Itan manigbagbe Fukushima: Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ilẹ̀ ríru Fukushima ni Japan, èyíì tó mú ẹ̀mí 16,000 èèyàn lọ

Ọpọlọpọ eeyan lo di alainilelori lẹyin iṣẹlẹ alagbara Tsunami naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ eeyan lo di alainilelori lẹyin iṣẹlẹ alagbara Tsunami naa

Gege bi awọn onkọtan ṣe sọ, yatọ si isẹlẹ Chernobyl to waye lọdun 1986 ni Ukraine, ko tun si eyii to buru to iṣẹlẹ naa lagbaye.

Ni nnkan bii ọdun marun un sẹyin ni iṣẹlẹ ilẹ riru kan waye, iyẹn lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2011, nibi ti ẹgbẹgbẹrun eeyan ti dero ọrun.

Iṣẹlẹ naa buru to bẹẹ ti ẹmi nnkan bii ẹgbẹrun lọna ogun eeyan lọ si, to si tun ba ileeṣẹ Fukushima Dai-ichi to n pese ina manana jẹ titi di oni yii.

Gege bi awọn onkọtan ṣe sọ, yatọ si isẹlẹ Chernobyl to waye lọdun 1986 ni Ukraine, ko tun si eyii to buru to iṣẹlẹ naa lagbaye.

Àkọlé fídíò, Wo obìnrin kanṣoso láàrin àwọ́n ọkunrin agunẹṣin gbafẹ́ nílùú Ilorin àmọ́ tọ́kàn rẹ̀ yii

Kin ni ohun to sẹlẹ lọjọ naa gan ni pato?

Nkan ti iṣẹlẹ naa sọ awọn ile kan ati ọkọ dà niyii ni Natori, to wa nitosi Seandai.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Nkan ti iṣẹlẹ naa sọ awọn ile kan ati ọkọ dà niyii ni Natori, to wa nitosi Seandai.

Ni ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2011, ni iji lile kan kọlu eti okun iha ariwa ila-oorun orilẹ-ede Japan.

Tsunami naa ti giga rẹ to mita mẹwaa wọ gbogbo ile, ileeṣẹ, ọkọ ati ọkọ oju omi to wa loju ọna rẹ lọ bi igba ti ọmọde ba n ṣere ọwọ.

Nnkan bii ẹgbẹrun mẹrindilogun eeyan lo ba iṣẹlẹ naa lọ, ti nnkan bii ẹgbẹrun mẹta awọn miran si di awati, ti gbagbo si wa pe awọn naa ti ku.

Tsunami ti a n sọrọ rẹ yii tun sun kan ileeṣẹ Fukushima Dai-ichi to n pese ina, o ba awọn irinṣẹ rẹ jẹ, eyii to tun ṣakoba fun afẹfẹ ti awọn eeyan n mi simu lagbegbe naa.

Afẹfẹ ọhun buru to bẹ ti nnkan bii ẹgbẹrun lọna ọgọjọ eeyan fi agbegbe to yi ileeṣẹ naa ka titi de ọgbọn kilomita silẹ.

Yatọ si afẹfẹ, iṣẹlẹ naa tun ba omi mimu ati ounjẹ jẹ.

Nigba ti wọ n ṣe iṣiro iye nnkan to bajẹ, to fi mọ dukia ti awọn eeyan padanu, ko din ni biliọnu lọna ẹgbẹrun lọna igba dọla.

Àkọlé fídíò, Wo obìnrin kanṣoso láàrin àwọ́n ọkunrin agunẹṣin gbafẹ́ nílùú Ilorin àmọ́ tọ́kàn rẹ̀ yii

Iru ipo wo ni Fukushima wa bayii?

Ile to wo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bo tile je pe ileeṣẹ to n ṣakoso rẹ, Tokyo Electric Power Co, Tepco, sa gbogbo ipa rẹ, pelu ọpọ iwadii, iroyin ni ko si eni to tii le wọle sinu ileeṣẹ naa bayii.

Ṣugbọn wọn ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lati wa ojutu si ọrọ naa.

Gẹgẹ bii ohun ti Tepso sọ, o le to nnkan bii ọgbọn tabi ogoji ọdun ki ọrọ naa to le yanju patapata.

Ki ni ireti awọn eeyan to n gbe ni Fukushima tẹlẹ?

Nnkan bii ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan to sa kuro ni Fukushima ṣaaju ni ko tii pada sile wọn titi di akoko yii.

Bẹẹ si ni nnkan bii ẹgbẹrun mejidinlogun lara awọn eeyan naa lo si n gbe ni ile ti wọn pese fun wọn fun igba diẹ lati akoko naa wa.

Bo tile je ijọba Japan sọ pe awọn le má pada si awọn agbege kan ti wọn sọ pe o ti ṣe gbe fun awọn eeyan bayii, pupọ ninu awọn eeyan ọhun ni ẹru n ba lati pada sibẹ.

Awọn naa ni o ṣeṣe ki afẹfẹ to wa nibẹ ṣi le mu ẹmi eeyan lọ, ṣugbọn ijọba ti ṣe awọn ohun to tọ lati fọ afẹfẹ naa mọ.

Bakan naa ni ọpọ ninu awọn ọhun n sọ pe ijọba yoo da owo ajẹmọnu to n san fun wọn duro ti wọn ba le pada si Fukushima.

Ijọba Tokyo ti ṣeleri tiriliọnu mẹrindinlọgbọn owo ilẹ naa fun atunṣe agbegbe n, bakan naa lo tun ṣeleri tiriliọnu mẹfa lati maa tun agbegbe naa ṣe fun ọdun mẹwaa si asiko yii.