Charles Olumo Agbako: Ọjọ́ tí ìyá mi kú jẹ́ kò ṣeé gbàgbé- Abdulsalam Ishola

Àkọlé fídíò, Charles Olumo Agbako: Ọjọ́ tí ìyá mi kú jẹ́ kò ṣeé gbàgbé-

Lori ọ̀rọ̀ pe emi ni mo bi Pasuma, ẹ jẹ́ kí a fò ó lásikò yii- Charles Olumo Agbako.

Gbajugbaja agba oṣere, Charles Olumo ti ọpọ mọ si Agbako ni iroyin n gbe e pe o ti pe ẹni Ọgọrun ọdun lorilẹ aye bayii.

Gbogbo ọjọ kẹsan oṣu keje ọdun ni ọjọ ibi agba oṣere naa amọ ti ọdun yii da yatọ gẹgẹ bi gbogbo awọn akẹgbẹ rẹ lọmọde ati lagba ṣe n yẹ ẹ si tori o ṣọwọn lati gbọ pe eeyan kan pe ọgọrun ọdun paapaa lagbo tiata.

Amọṣa BBC Yoruba ko lee fidi ọjọ ori agba oṣere yii mulẹ.

Oloye Charles Olumo ti ọpọ n pe ni Agbako ṣalaye ohun to ṣokunfa orukọ Agbako to n jẹ ninu ere yatọ si Abdulsalam Ishola ti awon Obi rẹ sọ ọ.

O mẹnu ba bo ṣe bẹrẹ ere sise lasiko to n gbalejo BBC Yoruba nile rẹ.

Agba Osere naa sọ nipa ọjọ to baa ninu jẹ julọ laye.

Agbako ati awon ẹbi rẹ to wa nile nigba ti BBC Yoruba kan si wọn

Agbako sọ nipa awọn ipenija ti oju rẹ ti ri ati awọn ohun to ti la kọja sẹyin.

O tun gba awọn ọdọ nimọran lori iwa ọmọluwabi to n fun ni ni ẹmi gigun ati ifọkanbalẹ.

Agbako àto Pasuma

Oríṣun àwòrán, Others