Ikọ̀ Bayana Bayana ti South Africa ló gba Ife Ẹ̀yẹ WAFCON lẹ́yìn ìgbìyànjú ìgba mẹ́rin

Ikọ agbabọọlu obinrin ti South Africa, Bayana Bayana ti gba Ife Ẹyẹ Agbaye, WAFCON fun igba akọkọ lẹyin ti wọn na ikọ agbabọọlu Morocco ninu aṣekagba idije naa.
Agbabọọlu obinrin Hildah Magaia lo ṣe moriya ninu idije naa lẹyin ti o ṣiṣẹ karakara ti ikọ South Africa fi bori ninu idije naa fun igba akọkọ lẹyin igbiyanju marun un.
Ni saa akọkọ ifẹṣẹwọnṣẹ ni ikọ South Africa ti fakọyọ, ti ko si si ẹnikẹni ninu ikọ meji to gba bọọlu wọ inu awọn.
Lẹyin iṣeju mẹjọ ni wọn tun fọbale...
Amọ Magaia ko gba fun wọn to si gba bọọlu wọ inu awọn ni iṣeju mẹta kọja ọgọta, eleyii to mu ki wọn saaju ninu idije naa.
Lẹyin iṣẹju mẹjọ lẹyin naa ni wọn fi ọba le ti o si da mẹji ti ikọ Bayana Bayana fi bori.
Ami ayo keji yii lo ji awọn ikọ Morocco ti wọn si tiraka lati fi ami ayo ẹyọkan naa sinu awọn.
Arabinrin Ayane lo ṣiṣẹ to bẹẹ ti wọn fi pari erebọọlu naa.

Igba mẹrin ti wọn ti kuna ni lọdun 2000, 2008, 2012 ati ọdun 2018
Ninu ọrọ rẹ, Balogun ikọ Bayana Bayana, Refiloe Jane ni irẹlẹ ni aṣeyọri naa jẹ fun wọn, ti inu awọn si dun daradara.
O fikun un pe niiṣe ni oun bu ṣẹkun lẹyin ifẹṣẹwọnṣẹ naa, nitori awọn ṣiṣẹ karakara lati ri pe awọn gba Ife Ẹyẹ ti ọdun yii.
Bakan naa ni akọnimọọgba ikọ naa, Desire Ellis ni inu ohun dun daradara ninu aṣeyọri yii nitori pe gbogbo igbiyanju wọn ni ọdun mejilelogun ṣẹyin lati bori gẹgẹ bi agbabọọlu lo jasi pabo.
Iṣẹ takuntakun ni ikọ South-Africa ṣe pẹlu bi wọn ṣe n jijakadi pẹlu Morocco to jẹ ile ni wọn wa, ti wọn si ni awọn ololufẹ wọn biba to n ke fitafita fun wọn lati bori.












