Ń kó gbá àádọ́ta bílíọ́nù lóṣooṣù lọ́wọ́ Ambode – Tinubu

aworan Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, officialasiwajuba

Oludije sipo aarẹ fẹgbẹ APC, Bola Tinubu ti ni irọ ni iroyin kan to n ja kiri pe oun gba aadọta biliọnu losoosu lọwọ gomina tẹlẹri nipinlẹ Eko, Akimwummi Ambode nigba to wa lori alefa.

Atẹsita ti adari ẹgbẹ to n ri si ipologo fun Tinubu, Bayo Onanuga fisita fawọn akọroyin ni Tinubu ko ni irufẹ erongba bẹẹ.

O wa rọ awọn awọn alatako rẹ lati jawọ ninu pinpin iroyin ti ko lẹsẹ nilẹ mọ.

Onanuga ni oludije fun aarẹ APC naa ni ko le beere irufẹ owo ọhun nigba to mọ pe ipinlẹ Eko ko lanfani lati pa owo naa losoosu lasiko saa Ambode.

“Tinubu ko le beere irufẹ owo naa nigba ti o mọ pe ipinlẹ Eko ko pa owo toto bẹẹ laarin osu kan.

Atẹsita ọhun wa bu ẹnu atẹ lu bawọn alatako ṣe gbe iroyin ti ko lẹsẹ nilẹ kiri lati ṣe akoba fun erongba Tinubu lati di aarẹ Naijiria.

“Iroyin ti wọn gbe sita o jẹ iroyin ti ko ni ẹsẹ nilẹ.

Agbẹ́jọ́rò wọ INEC lọ ilé ẹjọ́ lórí ìwé ẹ̀rí ìdíje dupò Tinubu

Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat/Instagram

Agbẹjọro kan o fi ilu Abuja ṣe ibujoko ti wọ àjọ eleto idibo Naijiria, INEC lọ sí ilé ẹjọ lori aipese ojulowo iwe to nise pẹlu ifakalẹ oludije ipo ààrẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.

Ọgbẹni Mike Enahoro-Ebah, tun beere iyọnda lọdọ ile ẹjọ pe ki wọn pàṣẹ ki wọn ṣe agbekalẹ awọn iwe iforukọsilẹ ti Tinubu fi dije dupo Gomina nipinlẹ Eko lọdun 1999 ati 2003. Tinubu ni oludije to n dije ipo ààrẹ labẹ asia APC.

Ninu iwe ipẹjọ tí wọn pe ni FHC/ABJ/CS/1337/2022, Enahoro-Ebah ni oun n béèrè fún "gbogbo ìwé iforukọsilẹ to fi dije dupo Gomina ati awon iwe mii to jẹri sí idije dipo rẹ lọdun 1999 ati 2003"

Agbẹjọro yi sọ pe iwe meji ọtọọtọ loun fi beere iwe wọnyi labẹ ofin to faaye gba araalu lati beere eyikeyi iroyin to nise pẹlu ọrọ ilu.

Ki lo de ti fi n beere awọn iwe wọnyi?

Olùpẹ̀jọ yi gẹgẹ bí alaye to se ni idi toun fi fẹ ri awon iwe yi ni pé àjọ eleto idibo INEC lo ní wọn lọdọ. Nigba ti wọn sì jẹ iwe to nise pẹlu aráàlú, oun lẹtọ lati beere fawọn iwe yi ni ibamu ofin eto idibo.

O ni ofin idibo naa ti faraalu lanfaani ki wọn beere iroyin nipa ọrọ to ba ruju. O ni ọjọ mẹrinla tó yẹ ki INEC fi dahun ibeere, ki wọn sì fi iwe wọnyi ṣọwọ ti pe, o sì ti kọja, tori naa lóun ṣe gba ile ẹjọ lọ. Enahoro sọ pe kikọ ti INEC kọ lati gbe awọn iwe yii kalẹ takò ofin Naijiria. INEC nikan naa ni agbẹjọro yi da pe lẹjọ níwájú ilé ẹjọ giga.