Ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró nìyíí lórí Ekweremadu àti ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n ń jẹ́jọ́ èsùn rírà ẹ̀ya ara fún ìlera ọmọ wọn

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Senetọ Ekweremadu ati iyawo rẹ to n koju ẹsun ifiniṣowo ẹru ni o ṣeeṣe ki igbẹjọ rẹ tẹsiwaju titi di Oṣu Karun un, ọdun to n bọ ni UK.

Ẹsun ti wọn fi kan an nipe o fẹ yọ ẹya ara ọmọkunrin kan ti wọn mu lati orilẹede Naijiria lọ si Ilẹ Gẹẹsi fun tita ati rira.

Ekwemadu ati iyawo rẹ ni won fesun kan pe won fey o kindirin okunrin naa ki won si fun omo won to n se aisan lowo.

Arakunrin naa lo ḳo jalẹ lati ṣayẹwo kidirin ṛe ni ileewosan Royal Free Hospital ni Hampstead, North-west London.

Okunrin naa ni wọn kọkọ lo oun bii ẹru fun ọpọlọpọ ọjọ ki o to sa asala fun ẹmi rẹ, to si gba agọ ọlọpaa lọ.

Awọn lọkọ-laya naa ni wọn gbamu ni papakọ ofurufu Heathrow, lẹyin ti wọn de pẹlu ọkọ baalu kan lati Turkey.

Ekweremadu ṣi wa ni ẹwọn, adajọ ni igbẹjọ le di ọdun to n bọ ko to pari

Ẹsun ti wọn fi kan an Ekweremadu nipe o gbimọ pẹlu arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Obinna lati fiyajẹniyan.

Eleyii ni wọn ni o waye ni Oṣu Kẹjọ ọdun to kọja si Oṣu Karun un ,ọdun yii.

Ni asiko igbẹjọ ni Ọjọbọ, Abilekọ Ekweremadu ti wọn gba beeli rẹ ni o wa si ibi igbẹjọ rẹ, ti sẹnetọ Ekweremadu ati Obeta naa si darapọ mọ igbẹjọ naa nipa lilo fidio lati ọgba ẹwọn Wandsworth ti wọn wa.

Awọn afẹsunkan naa ni wọn ko fun ni aaye lati sọrọ amọ ki wọn kan darukọ ara wọn nikan, ti adajọ si ni ileẹjọ giga ni yoo gbọ ẹjọ naa.

Ọjọ Keji, Osu Karun, ọdun to n bọ ni wọn sun igbẹjọ naa si amọ ijiroro lori igbẹjọ naa yoo waye ni Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Oṣu Kẹwaa, ọdun yii.

Bakan naa ni adajọ ni ki Abilekọ Ekweremadu maa lo beeli rẹ lọ, amọ ki ọkọ rẹ ati ekeji rẹ si wa ni ọgba ẹwọn sibẹ.

Ìgbẹ́jọ́ Ike Ekweremadu ní London tó ti wáyé sẹ́yìn

Ike Ekweremadu àti ìyàwó rẹ̀

Ọjọ́ Keje, oṣù Keje, ọdún 2022 ni ìgbẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Ike Ekweremadu àti ìyàwó rẹ̀, Beatrice Nwanneka Ekweramadu waye kẹyin ṣaaju ti ana ọjọ Kẹrin Oṣu Kẹjọ ní London.

Ẹ̀sùn pé wọ́n fẹ́ yọ ẹ̀yà ara ènìyàn ni wọ́n fi kan Ike Ekweremadu àti ìyàwó rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè United Kingdom.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá orílẹ̀ èdè náà ní ẹ̀sùn ní ìjìyà lábẹ́ òfin Modern Slavery Act 2025.

Láti ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kẹfà ni Ekweremadu ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá Met Police lẹ́yìn tí weọ́n yọjú sí ilé ẹjọ́.

Ní ọjọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ yọjú sí ilé ẹjọ́ ni adájọ́ ní àwọn nílò láti jíròrò pẹ̀lú agbẹjọ́rò àgbà orílẹ̀ èdè náà kí wọ́n fi le mọ ìgbésẹ̀ tí wọn yóò gbé lórí ẹjọ́ náà nítorí ẹ̀sùn tí wọ́n ká sì wọn lẹ́sẹ̀ jẹ́ èyí tí díẹ̀ lára rẹ̀ wáyé ní orílẹ̀ tí kìí ṣe UK.

Ohun tó bá wáyé lónìí ni yóò sọ bí ìgbẹ́jọ́ yóò ṣe máa tẹ̀síwájú bóyá wọ́n máa gbé Ekweremadu àti ìyàwó rẹ̀ wá sí Nàìjíríà láti máa wá jẹ́jọ́ ní orílẹ̀ èdè baba wọn.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Met Police nínú àtẹ̀jáde kan ní àwọn nawọ́ gán Ike Ekweremadu àti Beatrice Ekweremadu lẹ́yìn tí àwọn ti ń furasí wọn.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ló ta àwọn lólobó nínú oṣù Karùn-ún wí pé Ike Ekweremadu fẹ́ yọ ẹ̀yà ara ọmọ náà láti lè fi pàrọ̀ kíndìnrín ọmọ ti wọn tó ń ṣe àìsàn.