Fihàn agbébọn pé ìwọ ní ádárì wá - Afenifere sọ̀kò ọ̀rọ̀ sì Buhari

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ Afenifere ilẹ Yoruba ti rọ Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko ṣe afihan pe oun lo si wa nidi iṣeto aabo fun Naijiria nipa gbigba awọn eeyan silẹ lọwọ ijinigbe ati iṣekupa.
Afenifere pa arọwa yii lati bi bu ẹnu atẹlu bi Aarẹ ṣe fi ọwọ yepẹrẹ mu igbesunami ati iṣekupani to wọpọ lori ni orilẹede yii.
Ninu atẹsita kan ti Akọwe ẹgbẹ naa, Jare Ajayi fi sita fun awọn akọroyin, Afenifere ni ko si ibi kankan lorilẹede Naijiria ti abo to peye wa.
Ajayi ni ọpọ igba ni iṣekupani ati ijinigbe ti n waye ni guusu ìwọ oorun orilẹede yii, papa eyi to waye laipẹ niluu ogbomoso .
O ni awọn mẹta kan ti bọ si ọwọ awọn ajinigbe, ti wọn si tun gba ẹmi wọn lẹyin akitiyan awọn mọlẹbi wọn.
O ni ọwọ yẹpẹrẹ ni awọn ijọba fi mu eto abo lorilẹede yii eyiu ni awọn ọdaran fi anfani lati ma gbero lati ṣe ikọlu si ibi kibi to o ba ti wu wọn lọkan.
“Ko tọna bi irufẹ iwa yii ṣe waye labẹ isakoso Aarẹ Muhammadu Buhari.”
“Ọpọ igba ni awọn ọdaran ti ṣe ikọlu, ti wọn si tun ma ṣeku awọn ti jigbe. Aipẹ ni wọn ṣe ikọlu si agbegbe Bali ni ipinlẹ Taraba, wọn pa eeyan mẹta, wọn tun ji ọpọlọpọ gbe lọ.”
“Awọn ọdaran yi ti wa bẹrẹ lati wọ ninu ile lọ ba awọn eeyan lati ṣe wọn ni ijamba lẹyin ti wọn ba ti bori awọn ẹsọ alaabọ ni opopona.”
“Lọjọ eti yii ni awọn agbebọn ṣe ikọlu si Agwa ni ipinlẹ Imo, wọn si pa ọlọpaa mẹrin “

Oríṣun àwòrán, others
Ajayi tẹ siwaju pe ọpọ igba ni ijọba ati awọn ẹsọ alaabo ni awọn n ṣe nkan lati fi opin iwa yii sugbọn o n peleke si ni.
Afenifere ni ko tona bi ijọba ṣe n dari jin awọn ọdaran, ti ofin si kede wọn gẹgẹ bi ọdaran, ti wọn si tun ti ṣeku pa ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹede.
O ni Aarẹ gbọdọ mura si isẹ ati lati fihan pe oun ni o si wa ni isakoso ijọba orilẹede Naijiria.
“Aarẹ ni lati bọ si ita pe ki awọn ọdaran fi oju ganni ida ofin nitori o to gẹ.
Bakana ni Aarẹ ni lati ranti pe oun ‘se adehun fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria pe oun yoo mu idẹrun ba igbe aye wọn, ẹmi ati dukia wọn pẹlu,”
“Ṣugbọn o ṣe ni laanu pe Aarẹ kọ lati mu awọn adehun yii wa si imusẹ, ti o si mu idakeji ba awọn ọmọ orilẹede yi.”.
'Tó bá jẹ́ wí pé ríra ọkọ̀ fún Niger Republic ma tán ìṣòro ààbò, kò sí ohun tó burú níbẹ̀'

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awọn ọmọ Naijiria ti ni o yẹ ki ijọba apapọ fi to ara ilu leti ki wọn to gbe igbesẹ rira ọkọ bọgini fun orilẹede alamuleti Naijiria iyẹn Niger Republic.
Láti ìgbà tí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ti kéde pé àwọn ra ọkọ̀ fún orílẹ̀ èdè Niger ni orí ayélujára ti ń gbóná janjan.
Lẹ́yìn ìpàdé ìgbìmọ̀ aláṣẹ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà èyí tí Ààrẹ Buhari darí rẹ̀ ní Mínísítà fétò ìsúná, Zainab Ahmed fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ìjọba fi owó tí iye rẹ̀ tó #1.4b ra ọkọ̀ fún Niger Republic.
Ahmed ní ìjọba gbé ìgbésẹ̀ yìí láti ṣe ìrànwọ́ fún Niger lẹ́yìn tí Ààrẹ Niger bèrè ìrànwọ́ lọ́wọ́ ìjọba Nàìjíríà pàápàá lórí ọ̀rọ̀ ààbò.
Ó ní kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí ìjọba ma ṣe ìrànwọ́ fún àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n jọ pa ààlà bí Niger, Chad àti Cameroon pọ niyi pàápàá láti wá ojútùú sọ̀rọ̀ ààbò tó ń bá Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀èdè náà fínra.
Ọ̀rọ̀ yìí ti wá ń fa awuyewuye lọ́kan-ò-jọ̀kan láàrín àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà pé ṣé ìgbésẹ̀ yìí ló kàn fún ìjọba Nàìjíríà lásìkò yìí.
Èyí ló mú kí BBC News Yorùbá kàn sí àwọn onímọ̀ láti gbọ́ èrò wọn lórí ọ̀rọ̀ náà.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Dikrulahi Yagboyaju, tó jẹ́ olùkọ́ àgbà ní ẹ̀ka ìmọ̀ òṣèlú ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ibadan, ní láti ìgbàdégbà ní àwọn orílẹ̀èdè ti ma ń dọ́rẹ̀ẹ́ pọ̀ fún onírúurú ìdí.
Ó yẹ kí ìjọba fi tó ará ìlú létí pé àwọn ra ọkọ̀ fún Niger

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Yagboyaju ní àwọn àṣepọ̀ yìí máa ń dá lé oríṣiríṣi nǹkan bíi ètò ààbò, oúnjẹ, ọrọ̀ ajé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó ní tó bá jẹ́ wí pé láti jẹ́ kí ètò ààbò fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀ si ni ìgbésẹ̀ náà ohun tó da ni nítorí àwọn agbéṣùmọ̀mì àti àwọn ọ̀daràn máa ń gba àwọn orílẹ̀ èdè tó sún mọ́ Nàìjíríà wọ orílẹ̀ èdè yìí.
Ó fi kun pé tó bá jẹ́ pé èròńgbà Ààrẹ Buhari àti ìjọba Nàìjíríà láti so okùn ààbò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà daindain ni ríra àwọn ọkọ̀ fún Niger, ìjọba nílò láti fi tó ará ìlú létí ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀.
Yagboyaju ní kìí ṣe èèwọ̀ fún ìjọba láti ran àwọn orílẹ̀ èdè tó múlé tìí lọ́wọ́ nítorí gbogbo ohun tó bá ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ṣeéṣe kó ní ipa lórí orílẹ̀ èdè ti wa náà.
Lara awọn eekan ilu mii to tun fi ọrọ sita nipa ọrọ yii ni Oniroyin kan to tun maa n sọrọ lori ayelujara, David Hundeyin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ìgbésẹ̀ kan kò lè tán ìpèníjà ètò ààbò
Yagboyaju ní ohun tó dájú ni pé lóòótọ́ ni ríra ọkọ̀ fún orílẹ̀ èdè Niger le tán ìṣòro kan nínú ìpèníjà tó ń bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fínra, síbẹ̀ ríra àwọn ọkọ̀ yìí kò le tán gbogbo ìṣòro ààbò Nàìjíríà.
Ó ní kìí ṣe wí pé Niger nìkan ni ètò ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra ti ń wá.
Láìsí ètò ààbò kò sí ohunkóhun tó le ṣiṣẹ́
Yagboyaju tẹmpẹlẹmọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ni wí pé ó yẹ kí ìjọba ná owó ọ̀hún sí àwọn nǹkan tí Nàìjíríà nílò síbẹ̀ ètò ààbò kò ṣé fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú.
Ó ní gbogbo nǹkan tó bá máa mú ètò ààbò gbópọn si ló yẹ kí ìjọba ma ṣe báyìí nítorí àwùjọ tí inú fu, àyà fu bá ti wà kò le ní ìdàgbàsókè.
Ó fi kun pé ètò ẹ̀kọ́ àti àwọn ẹ̀ka mìíràn kò le ṣiṣẹ́ tí ètò ààbò bá ti mẹ́hẹ.
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ náà, Sarafa Alli tí òun náà bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ náà ní tó bá jẹ́ wí pé nítorí ètò ààbò ni ìjọba ṣe ra ọkọ̀ fún orílẹ̀ èdè náà kò sí ohun tó burú níbẹ̀ nítorí ìpèníjà tí Nàìjíríà ń kojú jùlọ kò kọjá ètò ààbò.
Alli ṣàlàyé wí pé àwọn nǹkan tó ń ba àwọn ènìyàn lẹ́rù ní orílẹ̀ èdè lyìí lásìkò tí a wà yìí kò kọjá ètò ààbò tó mẹ́hẹ.
Ó fi kun pé tó bá wí pé nítorí ká le sùn forí lé òṣùpá ni ìgbésẹ̀ náà fi wáyé kò sí láìfí kankan níbẹ̀.
“Ìjọba ló ni ètò, tí sì mọ èrò tó bá jẹ́ wí pé nítorí ààbò ni ìjọba ṣe fúnNiger Republic lówó kò sí aburú níbẹ̀.”












