Folarin ní òun kẹ́ pàkúté méjì sílẹ̀ fún Makinde, ọ̀gá ọlọ́pàá, ẹ gbà wá - PDP Oyo

Ẹ ni Folarin kẹ́ pàkúté fún Makinde, kì ni ká sọ̀ lórí ìhàlẹ̀ Auxiliary sí Folarin? - APC ń bèèrè

aworan makinde ati folarin

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo ti rọ ọga ọlọpaa Naijiria, Alkali Baba Usman, lati gbé ìgbésẹ̀ lori awọn isẹlẹ to n waye nipinlẹ Oyo.

PDP ni ki Alkali kilọ fun oludije sipo gomina labe asia ẹgbẹ APC, Sẹnatọ Teslim Folarin, ko mase bẹrẹ ija nipinlẹ Oyo.

Ikilọ naa lo waye lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu PDP fẹsun kan APC pe wọn gbero lati gba ẹmi oludije gomina PDP, Seyi Makinde, lẹyin fọnran kan to jade.

Fọnran aworan naa lo n ṣafihan alaga igbimọ oludari awọn ibudokọ nipinlẹ Oyo, Alhaji Lamidi Mukaila, ti ọpọ mọ si Auxilliary, nibi to ti n dunkooko lati fiya jẹ Folarin.

PDP, ninu atẹsita kan ti akọwe ẹgbẹ, Akeem Olatunji fọwọsi lọjọ isẹgun, sọ pe gbogbo erongba ọkan Teslim Folarin ni lati lo ofisi rẹ, da rogbodiyan silẹ ni ipinlẹ Oyo.

Ẹgbẹ oselu naa ni eyi n waye lati ipasẹ bi oun ati ẹgbẹ oṣelu APC ṣe fi ẹsun ti ko tọ kan ẹgbẹ oṣelu PDP.

“Ilera Folarin ni kudiẹkudiẹ ba nitori bi gbogbo nkan to ṣe ti ko da, ṣe n da lọkan ru.”

“Folarin yii lo n dun kukulaja mọ gomina Seyi Makinde pe oun ti dẹ pakute meji silẹ fun, ti ko si le bọ ninu awọn pakute naa.”

"Ti Folarin ati awọn alatilẹyin rẹ ti setan lati da ilu ru, amọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo ni ko gba fun,”

Awa naa ti kọ lẹta si ọga ọlọpaa lati gba wa kalẹ lọwọ yin - APC Oyo fesi pada fun PDP

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹgbẹ oṣelu APC naa ti wa fi esi si lẹta kan ti ẹgbẹ oṣelu PDP kọ si ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, Alkali Baba Usman (IGP) lori awọn isẹlẹ to n waye nipinlẹ Oyo.

Akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP, Alhaji Tajudeen Olanite, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori isẹlẹ naa ni gbogbo erongba PDP ni lati gbe ipinlẹ Oyo lọ soko ẹru.

Fun idi eyi, Olanite ni awọn ko ni faaye gba modaru kankan ni ipinlẹ Oyo.

Olanite ni ẹgbẹ oṣelu APC naa ti kọ lẹta si ọga agba ọlọpaa ni Naijiria lori fọnran to bọ si ori ayelujara.

Ninu fọnran ọhun lo ni oludari ẹgbẹ awọn alakoso ibudokọ nipinlẹ Oyo, Alhaji Lamidi Mukaila, ti ọpọ mọ si Auxilliary, ti n dunkooko lati fiya jẹ Folarin.

Olanite wa n beere pe "Ẹni Folarin kẹ́ pàkúté, kì ni ká sọ̀ lórí ìhàlẹ̀ Auxiliary sí Folarin?"

“Bawo ni wọn ṣe dẹ pakute iku fun Makinde, eyi ti ọmọsẹ Makinde sọ nkọ, ṣe o ti kuro nibẹ ni?"

"Gbogbo eeyan lo gbọ nkan ti Auxillary sọ pe Folarin yoo fi iku ṣe fajẹ, ekute rẹ yoo faragba ẹgba.

“Ṣe asiko yii wọn sẹsẹ mọ pe Folarin dẹ pakute iku fun wọn.”

‘APC naa kọ lẹti si ọga ọlọpaa pe ko fa Auxillary leti’

Adenite fikun pe ẹgbẹ oṣelu PDP naa ti kọ lẹta ransẹ si ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, pe ki wọn kilọ fun Auxillary,

“Awọn ti ni ki Ọlọpaa kilọ fun Auxillary ati ẹni to ran nisẹ, tori a mọ pe osisẹ Makinde ni Auxillary.

O tẹ siwaju pe gbogbo idunkoko PDP ni ko ba awọn bayii, ati pe awọn ko fẹ jagidijagan ni ipinlẹ Oyo.

“A fẹ ki wọn mọ pe APC ko fẹ jagidijagan, a ti n sun lati ọjọ yin ki wọn to de, ki lo tun wa de ti wọn ko fẹ ki oṣelu wu awọn eeyan ṣe mọ.”

Akọwe APC wa rọ awọn awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati ma ṣe bẹru nitori pe ẹgbẹ oṣelu APC ni yoo gba wọn ninu oko ẹru.

Folarin, fi ẹ̀ṣọ̀ ṣe lọ́dọ̀ mi kó má ba à di gbéré fún ọ - Auxilliary

Ọlọ́pàá Oyo, ẹ ràgà bo olùdíje gómìnà wa, Teslim Folarin lọ́wọ́ Auxillary - APC

Teslim ati Auxilliary

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Oyo, APC, ti ke gbajare fun ileeṣẹ ọlọpaa ati ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, lati raga bo oludije wọn fun ipo gomina ipinlẹ Oyo lọdun 2023, Teslim Folarin.

Igbesẹ APC yii waye lẹyin ti fidio kan, eyi to ṣafihan alaga igbimọ oludari awọn ibudokọ nipinlẹ Oyo, Alhaji Lamidi Mukaila, ti ọpọ mọ si Auxilliary, nibi to ti n dunkooko lati fiya jẹ Folarin.

Ninu fidio naa to to iṣẹju kan, ni Auxilliary ti sọ pe awọn agbebọn ti Teslim Folarin n ko jọ, ko le ṣe nkankan fun oun.

O ni “o di gbere, ti Folarin ko ba fi ẹ̀ṣọ̀ ṣe lọdọ mi, nitori pe mo yatọ si awọn yooku to ti kọju ija si ri."

“Ti oro rẹ ko ba fi ẹsọ fi lọdọ emi Auxilliary, o di gbere fun niyẹn.”

Amọ ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo, Tajudeen Olanite, fi sita , APC rọ awọn eleto aabo lati ṣe iwadii nipa Auxilliary.

APC sọ pe ẹru n ba oun pupọ lori ewu ti idunkooko Auxilliary le fi Sẹnetọ Folarin si “nitori awọn iwa ati iṣe awọn mọ Auxilliary”.

APC ni ihalẹ rẹ ko ṣe e fi ọwọ yẹpẹrẹ mu.

“A rọ ileeṣẹ ọlọpaa ati DSS, lati pese aabo to l’agbara fun oludije APC fun ipo gomina.

Idi ni pe gbogbo awọn idunkooko ti Alhaji Mukaila Lamidi ṣe si awọn eeyan kan nigba kan ri, lo mu ṣẹ.

O si se eyi nipa biba dukia jẹ́, idẹru bani, ati pipa awọn to ba ti dojukọ.”

Bakan naa ni APC fẹsun kan pe Ọgbẹni Auxilliary n ri oludije awọn gẹgẹ bi okuta idena, ti ko fẹ ẹ jẹ ki ọga rẹ, Gomina Seyi Makinde, bori idibo fun saa keji lọdun 2023.

“Nitori naa si lo ṣe da bi pe o pinnu lati yanju awọn oloṣelu nlanla ninu ẹgbẹ wa, lati le mu ko ṣeeṣe fun ọga rẹ lati de ipo.”

Wọn fi kun pe awọn n fẹ ki awọn ileeṣẹ eto aabo ṣe iwadii idunkooko iku mọ ni ti Auxilliary fi sita, nitori awọn ko ni i fẹ ki ikọlu kankan waye si oludije awọn, paapaa bi ipolongo ibo yoo ṣe bẹrẹ laipẹ.

Akọwe ẹgbẹ APC, fi ẹsun kan Auxilliary pe oun lo wa nidi awọn ikọlu kan ati ija igbo, to mu ẹmi lọ ni awọn asiko kan sẹyin nipinlẹ Oyo.

Ṣugbọn a ko le fidi eyi mulẹ. Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa tabi ajọ eleto aabo mii ko fi igba kankan kede eyi.

Taa ni Alhaji Mukaila Auxilliary ti APC n bẹru ijamba to le ṣe?

Auxilliary ati ẹnikan lara awọn ti ileeṣẹ alaabo mu fun ẹsun ipaniyan ati idaluru

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán, Auxilliary ati ẹnikan lara awọn ti ileeṣẹ alaabo mu fun ẹsun ipaniyan ati idaluru

Alhaji Mukaila Lamidi ‘Auxilliary’ ni alaga ajọ to n mojuto awọn ibudokọ nipinlẹ Oyo.

Idasilẹ PMS, ati iyansipo Auxilliary waye nigba ti Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, tu igbimọ ẹgbẹ awakọ, NURTW, ka nipinlẹ Oyo “nitori jagidijagan’, lọdun 2019.

Ṣugbọn ṣaaju asiko naa, Auxilliary jẹ ọkan lara aṣaaju ẹgbẹ NURTW nipinlẹ naa.

Ọpọ igba si ni iroyin ti sọ pe oun lo ma n wa nidi ọpọ ija igboro ati jagidijagan to ma n waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ nipinlẹ Oyo.

Bakan naa ni ijọba ju u si ẹwọn lasiko iṣejọba gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Abiola Ajimobi.

Ọdun 2016 ni wọn ju oun ati eeyan mẹrin miran si ẹwọn ọdun mẹfa, fun ẹsun pe wọn lọwọ ninu rogbodiyan to mu ẹmi awọn eeyan kan lọ nilu Ibadan loṣu Kẹta, ọdun 2014.

Ọdun 2018 si lo jade ni ẹwọn.