Barry Jhay and Kashy Godson: Mo mọ̀ pé o ti wà ní ẹnu ibodè ọ̀run torínáà, ẹkún ayọ̀ ni mo ń sun - Adaaliyah

Oríṣun àwòrán, kingkashy01
Oni lo yẹ ko jẹ ọjọ ibi Kashy Godson, oni kan naa to yẹ ko pe ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni wọn gbe e gbin sinu ilẹ gẹgẹ bo ṣe dagbere faye lọjọ diẹ sẹyin.
Loju opo arabinrin kan to pe ara rẹ ni afẹsọna Kashy lo ti fi fidio ati ọrọ idagbere sita si ololufẹ rẹ.

Oríṣun àwòrán, adaaliyah
Ada Aliyah fi awọn ọrọ to lee mu omije jade loju eeyan sita pe:
"Sun re o Ọba!
O ti fi ọwọ kan aye ọpeniyan o si ti yi aye ọpọlọpọ pada,
iyẹn awọn eniyan ti ko tilẹ wa si sakani rẹ nigba too nilo wọn ju,
ṣugbọn Ọlọrun lo mọ ju".
Lẹyin iku oloogbe yii ni orilẹede Ghana fi ẹsun kan gbajugbaja olorin Barry Jhay, to jẹ ọmọ agba ọjẹ olorin Yoruba oloogbe Sikiru Ayinde Barrister pe o lọwọ ninu iku Kashy.

Oríṣun àwòrán, adaaliyah

Oríṣun àwòrán, Yetunde Olugbenga
Aliya ni "mo mọ pe o ti wa ni ẹnu ibode ọrun, mo ṣeleri lati ma sọkun mọ, bi mo ba sọkun, ẹkun ayọ ni latara iranti didun ti mo ni pẹlu rẹ ati anfani nla ti mo ni lati ṣalabapade rẹ".
Sibẹ sibẹ, Aliya kọ ọrọ ikini ọjọ ibi sita fun Kashy ninu eyi to ti ni ko ṣi tii ye oun ṣugbọn Ọlọrun nikan lo mọ ju.

Oríṣun àwòrán, kingkashy01

Oríṣun àwòrán, adaaliyah
Aliyah ni gbogbo igba lo maa n sọ fun awọn eeyan bo ṣe fẹran rẹ to si mọ riri rẹ. Tori eyi o ni oun n ṣaaro rẹ, ẹni to maa n ṣe orikunkun si oun gan.
O fi kun un wipe o jẹ nkan iwuri gidi gan pe Kashy ṣe awọn nkan to jẹ pe ni ọgọrun ọdun si isisiyii, o ṣeeṣe ki awọn eeyan mii ma lee ṣe e gẹgẹ bo ṣe ya aworan rẹ loju opo awọn eeyan to n ṣe idaro rẹ.














