“Ìyàn ni yóò pa gbogbo èèyàn ìlú wa tí a bá kọ̀ láti ṣe ọdún ìjẹṣu”

Oba Ebenezer Adewumi Ogunmaṣuyi keji, Olúpẹ̀nmẹ̀n ti ilu Ùpẹ̀nmẹ̀n nipinlẹ Ondo lo sọ ọrọ yi nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ nibi ọdun ijẹṣu ilu naa ti wọn pe ni ìrẹ́mìrẹ́.
Ọba alaye ọun to ni ko si ọdun ibilẹ ti ko ni idi kan pataki ti wọn fi gbe kalẹ ni ọdun ijẹṣu ilu naa ni wọn n ṣe lati le iyan jina.
Amojuto aṣa ati iṣẹṣe ni ọna abayọ si iṣoro ti ilu ba n doju kọ

Oba Ogunmọlaṣuyi to ṣe lalaye pe o ti le ni igba ọdun ti wọn ti n ṣe ọdun naa fikun pe iyan ni yoo pa gbogbo ara ilu pata ti wọn ba kuna lati ṣe ọdun naa.

Kabiyesi naa ni akọlu to waye ni ilu Ọwọ loṣu to kọja ni ko jẹ ki wọn ṣe ọdun naa lalariwo, ati pe awọn ikorita kan to ti sọnu ninu ọdun ni oun n gbiyanju lati dapada ko ba le ri bii ti awọn baba nla oun to gbe kalẹ.

Lara awọn oun to waye nibi ọdun naa ni riru ẹru iṣu wọnu aafin lati agbala, orin latẹnu awọn obirin ilu, akanṣe adura latẹnu kabiyesi ati jijẹ iṣu ati iyan laafin lati sami jijẹ iṣu jakejado ilu naa.








