Violence against Women: Wo iye obìnrin lágbàáye tó ń kojú ìwà ipá, àti ohun tó ń ṣokùnfà ẹ̀?

Oríṣun àwòrán, PA Media
Iwadii ti Ajọ eto ilera lagbaye, WHO gbe jade ti fihan pe ida mẹta awọn obinrin lagbaye lo n koju iwa ipa ni igba kan tabi omiran ni igba aye wọn.
Iwadii yii safihan iwa ipa to lagbara julọ ti awọn obinrin n koju lati ọdun 2000 si 2018, to si fihan pe iwa ipa pọsi lasiko aarun Coronavirus.
''Iwa ipa ti peleke si ti ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu awọn obinrin ṣi n koju rẹ ni ojoojumọ''.
''Ida mẹrin awọn obinrin laaarin ọdun marundinlogun si ọdun mẹrinlelogun ni awọn ọrẹkunrin wọn ti fi ipa kan hu iwa ipa si.''
''iwa ipa ti awọn obinrin n koju yii si wọpo laarin awọn eniyan to wa ni Iwọ Guusu Asia ati Ilẹ Afrika, to fi mọ agbegbe Oceania.
Onimọ nipa ẹtọ awọn obinrin, Dokita Mairo Mandara ni iwadii naa ko jọ oun loju nitori gẹgẹ bi dokita, oun mọ awọn obinrin ti wọn n koju ọpọlọpọ idojukọ ninu igbeyawo wọn.
O ni iwa ipa si obinrin ti wọpọ ni awujọ ti ko si niiṣe pẹlu ede, ẹya , ẹsin tabi talika ati ọlọrọ, gbogbo eniyan ni wọn n hu iwa ipa si obinrin.
''Lasiko aarun Coronavirus yii, ifipabanilopọ ti pọsi to fi mọ awọn ọmọde.''
''Ọpọlọpọ awọn obinrin ti ko mọ wi pe awọn obi awọn ọkọ wọn ti hu iwa ipa si wọn nigba ti wọn wa ni ọmọde, ti wa bẹrẹ si ni hu iru iwa naa si wọn.''
Dokita Mandara ni bi o tilẹ jẹpe awọn obinrin ni ifarada, amọ wọn ko le e ni igbagbọ ninu ọkunrin to ba ti hu iwa ipa si wọn.
Bakan ni o parọwa si awọn ọkunrin lati bẹru Ọlọrun, ki wọn si ranti pe ti wọn ba fi iya jẹ awọn obinrin, obinrin ni iya wọn, obinrin si ni awọn ọmọ wọn nitori awọn ọmọ naa yoo dagba.

















