Oloolu: Àlàyé rèé lórí ìdí tí egúngún Ajé kìí fi wọ bàtà tàbí fojú kan obìnrin

Àwòrán eégún kan àti àwọn èrò tó tẹ̀lé e

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní kí a tó ṣòòṣà láti ń ṣoóṣá, kí àgbàdo tó dáyé nǹkankan ni adìyẹ ń jẹ.

Ohun tó gbajúmọ̀ ni wí pé ilẹ̀ Yorùbá kìí fi àṣà àti ìṣẹ̀ṣe wọn ṣeré rárá kòdá pẹ̀lú bí àwọn àṣà ọ̀làjú ilẹ̀ òkèrè ti wà lóde òní.

Àṣà àti ìṣẹ̀ṣe jẹ́ ohun tó pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá, tí àwọn àgbààgbà àti ọmọdé kìí fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú rárá.

Onírúurú ọ̀nà sì ni àwọn ẹ̀yà Yorùbá fi máa ń so pọ̀ mọ́ àwọn babańlá wọn.

Nípasẹ̀ àwọn babańlá wọ́n nìyí ni wọ́n fi máa ń tọrọ nǹkan lọ́wọ́ Elédùmarè.

Lára àwọn ọ̀nà tí Yorùbá fi máa ń tọ̀rọ̀ nǹkan lọ́wọ́ Elédùmarè ni ṣíṣe ọdún àwọn òrìṣà tí wọ́n gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí aṣojú Elédùmarè lókè eèpẹ̀.

Lára wọn ni Ṣàǹgó, Ògún, Egúngún àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Egúngún náà ni Yorùbá ń pè ní eégún.

Awọn ọmọ ẹyin Egungun kan

Egúngún Oloolu ní Ibadan

Kò sí àníàní wí pé ilẹ̀ Yorùbá ní àwọn egúngún tó lágbára gidi gan tí orípa wọn kò sì le parẹ́ láéláé.

Ọ̀kan lára àwọn egúngún yìí ni egúngún Oloolu tó wà ní Ibadan.

Òdú ni egúngún Oloolu fún àwọn ọmọ bíbí àti olùgbé ìlú Ibadan kódà àwọn ènìyàn tó wà ní ìlú mìíràn mọ̀ nípa eégún Oloolu.

Ní kété tí ènìyàn bá ti dárúkọ eégún Oloolu ní Ibadan ni kálukú ti ma máa forí gbárí, tí wọ́n máa sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn nítorí ẹ̀rù àti agbára tó wà lára rẹ̀.

Àwọn obìnrin kìí ti ẹ̀ sọsẹ̀ rárá nígbà tí wọ́n bá ti gbọ́hùn wí pé eégún Oloolu fẹ́ jáde.

ni ìdí tí àwọn obìnrin kò gbọdọ̀ ṣíjú wo Oloolu?

Èèwọ̀ ni fún obìnrin láti ṣíjú wo eégún Oloolu nítorí egungun agbárí obìnrin tí eégún náà máa ń gbé sórí.

Ìgbàgbọ́ sì wà wí pé obìnrin kóbìnrin tó bá ṣíjú wo eégún Oloolu kò ní rí nǹkan oṣù rẹ̀ mọ́ títí tó ma fi jáde láyé.

Kódà ìgbàgbọ́ tún wà wí pé obìnrin bẹ́ẹ̀ le pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lọ́jọ́ àìpé.

Onírúurú àwọn ìgbàgbọ́ ló rọ̀ mọ́ eégún Oloolu lára rẹ̀ náà tún ni wí pé ẹnikẹ́ni tó bá kọ́kọ́ ṣíjú wo eégún Oloolu nígbà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, onítọ̀hún ma ṣe àárẹ̀, tí wọn kò bá sì tètè ṣe etùtù ẹni náà le jáde láyé.

Awọn ọmọ ẹyin Egungun kan

Báwo ni eégún Oloolu ṣe bẹ̀rẹ̀?

Tí a bá perí ajá, à á máa perí ìkòkò ta fi sè é.

Tí ènìyàn bá wo bí eégún Oloolu ṣe máa ń jáde, ohun tó máa kọ́kọ́ wá sí ènìyàn lọ́kàn ni akọni jagunjagun kan nílẹ̀ Ibadan tó ń jẹ́ Ayorinde Aje.

Ayorinde Aje jẹ́ jagunjagun alágbára nilẹ̀ Ibadan, ayé ìgbà naa lo jagun lọ sí ìlú Akoko, ti eegun Oloolu si jade wa koju ikọ ogun Ibadan loju ogun.

Nígbà tí ìjà náà le dójú ẹ̀, tí kò sí jagunjagun kankan tó le lọ kojú eégún Oloolu lójú ogun, Ayorinde Aje nìkan ló láyà láti lọ kojú ẹ̀, tó sì ṣẹ́gun rẹ̀.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Idi ti obinrin ko se gbọdọ siju wo Oloolu:

Lẹ́yìn tí Ayorinde Aje ṣẹ́gun eégún Oloolu, ó pinnu láti mú ẹni tó gbé eégún náà wọ ìlú Ibadan ṣùgbọ́n tí onítọ̀hún kọ̀ láti tẹ̀le.

Nígbà tí ẹni tó gbé eégún náà fárígá pé òun kò ní tẹ̀lé Ayorinde Aje, ó fa ìbínú yọ tó sì bẹ́ orí ìyàwò eégún Oloolu, tó sì gbé orí náà lé ẹ̀kú rẹ̀ lórí.

Láti ìgbà náà ni wọ́n ti máa ń fi egungun agbárí obìnrin ti maa n wa lara ẹ̀kú eégún Oloolu, ìdí sì nìyí tí obìnrin kò ṣe gbọdọ̀ ṣíjú wo eégún Oloolu.

Ìgbà wo ni eégún Oloolu máa ń jáde?

Nínú oṣù Keje ọdọọdún ni eégun Oloolu máa ń jáde lásìkò tí wọ́n máa ń ṣayẹyẹ ọdún eégun.

Lásìkò yìí ní àwọn tó ń bọ eégún ma fi ń tọrọ ìbùkùn lọ́dọ̀ Elédùmarè tó sì máa ń mú ire wálé.

Lásìkò tí eégun Oloolu bá jáde, eégun kankan kìí jáde ní ọjọ́ náà.

Ẹni tó bá máa gbé eégun Oloolu kò gbọdọ̀ bá ìyàwó rẹ̀ ní àjọṣepọ̀ tó bá ti ku oṣù kan tí ọdún náà ma wáyé.

Ẹni tó bá gbé eégún Oloolu kò gbọdọ̀ wọ bàtà, kò ní gbé ẹrù mìíràn yàtọ̀ sí egunegun agbárí obìnrin tó máa wà lórí rẹ̀.

Lára àwọn ohun tó máa ń wà lára ẹ̀kú Oloolu ni àwọ̀n, agbárí obìnrin, egungun itan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tó máa ń mú eégún náà jẹ́ ohun ìbẹ̀rù.

Àkọlé fídíò, Charles Olumo Agbako: Ọjọ́ tí ìyá mi kú jẹ́ kò ṣeé gbàgbé-