Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tì sẹ́gbẹ́ kan, Asiwaju nìkan ló lè ṣé - APC

Raji Fashola

Oríṣun àwòrán, @Nairametrics

Minisita fun ọrọ iṣẹ ati ile gbigbe, Babatunde Raji Fasola ti sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC ni yoo gbegba oroke ninu eto idibo Aarẹ ti yoo waye lọdun 2023 lai wo ti họwu-họwu to n waye lori ọrọ ẹsin, iyẹn Muslim-Muslim ticket.

Fashola lo sọ ọrọ naa lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Channels.

O ni iṣoro to n koju Naijiria kọja ọrọ ẹsin ati ẹlẹyamẹya, ati pe ohun to yr ko jẹ awọn araalu logun bayii ni bi wọn yoo ṣe yan ẹni to dantọ sipo lai fi ti ọrọ ẹsin ṣe.

Lori ọrọ Muslim-Muslim ticket

Nigba ti Fahsola n sọ erongba rẹ lori ki Aarẹ ati igbakeji rẹ jẹ ẹlẹsin Musulumi kan naa, o ni “O yẹ ki awọn awọn oludije gbajumọ bi wọn yoo ṣe tan iṣoro to n koju Naijiria, awọn ọrọ to yẹ ki a maa jiroro le lasiko yii niyẹn.”

“Ninu erongba temi o, Asiwaju nikan ni mo lero o le sun Naijiria siwaju nitori mo ti ba ṣiṣẹ daadaa, mo si mọ ohun to le ṣe daadaa.”

“Ipo mi lori ọrọ ẹsin kii ṣe ohun ti mo n fi pamọ rara, mo si ti sọrọ lori rẹ daadaa, igbagbọ temi ni pe ko yẹ ki a maa sọrọ ẹsin ni gbangba, ọrọ inu ile ati ile ijọsin ni ọrọ ẹsin, kii ṣe ọrọ oṣelu.”

Fashola sọ pe ọrọ ẹsin ti pọ ju ni Naijiria amọ ọrọ ara ẹni lọrọ ẹsin, kii ṣe nnkan to yẹ ki awọn eeyan ma gbe gẹgẹ nita.

APC ni yoo bori ibo Aarẹ ọdun to n bọ

Gẹgẹ bi ohun to sọ, o di ẹyin idibo ọdun 2023 ki awọn eeyan to mọ boya Muslim-Muslim ticket lo le ṣe tabi bẹẹ kọ.

O ni “Ohun to ṣe pataki ni awọn ohun amayedẹrun bii ile ẹkọ, eto ilera to ye kooro atawọn ohun amayedẹrun mii.”

“Ṣebi a ni igabkeji Aarẹ to jẹ Kristẹni labẹ Aarẹ to jẹ Musulumi, sibẹ awọn agbebọn ṣi gbẹmi ọpọ eeyan ninu ṣọọṣi, bi wọn ṣe n pa alufaa naa ni wọn n pa awọn Musulumi.”

O pari ọrọ rẹ pe oun gbagbọ pe ẹgbẹ oṣelu APC ni yoo bori ninu idibo Aarẹ naa lọdun to n bọ.