Sikiru Ayinde Barrister's son: Báwo ni Barry Jhay se kó sí gbaga ọlọ́pàá?

Barry Jhay

Oríṣun àwòrán, BArry Jhay

Gbajugbaja olorin Barry Jhay to tun jẹ ọmọ agba ọjẹ olorin Yoruba ni Naijria, oloogbe Alhaji Ayinde Barrister ni ọlọpaa ṣẹṣẹ mu laipẹ yii lori ẹsun iku ọga ileeṣẹ to n gbe awọn awo orin rẹ sita, Babatunde Oyerinde Abiodun ti ọpọ mọ si Kashy.

Iroyin ni wọn fi ẹsun kan pe ilumọọka olorin naa wa ni orilẹede Ghana lati lọ ṣe awọn orin kan ati lati ba ọga ileeṣẹ orin rẹ sọ ọ̀rọ̀ katakara.

Ṣaaju ọjọ ti arakunrin naa papoda, a gbọ pe o fun Barry Jhay ni ẹbun ago ọwọ nla ti iye owo rẹ to miliọnu mẹsan naira eyi ti olorin naa fi buga ninu fidio kan to fi sita loju opo instagram rẹ.

Barry Jhay

Oríṣun àwòrán, Barry Jhay

Àkọlé fídíò, Wo obìnrin kanṣoso láàrin àwọ́n ọkunrin agunẹṣin gbafẹ́ nílùú Ilorin àmọ́ tọ́kàn rẹ̀ yii

Ninu fidio naa, eeyan lee gbọ ti Barry Jhay n sọ pe "bi mo ṣe darapọ mọ ẹgbẹ yẹn niyẹn" ti Kashy naa sin n sọrọ labẹlẹ pe "Mo nifẹ rẹ ọmọ iya".

Awọn awuyewuye to n lọ lode fihan pe o ti pẹ ti Kashy ti jẹ eegun ẹyin nipa ẹnawo fun iṣẹ orin kikọ Barry latori eyi to sọ ọ di ilumọka gangan lọdun 2018, "Aiye".

Beeyan ba si wo oju opo instagram Barry Jhay ati Kashy daadaa, eeyan o ri i pe irẹpọ gidi lo wa laarin awọn mejeeji.

Bi Kashy ba tilẹ fẹ jọ ẹni ti ko fẹran awọn itakun ayelujara, o ṣi pọn olorin naa le kẹyin lọjọ kẹtala oṣu keji ọdun 2021 tii ṣe ọjọ ibi Barry Jhay.

Ohun to jẹ kayefi ni wipe, nigba diẹ ṣaaju ki Kashy to ku, iroyin sọ pe Barry Jhay fi fidio kan hande nibi to ti n pọ ẹjẹ lẹnu.

Oloogbe Alhaji Barrister ati Ọmọ rẹ Barry jhay

Oríṣun àwòrán, BarryJhay

"Wo bi arakunrin yii ṣe n lu mi. Mi o ṣe nkankan o. Mo n ka orin silẹ ni ọkunrin yii si bẹrẹ si ni lu mi bayii". Igba to ya lo pe orukọ ẹni naa ti ẹnikẹni ko mọ ni "Jew".

Awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun lo maa n saba lo orukọ yẹn fun awọn ti kii ṣe ọmọ ẹgbẹ́ rara. Nigba mii o maa n tumọ si pe wọn n pe ẹni bẹ́ẹ́ ni ikoko tabi ojo ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Gbogbo iru eyi lo mu ki iroyin to n gbode kan di eyi ti wọn gbagbọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ẹgbẹ okunkun kan ni orilẹede Ghana lo ṣe ikọlu si i.

Kii ṣe ajoji laarin awọn oṣere ati olorin ki wọn maa ni aawọ lori ọrọ owo ati ni ọpọ igba, ibaṣepọ laarin wọn maa n fẹ́rẹ́ẹ̀ fori ṣanpọn.

Àkọlé fídíò, Wakili tẹẹ rí yẹn kìí ṣe ẹran rírọ̀, ó ń díbọ́n ní o - Iba Gani Adams

Iroyin kan fi sita pe Barry Jhay ati Kashy ni ija lori awọn ọrọ katakara kan.

Bi ẹ ba ranti, ajọ EFCC mu Kashy lọdun 2020 lori ẹsun jibiti ori ayelujara. Ọrọ latẹnu awọn kan to sunmọ ọ pẹti pẹti sọ pe iṣẹlẹ pẹlu ajọ EFCC pa a lara debi to kan an lẹmi eyi to mu ko bẹrẹ si ni lo oogun ni orilẹede ti ofin wn lodi si i.

Ẹwẹ, ohun tawọn eeyan n ran mẹnu nita gbangba lati igba naa ni pe ṣe Barry jhay lo fa iku ọga rẹ ni? Abi ṣe o ran awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lati fiya jẹ Kashy? Abi ṣe iporuru ọkan lo fa sababi bi Kashy ṣe gba ẹmi ara rẹ ni?

Eyi ati ọpọ ibeere ni ileeṣẹ ọlọpaa Ghana ni ireti lati ṣi aṣọ loju wọn ninu igbesẹ iwadi ti wọn n ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́.