Iṣẹ́ olùkọ́ ló wù mí kí ọmọ mi tó kọ́ afárá tí ìjọba fún ni ẹ̀bùn ₦5million ṣe àmọ́...

Àwòrán afárá tí ọmọ náà yà

Ní àìpẹ́ yìí gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, Ọ̀jọ̀gbọ́n Babagana Zulum ṣe àgbékalẹ̀ owó mílíọ̀nù márùn-ún náírà fún ẹbí Musa ní ìpínlẹ̀ náà fún ètò ẹ̀kọ́ Sani Musa.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí fídíò àwòrán afárá tí ọmọ ọdún mẹ́tàlá náà fi amọ̀ kọ́ irú afárá tí gómìnà náà kọ́ sí ìpínlẹ̀ ọ̀hún gba orí ayélujára kan.

Gómìnà ní ìdí tí òun fi fún ẹbí ọmọ náà ní owó náà ni pé ọmọ náà ti fi hàn wí pé òun ní ẹ̀bùn àti pé iṣẹ́ ìjọba ni láti ran ọmọ náà lọ́wọ́ kó le fi dé èbúté ògo ní ayé rẹ̀.

Abẹ́ṣinkáwọ́ gómìnà Zulum, El-Lawal Mustapha ní nígbà tí fọ́nrán ọmọ náà gba orí ayélujára ni gómìnà ri tó sì ní kí òun wá ọmọ náà kàn.

Mustapha ní ìyá ọmọ náà sọ fún òun wí pé kò sí nílé nígbà tí òun débẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti ń wa wá.

Bákan náà ló rọ àwọn ọ̀dọ́ láti wo àwòkọ́ṣe Sani Musa kí wọ́n máa kó ìwúrí bá ilẹ̀ Adúláwọ̀ pẹ̀lú ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wọn.

Sani Musa jẹ́ ọmọ ọmọ ọdún mẹ́tàlá tó wà ní ipò kẹrin nínú ọmọ mẹ́wàá tí àwọn òbí rẹ̀ bí.

Gómìnà Zulum ṣe àbẹ̀wò sí ilé àwọn ọmọ náà

Láti ìgbà kékeré ló ti máa ń fi amọ̀ mọ nǹkan

Mallama Hafsa Musa, tó jẹ́ ìyá Sani nígbà tó ń bá BBC sọ̀rọ̀ ní láti ìgbà tí Sani Musa ti wà ní kékeré ló ti máa ń fi iyẹ̀pẹ̀ àti amọ̀ mọ nǹkan.

Hafsa ṣàlàyé wí pé iṣẹ́ olùkọ́ ló wu òun kí ọmọ òun ṣe tó bá dàgbà nígbà tí òun bí sáyé àmọ́ ó jọ wí pé ọmọ náà ní ẹ̀bùn nínú nǹkan mìíràn ju ohun tí ò ń gbèrò lọ.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ó máa ń ṣe àárẹ̀ tàbí ní kàtá nítorí ó fẹ́ràn láti máa ṣeré ní etí irà àti iyẹ̀pẹ̀.

“Láti ìgbà náà ni mo ti máa ń rò ó wí pé ó dàbí wí pé Sani máa ṣe dada lẹ́ka ìmọ̀ ẹ̀rọ ju iṣẹ́ olùkọ́ tí mo fẹ́ kó ṣe tẹ́lẹ̀ lọ.”

Ìgbà tí àwọn gómìnà gbé ẹ̀bùn owó kalẹ̀ fún ẹbí Musa

Mo ní kó wó afárá náà nígbà tó kọ ṣùgbọ́n ó tún òmíràn kọ́

Hafsa ní nígbà tí Sani kọ́kọ́ mọ afárá náà òun ní kó fi ọwọ́ ara rẹ̀ wó afárá náà nítorí bí àwọn ènìyàn ṣe wá pejọ́ sí ilé àwọn láti wò ó.

“Ṣùgbọ́n ó tún kọ nígbà tí gómìnà ran ènìyàn wá sí ilé wa”.

“Inú mi dùn wí pé gómìnà ṣe ìwúrí fún ọmọ mi, ohun tí mi ò ní gbàgbé ní ilé ayé mi láéláé ni”

Bákan náà ló rọ àwọn láti máa fi àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ láti gbé ẹ̀bùn tí Ọlọ́run bá fún wọn jáde láìsí ìdíwọ́ kankan.

Ó fi kun láti ìgbà tí òun ti mọ̀ wí pé ọmọ náà fẹ́ràn láti máa ya nǹkan, gbogbo nǹkan tó bá le wùlò fun ni òun máa ń rà fun tí òun bá ti jáde.

Ó wù mí láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ - Sani Musa

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ Sani tó wà ní ẹ̀kọ́ kẹrin, ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ó wu òun láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ní ìgbésì ayé òun.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹgbẹ́ òun ló máa ń wù láti bá òun ya àwòrán nítorí òun ti di ìlú mọ̀ọ́ká.

Ó fi kun pé inú òun dùn sí afárá tí òun mọ náà tí òun sì ń gbèrò láti ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́jọ́ iwájú.