Wo ìdí tí fóònù rẹ fi lè máa gbóná àti ànà àbáyọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Njẹ o ti ṣakiyesi ri pe nigba mii ẹrọ ilewọ rẹ maa n gbona?
Eyii maa n waye lọpọ igba ti eeyan ba n ta ayo lori foonu rẹ tabi to n wo fidio lori ikanni ayelujara bii YoutTube tabi Facebook.
Yatọ si nnkan ti eeynan n wo lori ẹrọ ilewọ tabi ohun to n fi ẹrọ ilewọ naa ṣe, ọpọ eeyan lo maa n woye eredi ti foonu wọn ṣe n gbona lai fi ṣe iṣẹ to lagbara pupọ ju ẹmi irufẹ foonu bẹẹ lọ.
Wo awọn idi ti foonu rẹ fi le maa gbona ati ohun ti o le ṣe nipa rẹ.
Ti ooru ba pọ ju, ẹrọ ayarabiaṣa inu foonu le falẹ
Gẹgẹ bi ooru ko ṣe ba ẹda lara mu naa ni ooru kii ṣe ọrẹ ẹrọ ilewọ.
Ọjọgbọn kan nipa eto imọ ẹrọ ni fasiti Leeds Beckett, Roz Wyatt-Millington sọ pe awọn ohun to maa n mu ẹrọ ilewọ naa ṣiṣẹ lo maa n mu ko gbona.
O ni bi awọn eroja naa ba ṣe n gbona, ni ẹrọ ‘Processor’ inu foonu naa yoo maa ṣiṣẹ ki o ma baa gbona ju, eyii lo maa n mu ki foonu miran fa nilẹ bii igbin.
Battery to ja lati 100% si 0%
Ọjọgbọn Roz ni ti oru ba mu ju, o le mu ki foonu maa gbona, eyii ti yoo ṣe ipalara fun batiri foonu bẹẹ.
To n tumọ si pe batiri naa yoo tete maa ja ti foonu ba gbona ju.
O wa sọ pe eyii maa n waye ti eeyan ba yi imọle oju foonu rẹ soke pupọ ju, paapaa ti wọn ba wa ninu oorun.
Ọna abayọ si foonu to n gbona ju
Awọn nnkan ti o le maa ṣe ree lati dena foonu gbigbona
- Maṣe gbe ina le foonu rẹ nibi to mooru ju tabi nibi ti oorun ba wa. Fun apẹrẹ, ma ṣe gba ina sara fonu naa ninu ọkọ rẹ ki o si fi silẹ nibẹ
- Yọ foonu naa kuro ninu apo ti o fi si, ki o si ti gbogbo awọn aapu ti o ko lo, fun apẹerẹ, pa GPS rẹ ti o ko ba nilo rẹ
- Ti foonu rẹ ba n gbona, o le pa foonu naa ki o tun tan lẹyin iṣẹju diẹ
- Maṣẹ gbe foonu rẹ sinu apo irẹsi tabi inu ẹrọ amounjẹ tutu












