Mò ń bọ̀ láìpẹ́ láti tú àṣìrí PDP, Atiku – Gomina Wike

Aworan Wike

Oríṣun àwòrán, Other

Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti ṣeleri lati tu asiri ẹgbẹ osẹlu PDP ati oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu naa, Atiku Abubakar.

Eyi ko ṣẹyin gbọnmi si omi ko to to ti ṣuyọ lẹyin idibo sipo abẹle to waye ni ẹgbẹ oṣelu naa ti Atiku ti jawe olubori gẹgẹ bi oludije wọn.

Wike to sọ loju opo ikansiraẹni Twitter kọ si ibẹ pe oun n bọ laipẹ lati wa sọ ọtitọ gbogbo ohun to ti ṣẹlẹ ni ẹgbẹ oṣelu PDP ati gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ni ẹgbẹ oṣelu naa laipẹ yii.

Bakan naa ni oluranlọwọ pataki gomina Nyesom Wike, Kelvin Ebiri ninu atẹjade to fi lede pe asiko ti to lati sọ gbogbo ohun to ti ṣẹlẹ lati igba ti Akitu Abubakar ti di oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu naa.

‘’Lori ọrọ Atiku, maa sọrọ soke ki gbogbo ọmọ Naijiria mọ otitọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ ni ẹgbẹ oṣelu PDP.’’

Wike ko tii sọ ohunkohun lati igba to ti kuna idibo abẹlẹ PDP

Gomina ipinlẹ Rivers naa lo fidirẹmi ninu idibo abẹle naa, ti ọpọlọpọ iṣẹlẹ si ti n waye ninu ẹgbẹ oṣelu naa.

Lẹyin idibo naa to waye ni Osu Karun un ọdun yii ni gomina ọhun ko i tii sọ ohunkohun.

Awọn eniyan ti inu wọn ko dun ninu ẹgbẹ oṣelu naa ti wọn si fi apa janu ko yee fihan an pe nkan ko lọ deede ninu ẹgbẹ oṣelu naa.

Bakan naa ni gomina Wike ti gbalejo awọn gomina lati inuẹgbẹ oṣelu miran yatọ si PDP, to fi mọ Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party.

Ohun ti awọn eniyan n sọ ni lati fi arabale gbọ ohun ti Wike yoo sọ laipẹ gẹ gẹ bi o ṣe fi lede wipe ohun n bọ lati wa sọ ti ẹnu ohun.