Christians in Pakistan: Ọmọbìnrin ọdún méjìlà tó dí ìyàwó tipátipá fún Mùsùlùmí sọ ìrírí rẹ̀

obinrin

Oríṣun àwòrán, others

Ọjọ Karundinlogun, Oṣu Kẹfa, ọdun 2020 ni awọn ọkunrin mẹta kan ilẹkun ile ọdọmọbinrin Farah, ti wọn si ji gbe lọ loju ibọn.

Ọmọ ọdun mejila ni Farah nigba ti iṣẹlẹ yii waye nitori o jẹ ọmọlẹyin Kristi ni orilẹede Pakistan.

Awọn ajinigbe ọhun gbe e lọ si agbegbe Faisalabad ti o jina si ile rẹ, ti wọn si kan an ni pa fun wọn lati jọwọ ẹsin Kristẹni rẹ fun ẹsin Islam.

Àkọlé fídíò, 'Mi ò sí ni Ghana àmọ̀ ó dá wa lójú pé Ghana jẹ́ ìlú tó máa ń lo òfin wọn dáadáa, Barry Jhay máa bọ́'

Wẹrẹ ti iṣẹlẹ yii waye ni Baba Farah gbera lọ si ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe naa, amọ wọn o kọbi ara si, niṣe ni wọn fi iya jẹ baba ọmọ naa, ti wọn ko si gba ọrọ rẹ silẹ wi pe awọn agbebọn ti ji ọmọ rẹ gbe lọ nitori ẹsin rẹ.

Ọpẹlọpẹ awọn ara ẹsin Kristẹni ni agbegbe naa ti wọn pese iranwọ fun wọn lati bẹrẹ si ni wa gbogbo ọna ti ileeṣẹ ọlọpaa yoo fi dasi ọrọ naa.

Farah ni wọn fi tipatipa ba oun lọpọ, wọn si tun gbe oun ni iyawo.

Lẹyin naa ni wọn de e mọlẹ, ti wọn si fi ṣe ẹru ninu ile naa.

Farah ni oun ni ọmọ ọdọ ninu ile, ti yo tọju ile ati awọn ẹranko to wa ni ita.

'Lẹyin naa ni wọn tun fi okun demi mọlẹ, amọ ni gbogbo asiko yii ni mo ma n gbadura si Ọlọrun lati gbamila kuro ni ọwọ awọn aṣebi yii.

Àkọlé fídíò, Wo obìnrin kanṣoso láàrin àwọ́n ọkunrin agunẹṣin gbafẹ́ nílùú Ilorin àmọ́ tọ́kàn rẹ̀ yii

Lẹyin oṣu marun un ni awọn ọlọpaa to gba lati bẹrẹ iwadii lori ọrọ Farah, ti wọn si tọ pinpin rẹ de ibi ti wọn jigbe lọ.

Awọn ẹbi Farah gba ile ẹjọ lọ,amọ Farah kọkọ kọ jalẹ wi pe niṣe ni oun gba lati fẹ ọkọ oun lai si ẹni to fi ipa mu oun, ati lati kọ ẹsin Kristẹni silẹ fun ẹsin Islam.

Amọ iwadii kikun fihan pe wọn ja Farah laya, ti wọn si sọ fun wi pe , to ba sọ otitọ, wọn yoo pa ẹbi ati ara rẹ.

Adajọ ri wi pe igbeyawo rẹ ko ba ọna ofin mu, ti wọn si tu igbeyawo naa ka, ti Farah si pada lọ si ile rẹ ni ayọ ati alaafia.

Amọ, ọrọ ko ri bẹẹ fun arabinrin Shabzaz to jẹ ẹni ọdun mẹrinla nigba ti wọn jigbe, amọ to jajabọ lọwọ awọn ajinigbe oun nitori o jẹ ẹlẹsin Kristẹni.

Nibayii, oun ati awọn mọlẹbi rẹ wa ni apamọ nitori awọn ajinigbe naa ni awọn yoo pa oun ati ẹbi rẹ nitori o salọ kuro ni igbekun.

Iwa yii peleke si lorilẹede Pakistan nitori ida kan awọn eniyan lorilẹede naa ni ẹlẹsin Kristẹni, ti iwadii si fihan pe o kere ọdọbinrin ẹgbẹrun to jẹ ọmọlẹyin Kristẹni ni ẉn jigbe lọdọọdun ni orilẹede Pakistan.