"Mo ti bí ìbejì nígbà márùn ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àmọ́ mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni"

"Mo ti bí ìbejì nígbà márùn ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àmọ́ mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni"

Àkọlé fídíò, "Mo ti bí ìbejì nígbà márùn ún ọ̀tọ̀tọ̀, àmọ́ mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni"

Ọkunrin kan to bi ibeji nigba marun un ọtọtọ ti ṣalaye fun BBC bi inu rẹ ṣe dun to lẹyin to bi awọn ọmọ naa, ati pe oun ṣi nifẹ si lati bi awọn mii si.

Baba ibarun naa, Ayopo Ogunleye, ni ibeji ni iyawo oun maa n bi ni gbogbo igba to ba fẹ bi ọmọ.

O ni eredi ti oun ko ṣe dawọ ọmọ bibi duro ko ṣẹyin igbagbọ pe o ṣeeṣe ki awọn ọmọ naa ya ajẹ ti oun ati iyawo oun ba dawọ ọmọ bibi duro.

O ni “Nigba ti a ti bii pe bii ẹẹmẹta, wọn ni ki a da duro, ṣugbọn nilẹ Yoruba, wọn ni ki a ma da duro nitori a ṣi kere.”

“Wọn ni ti a ba da duro bẹẹ ti a ko sudo wọn, wọn ni ajẹ ni wọn maa da... la ba ni ka ṣi maa ṣere lọ.”

Baba ibeji naa ni ọmọ kan ṣoṣo ni awọn n wa si ọmọ awọn titi ti wọn fi bi ibeji lẹẹmarun un lera-lera.

O ni “Idowu ati Alaba ni n wa pe ki a danu duro, ni a fi bi ibeji lẹẹmarun un.”

Baba Ibeji

Mo ṣi maa bi ọmọ si

Bo tilẹ jẹ pe Ogunleye ti bi ibeji nigba marun un, o ni o ṣi wu oun lati bi awọn ọmọ mii si.

O ni “Mo ṣi n bimọ lọ o, ti mo ba bi ibẹta tabi ibẹrin si awọn ọmọ mi, idunnu mi naa ni pe Ọlọrun ṣeun.”

Baba ibeji ọhun ni ọpọ igba lawọn ọkunrin maa n bere lọwọ oun aṣiri bi oun ṣe n bi awọn ibeji.

O pari ọrọ rẹ pe kii ṣe ipa tabi agbara oun loun ṣe n bi ibaji, amọ iṣẹ Ọlọrun ni.

O fi kun pe kii ṣe pe oun lowo lọwọ pẹlu iye ọmọ ti oun bi.

O ni “Ọlọrun lo n gbọ bukata mi... mo ṣi wa lori ọmọ bibi titi di igba ti mi o ba lokun lati ṣere mọ.”