹẹ gbogbo awọn ẹgbẹ okunkun lo m an deru ba awọn eeyan bi wọn ba darukọ wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ninu awọn to buru ninu wọn ni ẹgbẹ Alaake dudu, Black Axe.
Ni nkan bi ọdun diẹ sẹyin ni won bẹrẹ sii ni gberi ti wọn si mọ wọn si Neo Black Movement ni ibẹrẹ.
Awọn to da silẹ ni erongba awọn ni lati tu ẹya alawọdudu silẹ lọwọ igbekun.
Ṣugbọn lode oni, awọn ọmọ ẹgbẹ yi lawọn fasiti ti yi ipinu pada.
Kaka ki wọn ranti ipilẹṣẹ pupo a ma seku pani ti wọn a si ma bani lopo lọna aitọ.
Awọn kan fẹsun kan ologun pe wọn n ran ẹgbẹ okunkun lọwọ
Ni ọdun 1999 wọn pa awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo nilu ile Ife nipinlẹ Osun.
Bẹẹ naa lawọn kan naa seku pa awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Black Axe.
Ni nkan bi ọdun 1990 awọn kan bẹ ori olori ẹgbẹ okunkun ti won si gbe kọ si ori opo lati fi ṣe afihan pe awọn pegede.
Laarin ọdun 1980 siwaju, ija laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun peleke.
Ọrọ naa buru pupọ laarin igba t'awọn ologun fi n gba ijọba lorileede Naijiria.
Leralera lawọn eeyan n fẹsun kan awọn ologun pe wọn ṣe iranwọ owo ati nkan ija fawọn ẹgbẹ okunkun lati le doju ija kọ awọn to n pe fun Ijọba alagbada.

Akọroyin Omoyele Sowore mọ awọn ẹgbẹ okunkun yi bi ẹni m'owo nigba to n kẹkọọ ni fasiti ilu Eko, Unilag.
Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun n dunkoko mọ awọn akẹkọọ nigba to jẹ aare ẹgbẹ awọn akẹkọọ fasiti naa.
O ṣe ìpinnu lati koju wọn ṣugbọn igbesẹ yi léwu fún un.
O so fun BBC pe "Ẹmi mii fẹ ba lọ"
Loṣu Kẹta 1994, wọn gbe ibọn si lori ti wọn si gun labẹrẹ ti ko mọ ohun to wa ninu rẹ.
"Ọpọ wọn ya bo mi, wọn gun mi lọbẹ lori ati ni ibi ikun mi. Wọn bọ mí sí ihoho"
Awọn akẹkọọ akẹgbẹ rẹ lo pada gbaa silẹ lọwọ wọn ti wọn si gbe e lọ si ile iwosan.
Egbẹ okunkun, oogun oloro ati owo eeyan ṣiṣe
Iwa to wa lọwọ awọn ẹgbẹ okunkun mi kọja orileede bode orileede Naijiria.
Wọn fẹsun kan ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ pe wọn pẹka de ilẹ okeere.
Awọn ọmọ ẹgbẹ naa wa lara awọn metalelogun t'awọn agbofinro ilẹ Spain mu l'agbegbe Catalonia lọdun 2015 pe wọn n se owo fifi eeyan s'owo ẹru ti wọn a sì tún ma ta oogun oloro to fi mọ ṣíṣe ayederu iwe irina fawọn eeyan.
Ikọ awọn odaran yi ni wọn tun fi ẹsun kan pe wọn n ji epo robi ta lọna aitọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O s'ọwọn ki eeyan to wa ninu ẹgbẹ okunkun ribi já ara rẹ gba kuro ninu ẹgbẹ naa lasiko to wa ni ile ẹkọ.
Awọn to dan wo ninu ki wọn farapa tabi ki wọn padanu ẹmi wọn.
Pupọ akẹkọọ lo pa ẹkọ rẹ ti nigba ti wahala awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ba fẹ yọ ile aye l'ẹmi wọn.
Awọn mi,titi laye ni wọn yoo fi ṣẹgbẹ naa.
Koda a ma fun wọn láánfàní iṣẹ tó da ati ibaṣepọ pẹlu awọn to lẹnu lọrọ láwùjọ.
Awọn mi a ma kowo sidi ẹgbẹ okunkun.Won a ma ṣe baba isalẹ fawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun.
Awọn wọn yi a si ma wa awọn ọmọ obinrin fun won nigba to ba wu wọn lati ṣe Ibalopọ pẹlu wọn.
Roland ni igbagbọ pe ofo lasan ni ileri ati adehun t'awọn ẹgbẹ okunkun maa n se fawọn ọmọ ẹgbẹ wọn.
"Lọpọ igba eeyan yoo wa ninu ibẹrubojo ni.Ko si bi awọn ọmọ ẹgbẹ ṣe le parọ fún e to, gbogbo igba leru ma n ba wọn"
* A lo orukọ Roland la ti fi bo ẹni ta ba sọrọ lasiri ki ẹmi rẹ ma ba wa ninu ewu
* Manuella Bonomi ileeṣẹ BBC lo ya gbogbo aworan ta fi ṣe akawe ọrọ
Ile ẹjọ ti ni kí ọkùnrin, ẹni ọgbọn ọdun, Nwali Kingsley, ma a gbatẹ́gùn ni ọgbà ẹ̀wọ̀n, fun pe o lu ọkunrin kan, Victor Nwafor pa, lasiko to n seto igbaniwọle sinu ẹgbẹ okunkun fun.
Afurasi naa, ni iroyin sọ pe oun ati awọn miran, to ti ṣa lọ bayii, tun ṣe ẹlomiran, Chigbo Ugbala leṣe, nipa fifi igi lu u, ti wọn si tun fi àdá ṣa, nibi eto igbani wọle naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Agolo gáásì kéeké tó ń jò bú gbàmù l‘Eko, ẹ̀mí kan bọ́, mẹ́ta fara pa
- Ìjọba àpapọ̀ ti gba 800 bílíọ̀nù padà lọ́wọ́ àwọn tó jí owó ìlú kó, àwọn 1,400 ti wà nínú ẹ̀wọ̀n -Lai Mohammed
- Toke Makinwa ti sọ̀rọ̀; Amcon náà dá a padà fún un pé...
- Ọwọ́ tẹ́ àwọn ọkùnrin Fulani mẹ́ta tí wọ́n jí Màálù méjì kó ní Ogbomọṣọ- Àjọ NSCDC
- Ọmọ́ Yorùbá korò ojú sí Buhari bí kò ṣe fi orúkọ Obasanjo sọ ibùdókọ̀ ojú'rin
- Ọ̀nà tó fi le è mọ gbájúẹ̀ babaláwo - Ẹlẹ́buìbọn
- Òfin lè má mọ oògùn ṣùgbọ́n èmí gbàgbọ́ pé ǹkan wà nídìí bí wọ́n ṣe pa ọmọ mi- Baba Favour
Iṣẹlẹ naa la gbọ pe o waye nileewe girama Ekeugwu Azuinyaba, nijọba ibilẹ Ishielu, nipinlẹ Ebonyi, lọjọ kẹwàá, oṣu Keje.
Iroyin ni nibi ti won ti n ju oku Nwafor sinu odo, ni Ugbala si raaye sá lọ, gbogbo igbiyanju lati ri oku oloogbe naa, lo ja si òfo.

Ẹsun ipaniyan, igbimọ pọ, ṣíṣe ẹgbẹ okunkun, ati níní nkan ija lai gba iwe àṣẹ, ni wọn fi kan Kingsley.
Afurasi naa, ti ko ní agbẹjọro to ṣoju rẹ nile ẹjọ sọ pe, awọn ọrẹ oun lo fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ fa oun sinu iwa buruku naa, to si tun bẹbẹ pe ki ile ẹjọ siju aanu wo oun.
Ọlọpaa to rojọ tako o nile ẹjọ, ASP Eze Nnabuaku, sọ fun ile ẹjọ pe, "ijiya wa fún awọn ẹsun ti wọn fi kan Kingsley, ninu ofin ọ̀daràn, ti ipinlẹ Ebonyi.
Sugbọn, adajọ ile ẹjọ Majisireti naa, Arabinrin Nnenna Onuoha, ti pàṣẹ pe, ki wọn o taari iwe ẹjọ naa si ọfiisi ikọ agbẹjọro ijọba fun igbesẹ to yẹ,
O ni ile ẹjọ majisireti naa ko ni agbara lati gbọ ẹjọ naa, to si sún igbẹjọ si ọjọ keje, oṣu Kẹjọ ọdun 2020.























