Sunday Igboho: ''Ọlọ́pàá tó bá yìnbọn pa àgbẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá yóò kábàmọ́ọ̀, àwọn tó ń gbé AK-47 ni Buhari ní kí ẹ pa''

Oríṣun àwòrán, Nigeria police/Sunday Igboho
Gbajugbaja ajijagbara ilẹ Yoruba, Ọgbẹni Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti kilọ fawọn ọtẹlẹmuyẹ. awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ eleto abo mii lati rọra ṣe lori aṣẹ ti Aarẹ Muhammadu Buhari pa pe kawọn ẹṣọ alaabo maa yinbọn
Laipẹ yii ni Buhari paṣẹ fawọn ẹṣọ eleto abo lati yinbọn fun ẹnikẹni ti wọn ba ri ibọn AK-47 lọwọ rẹ ninu igbo.
Ṣugbọn Igboho sọ ninu fidio kan to fi lede lori ayelujara pe ki awọn ẹṣọ eleto abo maa lọ ṣeeṣi mu awọn agbẹ tabi ọde to n lo ibọn sakabula nilẹ Yoruba.
- Ewú ńbẹ! Ẹgbẹ̀ àwọn oṣìṣẹ́ NLC faraya, yóò gùnlé ìyànṣẹ́lòdí lónìí
- Kí ló gbé Barry Jhay ọmọ Alhaji Sikiru Ayinde Barrister dé gbaga ọlọ́pàá?
- Wo ohun mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìbọn AK-47
- Wòlíì Kasali gba Bunmi ìyàwó rẹ̀ àkọ́fẹ́ padà, ìjà parí!
- Mò ń bẹ Ọlọ́run pé kí ìdàgbàsókè Nàíjíríà ṣojú ẹ̀mí mi - Obasanjo
- Wọ́n ti ń ti ọ̀rọ̀ olóṣèlú bọ ọ̀rọ̀ Sunday Igboho ní èyí tó yẹ kí Yorùbá fi ṣọ́ra- Oba Francis Olusola-Alao
- Awẹ́ Gbólóhùn ni kókó tí à ń gbéyẹ̀wò lónìí lórí ètò Akomolede- Olùkọ Olajide
- Wo ohun tí Ńo-Fly Zone' túmọ̀ sí
Ọgbẹni Adeyemo ṣalaye pe ibọn AK-47 yatọ si iru ibọn tawọn agbẹ n gbe kọpa lọ si oko nilẹ Yoruba.
O kilọ fawọn ẹṣọ eleto abo lati maa yinbọn fawọn agbẹ ti wọn fi ibọn sakabula ṣora lorukọ wi pe wọn n gbe ibọn AK-47 kiri ninu igbo.
''Sheikh Gumi ti sọ ibi tawọn janduku to n lo ibọn AK-47 wa ninu igbo, nibẹ lo yẹ kawọn ẹṣọ eleto lọ.
Ki wọn maa tiẹ gbero lati yọ awọn ọdẹ ati awọn agbẹ to n lo ibọn lẹnu rara,'' Igboho lo sọ bẹẹ.
Ọgbẹni Igboho ni inu oun dun si aṣẹ ti Buhari pa lori ọrọ awọn to n gbe ibọn AK-47 kiri ninu igbo, o ni ariwo ti oun atawọn eeyan kan n pa nipa awọn darandaran to n gbebọn kiri ti n so eso rere niyẹn.
Igboho rọ awọn agbofinro lati jẹ iṣẹ ti Buhari ran wọn lai beṣu bẹgba.
O ni ẹnikẹni to ṣeeṣi pa ọlọdẹ tabi agbẹ to n gbebọn sakabula lọ si oko fun iṣọra ara rẹ yoo kabamọ.
Igboho ni lorukọ gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba lapaapọ ni oun n jiṣẹ naa fawọn eṣọ eleto abo.












